II. Sam 6:13-15
II. Sam 6:13-15 Bibeli Mimọ (YBCV)
O si ṣe, nigbati awọn enia ti o rù apoti-ẹri Oluwa ba si ṣi ẹsẹ mẹfa, on a si fi malu ati ẹran abọpa rubọ. Dafidi si fi gbogbo agbara rẹ̀ jó niwaju Oluwa; Dafidi si wọ̀ efodu ọgbọ̀. Bẹ̃ni Dafidi ati gbogbo ile Israeli si gbe apoti-ẹri Oluwa goke wá, ti awọn ti iho ayọ̀, ati pẹlu iro ipè.
II. Sam 6:13-15 Yoruba Bible (YCE)
Lẹ́yìn tí àwọn tí wọ́n ru àpótí ẹ̀rí náà ti gbé ìṣísẹ̀ mẹfa, Dafidi dá wọn dúró, ó sì fi akọ mààlúù kan ati ọmọ mààlúù àbọ́pa kan rúbọ sí OLUWA. Dafidi sán aṣọ mọ́dìí, ó sì ń jó pẹlu gbogbo agbára níwájú OLUWA. Bẹ́ẹ̀ ni ọba ati gbogbo àwọn ọmọ Israẹli ṣe gbé àpótí ẹ̀rí OLUWA wọ Jerusalẹmu, pẹlu ìhó ayọ̀ ati ìró fèrè.
II. Sam 6:13-15 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Ó sì ṣe nígbà tí àwọn ènìyàn tí ó ru àpótí ẹ̀rí OLúWA bá sì ṣí ẹsẹ̀ mẹ́fà, òun a sì fi màlúù àti ẹran àbọ́pa rú ẹbọ. Dafidi sì fi gbogbo agbára rẹ̀ jó níwájú OLúWA; Dafidi sì wọ efodu ọ̀gbọ̀. Bẹ́ẹ̀ ni Dafidi àti gbogbo ilé Israẹli sì gbé àpótí ẹ̀rí OLúWA gòkè wá, pẹ̀lú ìhó ayọ̀, àti pẹ̀lú ìró ìpè.