II. Sam 8:13-18
II. Sam 8:13-18 Bibeli Mimọ (YBCV)
Dafidi si ni asiki gidigidi nigbati o pada wá ile lati ibi pipa awọn ara Siria li afonifoji iyọ̀, awọn ti o pa jẹ ẹgbãsan enia. O si fi awọn ologun si Edomu; ati ni gbogbo Edomu yika li on si fi ologun si, gbogbo awọn ti o wà ni Edomu si wá sin Dafidi. Oluwa si pa Dafidi mọ nibikibi ti o nlọ. Dafidi si jọba lori gbogbo Israeli; Dafidi si ṣe idajọ ati otitọ fun awọn enia rẹ̀. Joabu ọmọ Seruia li o si nṣe olori ogun; Jehoṣafati ọmọ Ahiludi si nṣe akọwe. Ati Sadoku ọmọ Ahitubu, ati Ahimeleki ọmọ Abiatari, li awọn alufa; Seruia a si ma ṣe akọwe. Benaiah ọmọ Jehoiada li o si nṣe olori awọn Kereti, ati awọn Peleti; awọn ọmọ Dafidi si jẹ alaṣẹ.
II. Sam 8:13-18 Yoruba Bible (YCE)
Dafidi túbọ̀ di olókìkí sí i nígbà tí ó pada dé, láti ibi tí ó ti lọ pa ẹgbaasan-an (18,000) ninu àwọn ará Edomu, ní Àfonífojì Iyọ̀. Ó kọ́ ibùdó àwọn ọmọ ogun káàkiri ilẹ̀ Edomu, gbogbo àwọn ará Edomu sì ń sin Dafidi. OLUWA fún Dafidi ní ìṣẹ́gun ní gbogbo ibi tí ó lọ. Bẹ́ẹ̀ ni Dafidi ṣe jọba lórí gbogbo Israẹli, ó sì ń ṣe ẹ̀tọ́ ati òdodo sí gbogbo eniyan, nígbà gbogbo. Joabu, ọmọ Seruaya ni balogun rẹ̀, Jehoṣafati, ọmọ Ahiludi ni alákòóso gbogbo àwọn ìwé àkọsílẹ̀ rẹ̀. Sadoku, ọmọ Ahitubu, ati Ahimeleki, ọmọ Abiatari ni alufaa, Seraaya ni akọ̀wé gbọ̀ngàn ìdájọ́ rẹ̀. Bẹnaya, ọmọ Jehoiada ni olórí àwọn Kereti ati àwọn Peleti (tí ń ṣọ́ ààfin), àwọn ọmọ Dafidi ọkunrin ni wọ́n sì jẹ́ alufaa.
II. Sam 8:13-18 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Dafidi sì ní òkìkí gidigidi nígbà tí ó padà wá ilé láti ibi pípa àwọn ará Siria ní Àfonífojì Iyọ̀, àwọn tí o pa jẹ́ ẹgbàásàn án ènìyàn. Ó sì fi àwọn ológun sí Edomu; àti ní gbogbo Edomu yíká ni òun sì fi ológun sí, gbogbo àwọn tí ó wà ní Edomu sì wá sin Dafidi, OLúWA sì fún Dafidi ní ìṣẹ́gun níbikíbi tí ó ń lọ. Dafidi sì jẹ ọba lórí gbogbo Israẹli; Dafidi sì ṣe ìdájọ́ àti òtítọ́ fún àwọn ènìyàn rẹ̀. Joabu ọmọ Seruiah ni ó sì ń ṣe olórí ogun; Jehoṣafati ọmọ Ahiludi sì ń ṣe akọ̀wé. Sadoku ọmọ Ahitubu, àti Ahimeleki ọmọ Abiatari, ni àwọn àlùfáà; Seraiah a sì máa ṣe akọ̀wé. Benaiah ọmọ Jehoiada ni ó sì ń ṣe olórí àwọn Kereti, àti àwọn Peleti; àwọn ọmọ Dafidi sì jẹ́ aláṣẹ.