II. Tes 1:7-9
II. Tes 1:7-9 Bibeli Mimọ (YBCV)
Ati fun ẹnyin, ti a npọ́n loju, isimi pẹlu wa, nigba ifarahàn Jesu Oluwa lati ọrun wá ninu ọwọ́ ina pẹlu awọn angẹli alagbara rẹ̀, Ẹniti yio san ẹsan fun awọn ti kò mọ Ọlọrun, ti nwọn kò si gbà ihinrere Jesu Oluwa wa gbọ́: Awọn ẹniti yio jiya iparun ainipẹkun lati iwaju Oluwa wá, ati lati inu ogo agbara rẹ̀
II. Tes 1:7-9 Yoruba Bible (YCE)
ati láti fún ẹ̀yin tí wọn ń pọ́n lójú, ati àwa náà ní ìsinmi, nígbà tí Oluwa wa, Jesu, bá farahàn láti ọ̀run ninu ọwọ́ iná pẹlu àwọn angẹli tí wọ́n jẹ́ alágbára. Nígbà náà ni yóo gbẹ̀san lára àwọn tí kò mọ Ọlọrun ati àwọn tí kò gba ọ̀rọ̀ ìyìn rere Oluwa wa Jesu. Àwọn yìí ni wọn yóo gba ìdálẹ́bi sí ìparun ayérayé, wọn yóo sì kúrò níwájú Oluwa ati ògo agbára rẹ̀
II. Tes 1:7-9 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Òun yóò sì fi ìtura fún ẹ̀yin tí a ti pọ́n lójú àti fún àwa náà pẹ̀lú. Èyí yóò sì ṣe nígbà ìfarahàn Jesu Olúwa láti ọ̀run wá fún wá nínú ọwọ́ iná pẹ̀lú àwọn angẹli alágbára. Òun yóò fi ìyà jẹ àwọn tí kò mọ Ọlọ́run àti àwọn tí ń ṣe àìgbọ́ràn sí ìhìnrere Jesu Olúwa wa. A ó fi ìparun àìnípẹ̀kun jẹ wọ́n ní yà, a ó sì ṣe wọn mọ̀ kúrò níwájú Olúwa àti inú ògo agbára rẹ̀