II. Sam 8:15-18
II. Sam 8:15-18 Bibeli Mimọ (YBCV)
Dafidi si jọba lori gbogbo Israeli; Dafidi si ṣe idajọ ati otitọ fun awọn enia rẹ̀. Joabu ọmọ Seruia li o si nṣe olori ogun; Jehoṣafati ọmọ Ahiludi si nṣe akọwe. Ati Sadoku ọmọ Ahitubu, ati Ahimeleki ọmọ Abiatari, li awọn alufa; Seruia a si ma ṣe akọwe. Benaiah ọmọ Jehoiada li o si nṣe olori awọn Kereti, ati awọn Peleti; awọn ọmọ Dafidi si jẹ alaṣẹ.
II. Sam 8:15-18 Yoruba Bible (YCE)
Bẹ́ẹ̀ ni Dafidi ṣe jọba lórí gbogbo Israẹli, ó sì ń ṣe ẹ̀tọ́ ati òdodo sí gbogbo eniyan, nígbà gbogbo. Joabu, ọmọ Seruaya ni balogun rẹ̀, Jehoṣafati, ọmọ Ahiludi ni alákòóso gbogbo àwọn ìwé àkọsílẹ̀ rẹ̀. Sadoku, ọmọ Ahitubu, ati Ahimeleki, ọmọ Abiatari ni alufaa, Seraaya ni akọ̀wé gbọ̀ngàn ìdájọ́ rẹ̀. Bẹnaya, ọmọ Jehoiada ni olórí àwọn Kereti ati àwọn Peleti (tí ń ṣọ́ ààfin), àwọn ọmọ Dafidi ọkunrin ni wọ́n sì jẹ́ alufaa.
II. Sam 8:15-18 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (BMYO)
Dafidi sì jẹ ọba lórí gbogbo Israẹli; Dafidi sì ṣe ìdájọ́ àti òtítọ́ fún àwọn ènìyàn rẹ̀. Joabu ọmọ Seruiah ni ó sì ń ṣe olórí ogun; Jehoṣafati ọmọ Ahiludi sì ń ṣe akọ̀wé. Sadoku ọmọ Ahitubu, àti Ahimeleki ọmọ Abiatari, ni àwọn àlùfáà; Seraiah a sì máa ṣe akọ̀wé. Benaiah ọmọ Jehoiada ni ó sì ń ṣe olórí àwọn Kereti, àti àwọn Peleti; àwọn ọmọ Dafidi sì jẹ́ aláṣẹ.