II. Tes 2:3-4
II. Tes 2:3-4 Bibeli Mimọ (YBCV)
Ẹ máṣe jẹ ki ẹnikẹni tàn nyin jẹ lọnakọna; nitoripe ọjọ na ki yio de, bikoṣepe ìyapa nì ba kọ́ de, ki a si fi ẹni ẹ̀ṣẹ nì hàn, ti iṣe ọmọ ègbé; Ẹniti nṣòdì, ti o si ngbé ara rẹ̀ ga si gbogbo ohun ti a npè li Ọlọrun, tabi ti a nsin; tobẹ ti o joko ni tẹmpili Ọlọrun, ti o nfi ara rẹ̀ hàn pe Ọlọrun li on.
II. Tes 2:3-4 Yoruba Bible (YCE)
Ẹ má ṣe jẹ́ kí ẹnikẹ́ni tàn yín jẹ lọ́nàkọnà nípa ọ̀rọ̀ yìí. Nítorí kí ọjọ́ Oluwa tó dé, ọ̀tẹ̀ nípa ti ẹ̀sìn níláti kọ́kọ́ ṣẹlẹ̀, kí Ẹni Ibi nnì, ẹni ègbé nnì sì farahàn. Yóo lòdì sí ohun gbogbo tí ó jẹ́ ti Ọlọrun tabi tí ó jẹ mọ́ ti ẹ̀sìn. Yóo gbé ara rẹ̀ ga ju èyíkéyìí ninu àwọn oriṣa lọ; yóo tilẹ̀ lọ jókòó ninu Tẹmpili Ọlọrun, yóo sì fi ara hàn pé òun ni Ọlọrun.
II. Tes 2:3-4 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Ẹ má ṣe jẹ́ kí ẹnikẹ́ni kí ó tàn yín jẹ ní ọ̀nàkọnà, nítorí pé ọjọ́ náà kì yóò dé, bí kò ṣe pé ìṣọ̀tẹ̀ bá kọ́ ṣẹlẹ̀, tí a sì fi ẹni ẹ̀ṣẹ̀ hàn, tí í ṣe ọmọ ègbé. Òun yóò lòdì sí, yóò sì gbé ara rẹ̀ ga sí gbogbo ohun tí a ń pè ní Ọlọ́run tàbí tí a ń sìn, dé ibi pé yóò gbé ara rẹ̀ jókòó nínú tẹmpili Ọlọ́run, tí yóò sì pe ara rẹ̀ ní Ọlọ́run.