II. Tes 2:1-3
II. Tes 2:1-3 Bibeli Mimọ (YBCV)
ṢUGBỌN awa mbẹ̀ nyin, ará, nitori ti wíwa Jesu Kristi Oluwa wa, ati ti ipejọ wa sọdọ rẹ̀, Ki ọkàn nyin ki o máṣe tete mì, tabi ki ẹ máṣe jaiya, yala nipa ẹmí, tabi nipa ọ̀rọ, tabi nipa iwe bi lati ọdọ wa wá, bi ẹnipe ọjọ Oluwa de. Ẹ máṣe jẹ ki ẹnikẹni tàn nyin jẹ lọnakọna; nitoripe ọjọ na ki yio de, bikoṣepe ìyapa nì ba kọ́ de, ki a si fi ẹni ẹ̀ṣẹ nì hàn, ti iṣe ọmọ ègbé
II. Tes 2:1-3 Yoruba Bible (YCE)
Ẹ̀yin ará, à ń bẹ̀ yín nípa ọ̀rọ̀ lórí ìgbà tí Oluwa yóo farahàn ati ìgbà tí yóo kó wa jọ sọ́dọ̀ ara rẹ̀, ẹ má jẹ́ kí ọkàn yín tètè mì, tabi kí èrò yín dàrú lórí ọ̀rọ̀ pé Ọjọ́ Oluwa ti dé. Kì báà jẹ́ pé ninu ọ̀rọ̀ wa tabi ninu Ẹ̀mí ni wọ́n ti rò pé a sọ ọ́, tabi bóyá ninu àlàyékálàyé kan tabi ìwé kan tí wọ́n rò pé ọ̀dọ̀ wa ni ó ti wá. Ẹ má ṣe jẹ́ kí ẹnikẹ́ni tàn yín jẹ lọ́nàkọnà nípa ọ̀rọ̀ yìí. Nítorí kí ọjọ́ Oluwa tó dé, ọ̀tẹ̀ nípa ti ẹ̀sìn níláti kọ́kọ́ ṣẹlẹ̀, kí Ẹni Ibi nnì, ẹni ègbé nnì sì farahàn.
II. Tes 2:1-3 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Ní ti bíbọ̀ Jesu Kristi Olúwa wa, àti ti ìpéjọ wa sọ́dọ̀ rẹ̀, àwa wí fún yín ará, kí ọkàn yín má ṣe àìbalẹ̀, tàbí kí ẹ má ṣe jáyà nípa àsọtẹ́lẹ̀, ìròyìn tàbí lẹ́tà tí ó lè fi ara jọ èyí tí ó le wá láti ọ̀dọ̀ wa, tí yóò máa wí pé ọjọ́ Olúwa ti dé ná. Ẹ má ṣe jẹ́ kí ẹnikẹ́ni kí ó tàn yín jẹ ní ọ̀nàkọnà, nítorí pé ọjọ́ náà kì yóò dé, bí kò ṣe pé ìṣọ̀tẹ̀ bá kọ́ ṣẹlẹ̀, tí a sì fi ẹni ẹ̀ṣẹ̀ hàn, tí í ṣe ọmọ ègbé.