II. Tes 1:6-7
II. Tes 1:6-7 Bibeli Mimọ (YBCV)
Bi o ti jẹ pe ohun ododo ni fun Ọlọrun lati fi ipọnju gbẹsan lara awọn ti npọ́n nyin loju, Ati fun ẹnyin, ti a npọ́n loju, isimi pẹlu wa, nigba ifarahàn Jesu Oluwa lati ọrun wá ninu ọwọ́ ina pẹlu awọn angẹli alagbara rẹ̀
Pín
Kà II. Tes 1II. Tes 1:6-7 Yoruba Bible (YCE)
Nítorí ó tọ́ lójú Ọlọrun láti fi ìpọ́njú san ẹ̀san fún àwọn tí wọn ń pọn yín lójú, ati láti fún ẹ̀yin tí wọn ń pọ́n lójú, ati àwa náà ní ìsinmi, nígbà tí Oluwa wa, Jesu, bá farahàn láti ọ̀run ninu ọwọ́ iná pẹlu àwọn angẹli tí wọ́n jẹ́ alágbára.
Pín
Kà II. Tes 1II. Tes 1:6-7 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Olódodo ni Ọlọ́run: Òun yóò pọ́n àwọn tí ń pọ́n yín lójú, lójú, Òun yóò sì fi ìtura fún ẹ̀yin tí a ti pọ́n lójú àti fún àwa náà pẹ̀lú. Èyí yóò sì ṣe nígbà ìfarahàn Jesu Olúwa láti ọ̀run wá fún wá nínú ọwọ́ iná pẹ̀lú àwọn angẹli alágbára.
Pín
Kà II. Tes 1