II. Sam 8:1-14

II. Sam 8:1-14 Bibeli Mimọ (YBCV)

O SI ṣe, lẹhin eyi, Dafidi si kọlu awọn Filistini, o si tẹri wọn ba: Dafidi si gbà Metegamma lọwọ awọn Filistini. O si kọlu Moabu, a si fi okùn tita kan diwọ̀n wọn, o si da wọn bu'lẹ; o si ṣe oṣuwọn okun meji ni iye awọn ti on o pa, ati ẹkún oṣuwọn okùn kan ni iye awọn ti yio dá si. Awọn ara Moabu si nsìn Dafidi, nwọn a si ma mu ẹbùn wá. Dafidi si kọlu Hadadeseri ọmọ Rehobu, ọba Soba, bi on si ti nlọ lati gbà ilẹ rẹ̀ pada ti o gbè odo Eufrate. Dafidi si gbà ẹgbẹrun kẹkẹ lọwọ rẹ̀, ati ẹ̃dẹgbẹrin ẹlẹṣin, ati ẹgbãwa awọn ẹlẹsẹ: Dafidi si ja gbogbo ẹṣin kẹkẹ́ wọn wọnni ni pátì, ṣugbọn o da ọgọrun kẹkẹ́ si ninu wọn. Nigbati awọn ara Siria ti Damasku si wá lati ran Hadadeseri ọba Soba lọwọ, Dafidi si pa ẹgbãmọkanla enia ninu awọn ara Siria. Dafidi si fi awọn ologun si Siria ti Damasku: awọn ara Siria si wa sìn Dafidi, nwọn a si ma mu ẹbùn wá. Oluwa si pa Dafidi mọ nibikibi ti o nlọ. Dafidi si gbà aṣà wura ti o wà lara awọn iranṣẹ Hadadeseri, o si ko wọn wá si Jerusalemu. Lati Beta, ati lati Berotai, awọn ilú Hadadeseri, ni Dafidi ọba si ko ọ̀pọlọpọ idẹ wá. Nigbati Toi ọba Hamati si gbọ́ pe Dafidi ti pa gbogbo ogun Hadadeseri, Toi si ran Joramu ọmọ rẹ̀ si Dafidi ọba, lati ki i, ati lati sure fun u, nitoripe o ti ba Hadadeseri jagun, o si ti pa a: nitoriti Hadadeseri sa ti ba Toi jagun. Joramu si ni ohun elo fadaka, ati ohun elo wura, ati ohun elo idẹ li ọwọ́ rẹ̀: Dafidi ọba si fi wọn fun Oluwa, pẹlu fadaka, ati wura ti o ti yà si mimọ́, eyi ti o ti gbà lọwọ awọn orilẹ-ède ti o ti ṣẹgun; Lọwọ Siria ati lọwọ Moabu, ati lọwọ awọn ọmọ Ammoni, ati lọwọ awọn Filistini, ati lọwọ Amaleki, ati ninu ikogun Hadadeseri ọmọ Rehobu ọba Soba. Dafidi si ni asiki gidigidi nigbati o pada wá ile lati ibi pipa awọn ara Siria li afonifoji iyọ̀, awọn ti o pa jẹ ẹgbãsan enia. O si fi awọn ologun si Edomu; ati ni gbogbo Edomu yika li on si fi ologun si, gbogbo awọn ti o wà ni Edomu si wá sin Dafidi. Oluwa si pa Dafidi mọ nibikibi ti o nlọ.

II. Sam 8:1-14 Yoruba Bible (YCE)

Lẹ́yìn náà, Dafidi ọba gbógun ti àwọn ará Filistia, ó ṣẹgun wọn, ó sì gba ìlú Mẹtẹgi-ama lọ́wọ́ wọn. Ó ṣẹgun àwọn ará Moabu bákan náà, ó sì mú kí àwọn tí ó kó lẹ́rú ninu wọn dọ̀bálẹ̀ lórí ilẹ̀ ní ìlà mẹta, ó pa gbogbo àwọn tí wọ́n wà lórí ìlà meji, ó sì dá àwọn tí wọ́n dọ̀bálẹ̀ lórí ìlà kan sí, bẹ́ẹ̀ ni àwọn ará Moabu ṣe di ẹrú rẹ̀, tí wọ́n sì ń san owó ìṣákọ́lẹ̀ fún un. Dafidi sì tún ṣẹgun Hadadeseri, ọmọ Rehobu, ọba Soba, bí ó tí ń lọ láti fi ìdí ìjọba rẹ̀ múlẹ̀ ní ilẹ̀ tí ó wà ní agbègbè odò Yufurate. Ẹẹdẹgbẹsan (1,700) ẹlẹ́ṣin ni Dafidi gbà lọ́wọ́ rẹ̀, ati ọ̀kẹ́ kan àwọn ọmọ ogun tí wọ́n ń fi ẹsẹ̀ rìn. Dafidi dá ẹsẹ̀ àwọn ẹṣin tí ń fa kẹ̀kẹ́ ogun rẹ̀, ṣugbọn ó dá ọgọrun-un (100) sí ninu wọn. Nígbà tí àwọn ará Siria dé láti Damasku tí wọ́n ran Hadadeseri, ọba Soba lọ́wọ́, Dafidi pa ẹgbaa mọkanla (22,000) ninu àwọn ọmọ ogun wọn. Dafidi bá kọ́ àgọ́ àwọn ọmọ ogun kan sí Aramu, ní Damasku, gbogbo àwọn ará Siria sì ń sin Dafidi, wọ́n sì ń san owó ìṣákọ́lẹ̀ fún un. OLUWA fún Dafidi ní ìṣẹ́gun ní gbogbo ibi tí ó lọ. Dafidi gba àwọn apata wúrà tí àwọn ọ̀gágun Hadadeseri fi ń jagun, ó sì kó wọn wá sí Jerusalẹmu. Bákan náà, Dafidi ọba kó ọpọlọpọ idẹ láti Bẹta ati Berotai, ìlú meji ninu àwọn ìlú tí ó wà lábẹ́ ìjọba Hadadeseri. Nígbà tí Toi ọba Hamati gbọ́ pé Dafidi ti ṣẹgun gbogbo àwọn ọmọ ogun Hadadeseri, ó rán Joramu ọmọ rẹ̀ láti kí Dafidi ọba kú oríire, fún ìṣẹ́gun rẹ̀ lórí Hadadeseri, nítorí pé Hadadeseri ti bá Toi jagun ní ọpọlọpọ ìgbà. Joramu mú ọpọlọpọ ẹ̀bùn tí wọ́n fi wúrà ṣe, ati ti fadaka, ati ti idẹ lọ́wọ́ fún Dafidi. Dafidi ọba ya àwọn ẹ̀bùn náà sí mímọ́ fún ìlò ninu ilé OLUWA, pẹlu gbogbo fadaka ati wúrà tí ó rí kó láti gbogbo orílẹ̀-èdè tí ó ti ṣẹgun; àwọn bíi: àwọn ará Edomu, àwọn ará Moabu, àwọn ará Amoni, àwọn ará Filistia, ati àwọn ará Amaleki; pẹlu ìkógun Hadadeseri, ọba Soba. Dafidi túbọ̀ di olókìkí sí i nígbà tí ó pada dé, láti ibi tí ó ti lọ pa ẹgbaasan-an (18,000) ninu àwọn ará Edomu, ní Àfonífojì Iyọ̀. Ó kọ́ ibùdó àwọn ọmọ ogun káàkiri ilẹ̀ Edomu, gbogbo àwọn ará Edomu sì ń sin Dafidi. OLUWA fún Dafidi ní ìṣẹ́gun ní gbogbo ibi tí ó lọ.

II. Sam 8:1-14 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)

Ó sì ṣe, lẹ́yìn èyí, Dafidi sì kọlu àwọn Filistini, ó sì tẹrí wọn ba: Dafidi sì gba Metegamima lọ́wọ́ àwọn Filistini. Dafidi sì kọlu Moabu, ó sì fi okùn títa kan dì wọ́n, ó sì dá wọn dùbúlẹ̀; ó sì ṣe òṣùwọ̀n okùn méjì ni iye àwọn tí yóò dá sí. Àwọn ará Moabu sì ń sin Dafidi, wọn a sì máa mú ẹ̀bùn wá. Dafidi sì kọlu Hadadeseri ọmọ Rehobu, ọba Ṣoba, bí òun sì ti ń lọ láti mú agbára rẹ̀ bọ̀ sípò ni odò Eufurate. Dafidi sì gba ẹgbẹ̀rún kẹ̀kẹ́ lọ́wọ́ rẹ̀, àti ẹ̀ẹ́dẹ́gbàárin ẹlẹ́ṣin, àti ẹgbàáwàá àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀: Dafidi sì já gbogbo àwọn ẹṣin kẹ̀kẹ́ wọn ní pàtì, ṣùgbọ́n ó dá ọgọ́ọ̀rún kẹ̀kẹ́ sí nínú wọn. Nígbà tí àwọn ará Siria ti Damasku sì wá láti ran Hadadeseri ọba Ṣoba lọ́wọ́, Dafidi sì pa ẹgbàá-mọ́kànlá ènìyàn nínú àwọn ará Siria. Dafidi sì fi àwọn ológun sí Siria ti Damasku: àwọn ará Siria sì wá sin Dafidi, wọn a sì máa mú ẹ̀bùn wá, OLúWA sì pa Dafidi mọ́ níbikíbi tí o ń lọ. Dafidi sì gba àṣà wúrà tí ó wà lára àwọn ìránṣẹ́ Hadadeseri, ó sì kó wọn wá sí Jerusalẹmu. Láti Beta, àti láti Berotai, àwọn ìlú Hadadeseri, Ọba Dafidi kó ọ̀pọ̀lọpọ̀ idẹ wá. Nígbà tí Tou ọba Hamati sì gbọ́ pé Dafidi ti pa gbogbo ogun Hadadeseri. Toi sì rán Joramu ọmọ rẹ̀ sí Dafidi ọba, láti kí i, àti láti súre fún un, nítorí pé ó tí bá Hadadeseri jagun, ó sì ti pa á: nítorí tí Hadadeseri sá à ti bá Toi jagun. Joramu sì ni ohun èlò fàdákà, àti ohun èlò wúrà, àti ohun èlò idẹ ní ọwọ́ rẹ̀. Dafidi ọba sì fi wọ́n fún OLúWA pẹ̀lú fàdákà, àti wúrà tí ó yà sí mímọ́, èyí tí ó ti gbà lọ́wọ́ àwọn orílẹ̀-èdè tí ó ti ṣẹ́gun. Lọ́wọ́ Siria àti lọ́wọ́ Moabu àti lọ́wọ́ àwọn ọmọ Ammoni, àti lọ́wọ́ àwọn Filistini, àti lọ́wọ́ Amaleki, àti nínú ìkógun Hadadeseri ọmọ Rehobu ọba Ṣoba. Dafidi sì ní òkìkí gidigidi nígbà tí ó padà wá ilé láti ibi pípa àwọn ará Siria ní Àfonífojì Iyọ̀, àwọn tí o pa jẹ́ ẹgbàásàn án ènìyàn. Ó sì fi àwọn ológun sí Edomu; àti ní gbogbo Edomu yíká ni òun sì fi ológun sí, gbogbo àwọn tí ó wà ní Edomu sì wá sin Dafidi, OLúWA sì fún Dafidi ní ìṣẹ́gun níbikíbi tí ó ń lọ.