II. Tes 3:2-3 - Compare All Versions

II. Tes 3:2-3 YBCV (Bibeli Mimọ)

Ati ki a le gbà wa lọwọ awọn aṣodi ati awọn enia buburu: nitoripe ki iṣe gbogbo enia li o gbagbọ́. Ṣugbọn olododo li Oluwa, ẹniti yio fi ẹsẹ nyin mulẹ, ti yio si pa nyin mọ́ kuro ninu ibi.

II. Tes 3:2-3 YCE (Yoruba Bible)

Kí ẹ tún máa gbadura pé kí Ọlọrun gbà wá lọ́wọ́ àwọn eniyan burúkú ati àwọn ìkà, nítorí kì í ṣe gbogbo eniyan ni ó gbàgbọ́. Ṣugbọn olódodo ni Oluwa, òun ni yóo fi ẹsẹ̀ yín múlẹ̀, tí yóo sì pa yín mọ́ kúrò ninu ibi gbogbo.

II. Tes 3:2-3 BMYO (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)

Kí ẹ sì máa gbàdúrà fún wa kí a lè bọ́ lọ́wọ́ àwọn ìkà àti àwọn ènìyàn búburú, nítorí pé kì í ṣe gbogbo ènìyàn ló ní ìgbàgbọ́. Ṣùgbọ́n olódodo ni Olúwa, ẹni tí yóò fi ẹsẹ̀ yín múlẹ̀, tí yóò sì pa yín mọ́ kúrò nínú ibi.