II. Tim 1:3-4
II. Tim 1:3-4 Bibeli Mimọ (YBCV)
Mo dupẹ lọwọ Ọlọrun, ti emi nsìn lati ọdọ awọn baba mi wá ninu ẹri-ọkan funfun, pe li aisimi li emi nṣe iranti rẹ ninu adura mi, T'ọsan t'oru li emi njaìyà ati ri ọ, ti mo nranti omije rẹ, ki a le fi ayọ̀ kún mi li ọkàn
Pín
Kà II. Tim 1II. Tim 1:3-4 Yoruba Bible (YCE)
Nígbà tí mo bá ń ranti rẹ ninu adura mi tọ̀sán-tòru, èmi a máa dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọrun tí mò ń sìn pẹlu ẹ̀rí-ọkàn mímọ́, gẹ́gẹ́ bí àwọn baba-ńlá mi ti ṣe. Nígbà tí mo bá ranti ẹkún tí o sun, a dàbí kí n tún rí ọ, kí ayọ̀ mi lè di kíkún.
Pín
Kà II. Tim 1II. Tim 1:3-4 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Mo dá ọpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run, ẹni tí èmi ń sìn pẹ̀lú ẹ̀rí ọkàn mímọ́ gẹ́gẹ́ bí àwọn baba mi ti í ṣe, pé ni àìsimi lọ́sàn án àti lóru ni mo ń ṣe ìrántí rẹ nínú àdúrà mi. Bí mo ti rántí omijé rẹ, bẹ́ẹ̀ ni mo ń fẹ́ láti rí ọ kí èmi kí ó lè kún fún ayọ̀.
Pín
Kà II. Tim 1