II. Sam 7:14-29
II. Sam 7:14-29 Bibeli Mimọ (YBCV)
Emi o ma ṣe baba fun u, on o si ma jẹ ọmọ mi. Bi on ba dẹṣẹ, emi o si fi ọpá enia nà a, ati inà awọn ọmọ enia. Ṣugbọn ãnu mi kì yio yipada kuro lọdọ rẹ̀, gẹgẹ bi emi ti mu u kuro lọdọ Saulu, ti emi ti mu kuro niwaju rẹ. A o si fi idile rẹ ati ijọba rẹ mulẹ niwaju rẹ titi lai: a o si fi idi itẹ rẹ mulẹ titi lai. Gẹgẹ bi gbogbo ọ̀rọ wọnyi, ati gẹgẹ bi gbogbo iran yi, bẹ̃ni Natani si sọ fun Dafidi. Dafidi ọba si wọle lọ, o si duro niwaju Oluwa, o si wipe, Oluwa Ọlọrun, tali emi, ati ki si ni idile mi, ti iwọ fi mu mi di isisiyi? Nkan kekere li eyi sa jasi li oju rẹ, Oluwa Ọlọrun; iwọ si sọ ti idile iranṣẹ rẹ pẹlu ni ti akoko ti o jina. Eyi ha ṣe ìwa enia bi, Oluwa Ọlọrun? Kini Dafidi iba si ma wi si i fun ọ? Iwọ, Oluwa Ọlọrun mọ̀ iranṣẹ rẹ. Nitori ọ̀rọ rẹ, ati gẹgẹ bi ifẹ ọkàn rẹ, ni iwọ ṣe gbogbo nkan nla wọnyi, ki iranṣẹ rẹ ki o le mọ̀. Iwọ si tobi, Oluwa Ọlọrun: kò si si ẹniti o dabi rẹ, kò si si Ọlọrun kan lẹhin rẹ, gẹgẹ bi gbogbo eyi ti awa fi eti wa gbọ́. Orilẹ-ède kan wo li o si mbẹ li aiye ti o dabi awọn enia rẹ, ani Israeli, awọn ti Ọlọrun lọ ràpada lati sọ wọn di enia rẹ̀, ati lati sọ wọn li orukọ, ati lati ṣe nkan nla fun nyin, ati nkan iyanu fun ilẹ rẹ, niwaju awọn enia rẹ, ti iwọ ti ràpada fun ara rẹ lati Egipti wá, ani awọn orilẹ-ède ati awọn oriṣa wọn. Iwọ si fi idi awọn enia rẹ, ani Israeli, kalẹ fun ara rẹ lati sọ wọn di enia rẹ titi lai: iwọ Oluwa si wa di Ọlọrun fun wọn. Njẹ, Oluwa Ọlọrun, jẹ ki ọ̀rọ na ti iwọ sọ niti iranṣẹ rẹ, ati niti idile rẹ̀, ki o duro titi lai, ki o si ṣe bi iwọ ti wi. Jẹ ki orukọ rẹ ki o ga titi lai, pe, Oluwa awọn ọmọ-ogun li Ọlọrun lori Israeli: si jẹ ki a fi idile Dafidi iranṣẹ rẹ mulẹ niwaju rẹ. Nitoripe iwọ, Oluwa awọn ọmọ-ogun, Ọlọrun Israeli ti sọ li eti iranṣẹ rẹ, pe, emi o ṣe idile kan fun ọ: nitorina ni iranṣẹ rẹ si ṣe ni i li ọkàn rẹ̀ lati gbadura yi si ọ. Njẹ, Oluwa Ọlọrun, iwọ li Ọlọrun na, ọrọ rẹ wọnni yio si jasi otitọ, iwọ si jẹ'jẹ nkan rere yi fun iranṣẹ rẹ: Njẹ, jẹ ki o wù ọ lati bukún idile iranṣẹ rẹ, ki o wà titi lai niwaju rẹ: nitori iwọ, Oluwa Ọlọrun, li o ti sọ ọ: si jẹ ki ibukún ki o wà ni idile iranṣẹ rẹ titi lai, nipasẹ ibukún rẹ.
II. Sam 7:14-29 Yoruba Bible (YCE)
N óo jẹ́ baba fún un, yóo sì jẹ́ ọmọ mi. Bí ó bá ṣẹ̀, n óo bá a wí, n óo sì jẹ ẹ́ níyà, bí baba ti í ṣe sí ọmọ rẹ̀. Ṣugbọn n kò ní káwọ́ ìfẹ́ ńlá mi kúrò lára rẹ̀, bí mo ti ká a kúrò lára Saulu, tí mo sì yọ ọ́ lóyè, kí n tó fi í jọba. Ìran rẹ kò ní parun, arọmọdọmọ rẹ ni yóo sì máa jọba títí ayé, ìjọba rẹ̀ yóo sì wà títí lae.’ ” Natani bá tọ Dafidi lọ, ó sì sọ gbogbo nǹkan tí OLUWA fi hàn án fún un. Dafidi ọba bá wọlé, ó jókòó níwájú OLUWA, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí gbadura pé, “Ìwọ OLUWA Ọlọrun! Kí ni mo jẹ́, kí ni ilé mi jámọ́ tí o fi gbé mi dé ipò yìí? Sibẹsibẹ, kò jẹ́ nǹkankan lójú rẹ, OLUWA Ọlọrun, o ti ṣèlérí fún èmi iranṣẹ rẹ nípa arọmọdọmọ mi, nípa ọjọ́ iwájú, o sì ti fihàn. Kí ni mo tún lè sọ? O ṣá ti mọ̀ mí, èmi iranṣẹ rẹ, OLUWA Ọlọrun! Nítorí ìlérí ati ìfẹ́ ọkàn rẹ ni o fi ṣe gbogbo nǹkan ńlá wọnyi, kí iranṣẹ rẹ lè mọ̀ nípa wọn. OLUWA Ọlọrun, o tóbi gan-an! Kò sí ẹni tí ó dàbí rẹ, bẹ́ẹ̀ ni kò sí Ọlọrun mìíràn lẹ́yìn rẹ, nítorí gbogbo ohun tí a ti fi etí wa gbọ́. Kò sí orílẹ̀-èdè mìíràn ní gbogbo ayé, tí ó dàbí Israẹli, tí o yọ kúrò ní oko ẹrú láti fi wọ́n ṣe eniyan rẹ. O ti mú kí òkìkí Israẹli kàn nípa àwọn nǹkan ńláńlá, ati nǹkan ìyanu tí o ti ṣe fún wọn, nípa lílé àwọn eniyan orílẹ̀-èdè mìíràn jáde tàwọn ti oriṣa wọn, bí àwọn eniyan rẹ ti ń tẹ̀síwájú. O ti yan àwọn ọmọ Israẹli fún ara rẹ, láti jẹ́ eniyan rẹ, o sì ti di Ọlọrun wọn títí lae. “Ǹjẹ́ nisinsinyii, OLUWA Ọlọrun, jẹ́ kí ìlérí tí o ṣe nípa èmi ati arọmọdọmọ mi ṣẹ nígbà gbogbo, sì ṣe ohun tí o ti ṣèlérí pé o óo ṣe. Orúkọ rẹ yóo sì lókìkí títí lae, gbogbo eniyan ni yóo sì máa wí títí lae pé, OLUWA àwọn ọmọ ogun ni Ọlọrun Israẹli. O óo sì mú kí arọmọdọmọ mi wà níwájú rẹ títí laelae. OLUWA àwọn ọmọ ogun, Ọlọrun Israẹli, pẹlu ìgboyà ni mo fi gbadura mi yìí sí ọ, nítorí pé o ti fi gbogbo nǹkan wọnyi han èmi iranṣẹ rẹ, o sì ti ṣèlérí pé o óo sọ ìdílé mi di ìdílé ńlá. “Ǹjẹ́ nisinsinyii, OLUWA Ọlọrun, ìwọ nìkan ni Ọlọ́run, òtítọ́ ni ọ̀rọ̀ rẹ, o sì ti ṣèlérí ohun rere yìí fún iranṣẹ rẹ. Mò ń bẹ̀bẹ̀ pé kí o bukun arọmọdọmọ mi, kí wọ́n lè máa bá ojurere rẹ pàdé nígbà gbogbo. Ìwọ OLUWA Ọlọrun ni o ṣèlérí yìí, ibukun rẹ yóo sì máa wà lórí arọmọdọmọ mi títí laelae.”
II. Sam 7:14-29 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Èmi ó máa ṣe baba fún un, òun yóò sì máa jẹ́ ọmọ mi. Bí òun bá dẹ́ṣẹ̀, èmi yóò sì fi ọ̀pá ènìyàn nà án, àti ìnà àwọn ọmọ ènìyàn. Ṣùgbọ́n àánú mi kì yóò yípadà kúrò lọ́dọ̀ rẹ̀, gẹ́gẹ́ bí èmi ti mú un kúrò lọ́dọ̀ Saulu, tí èmi ti mú kúrò níwájú rẹ. A ó sì fi ìdílé rẹ àti ìjọba rẹ múlẹ̀ níwájú rẹ títí láé: a ó sì fi ìdí ìtẹ́ rẹ múlẹ̀ títí láé.’ ” Gẹ́gẹ́ bí gbogbo ọ̀rọ̀ wọ̀nyí, àti gẹ́gẹ́ bí gbogbo ìran yìí, bẹ́ẹ̀ ni Natani sì sọ fún Dafidi. Dafidi ọba sì wọlé lọ, ó sì dúró níwájú OLúWA, ó sì wí pé: “OLúWA Olódùmarè, ta ni èmi, àti kí sì ni ìdílé mi, tí ìwọ fi mú mi di ìsinsin yìí? Nǹkan kékeré ni èyí sá à jásí lójú rẹ, OLúWA Olódùmarè; ìwọ sì ti sọ nípa ìdílé ìránṣẹ́ rẹ pẹ̀lú ní ti àkókò tí o jìnnà. Èyí ha ṣe ìwà ènìyàn bí, OLúWA Olódùmarè? “Àti kín ní ó tún kù tí Dafidi ìbá tún máa wí fún ọ? Ìwọ, OLúWA Olódùmarè mọ̀ ìránṣẹ́ rẹ. Nítorí ọ̀rọ̀ rẹ, àti gẹ́gẹ́ bí ìfẹ́ ọkàn rẹ, ni ìwọ ṣe ṣe gbogbo nǹkan ńlá wọ̀nyí, kí ìránṣẹ́ rẹ lè mọ̀. “Ìwọ sì tóbi, OLúWA Olódùmarè! Kò sì sí ẹni tí ó dàbí rẹ, kò sì sí Ọlọ́run kan lẹ́yìn rẹ̀, gẹ́gẹ́ bí gbogbo èyí tí àwa fi etí wá gbọ́. Orílẹ̀-èdè kan wo ni ó sì ń bẹ ní ayé tí ó dàbí àwọn ènìyàn rẹ, àní Israẹli, àwọn tí Ọlọ́run lọ rà padà láti sọ wọ́n di ènìyàn rẹ̀, àti láti sọ wọ́n ní orúkọ, àti láti ṣe nǹkan ńlá fún un yín, àti nǹkan ìyanu fún ilé rẹ̀, níwájú àwọn ènìyàn rẹ, tí ìwọ ti rà padà fún ara rẹ láti Ejibiti wá, àní àwọn orílẹ̀-èdè àti àwọn òrìṣà wọn. Ìwọ sì fi ìdí àwọn ènìyàn rẹ, àní Israẹli kalẹ̀ fún ara rẹ láti sọ wọ́n di ènìyàn rẹ títí láé; ìwọ OLúWA sì wá di Ọlọ́run fún wọn. “Ǹjẹ́, OLúWA Ọlọ́run, jẹ́ kí ọ̀rọ̀ náà tí ìwọ sọ ní ti ìránṣẹ́ rẹ, àti ní ti ìdílé rẹ̀, kí ó dúró títí láé, kí ó sí ṣe bí ìwọ ti wí. Jẹ́ kí orúkọ rẹ ó ga títí láé, pé, ‘OLúWA àwọn ọmọ-ogun ni Ọlọ́run lórí Israẹli!’ Sì jẹ́ kí a fi ìdílé Dafidi ìránṣẹ́ rẹ múlẹ̀ níwájú rẹ. “Nítorí pé ìwọ, OLúWA àwọn ọmọ-ogun, Ọlọ́run Israẹli ti sọ létí ìránṣẹ́ rẹ, pé, ‘Èmí ó kọ́ ilé kan fún ọ.’ Nítorí náà ni ìránṣẹ́ rẹ sì ṣe ní i lọ́kàn rẹ̀ láti gbàdúrà yìí sí ọ. Ǹjẹ́, OLúWA Olódùmarè, ìwọ ni Ọlọ́run náà, àwọn ọ̀rọ̀ rẹ sì jásí òtítọ́, ìwọ sì jẹ́ ẹ̀jẹ́ nǹkan rere yìí fún ìránṣẹ́ rẹ. Ǹjẹ́, jẹ́ kí ó wù ọ́ láti bùkún ìdílé ìránṣẹ́ rẹ, kí ó wà títí láé níwájú rẹ: nítorí ìwọ, OLúWA Olódùmarè, ni ó ti sọ ọ́: sì jẹ́ kí ìbùkún wà ní ìdílé ìránṣẹ́ rẹ títí láé, nípasẹ̀ ìbùkún rẹ.”