II. Tes 2:13-17
II. Tes 2:13-17 Bibeli Mimọ (YBCV)
Ṣugbọn iṣẹ wa ni lati mã dupẹ lọwọ Ọlọrun nigbagbogbo nitori nyin, ará, olufẹ nipa ti Oluwa, nitori lati àtetekọṣe li Ọlọrun ti yàn nyin si igbala ninu isọdimimọ́ Ẹmí ati igbagbọ́ otitọ: Eyiti o ti pè nyin si nipa ihinrere wa, ki ẹnyin ki o le gbà ogo Jesu Kristi Oluwa wa. Nitorina, ará, ẹ duro ṣinṣin, ki ẹ si dì ẹkọ́ wọnni mu ti a ti fi kọ́ nyin, yala nipa ọ̀rọ, tabi nipa iwe wa. Njẹ ki Jesu Kristi Oluwa wa tikararẹ̀, ati Ọlọrun Baba wa, ẹniti o ti fẹ wa, ti o si ti fi itunu ainipẹkun ati ireti rere nipa ore-ọfẹ fun wa, Ki o tù ọkan nyin ninu, ki o si fi ẹsẹ nyin mulẹ ninu iṣẹ ati ọrọ rere gbogbo.
II. Tes 2:13-17 Yoruba Bible (YCE)
Ṣugbọn ó yẹ kí á máa dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọrun nítorí yín, ẹ̀yin ará, àyànfẹ́ Oluwa, nítorí Ọlọrun ti yàn yín láti ìbẹ̀rẹ̀ wá láti gbà yín là nípa Ẹ̀mí tí ó sọ yín di mímọ́, ati nípa gbígba òtítọ́ gbọ́. Ọlọrun pè yín sí ipò yìí nípa iwaasu wa, kí ẹ lè jogún ògo Oluwa wa Jesu Kristi. Nítorí náà, ẹ̀yin ará, ẹ dúró ṣinṣin, kí ẹ di àwọn ẹ̀kọ́ tí a fi le yín lọ́wọ́ mú, kì báà ṣe àwọn tí a kọ yín nípa ọ̀rọ̀ ẹnu tabi nípa ìwé tí à ń kọ si yín. Bẹ́ẹ̀ ni àwa náà gbà á. Oluwa wa fúnrarẹ̀ ati Ọlọrun Baba wa, tí ó fẹ́ wa, tí ó fún wa ní ìtùnú ayérayé ati ìrètí rere nípa oore-ọ̀fẹ́, yóo tù yín ninu, yóo fi ẹsẹ̀ yín múlẹ̀ ninu oríṣìíríṣìí iṣẹ́ ati ọ̀rọ̀ rere.
II. Tes 2:13-17 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Ṣùgbọ́n, ohun tí ó tọ́ fún wa ni láti máa dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run nígbà gbogbo nítorí yín, ará olùfẹ́ ní ti Olúwa, nítorí láti ìbẹ̀rẹ̀ ni Ọlọ́run ti yàn yín sí ìgbàlà nípa ìsọdimímọ́ ti Ẹ̀mí àti nípa gbígba òtítọ́ gbọ́. Òun ti pè yín sí èyí nípa ìhìnrere wa, kí ẹ̀yin kí ó lè pín nínú ògo Jesu Kristi Olúwa wa. Nítorí náà ará, ẹ dúró ṣinṣin, kí ẹ sì di àwọn ẹ̀kọ́ wọ̀n-ọn-nì tí a kọ́ yín mú, yálà nípa ọ̀rọ̀ ẹnu tàbí lẹ́tà. Ǹjẹ́ kí Jesu Kristi Olúwa wa tìkálára rẹ̀, àti Ọlọ́run baba wa, ẹni to ti fẹ́ wa, tí ó sì ti fi ìtùnú àìnípẹ̀kun àti ìrètí rere nípa oore-ọ̀fẹ́ fún wa. Kí ó mú ọkàn yín le, kí ó sì kún yín pẹ̀lú agbára nínú iṣẹ́ gbogbo àti ọ̀rọ̀ rere gbogbo.