II. Sam 6:12-18
II. Sam 6:12-18 Bibeli Mimọ (YBCV)
A si rò fun Dafidi ọba, pe, Oluwa ti bukún fun ile Obedi-Edomu, ati gbogbo eyi ti iṣe tirẹ̀, nitori apoti-ẹri Ọlọrun. Dafidi si lọ, o si mu apoti-ẹri Ọlọrun na goke lati ile Obedi-Edomu wá si ilu Dafidi ton ti ayọ̀. O si ṣe, nigbati awọn enia ti o rù apoti-ẹri Oluwa ba si ṣi ẹsẹ mẹfa, on a si fi malu ati ẹran abọpa rubọ. Dafidi si fi gbogbo agbara rẹ̀ jó niwaju Oluwa; Dafidi si wọ̀ efodu ọgbọ̀. Bẹ̃ni Dafidi ati gbogbo ile Israeli si gbe apoti-ẹri Oluwa goke wá, ti awọn ti iho ayọ̀, ati pẹlu iro ipè. Bi apoti-ẹri Oluwa si ti wọ̀ ilu Dafidi wá; Mikali ọmọbinrin Saulu si wò lati oju ferese, o si ri Dafidi ọba nfò soke o si njo niwaju Oluwa; on si kẹgàn rẹ̀ li ọkàn rẹ̀. Nwọn si mu apoti-ẹri Oluwa na wá, nwọn si gbe e kalẹ sipò rẹ̀ larin agọ na ti Dafidi pa fun u: Dafidi si rubọ sisun ati ẹbọ irẹpọ̀ niwaju Oluwa. Dafidi si pari iṣẹ ẹbọ sisun ati ẹbọ irẹpọ̀ na, o si sure fun awọn enia na li orukọ Oluwa awọn ọmọ-ogun.
II. Sam 6:12-18 Yoruba Bible (YCE)
Wọ́n bá lọ sọ fún Dafidi pé, “OLUWA ti bukun Obedi Edomu, ati gbogbo ohun tí ó ní, nítorí pé àpótí ẹ̀rí OLUWA wà ní ilé rẹ̀.” Dafidi bá lọ gbé àpótí ẹ̀rí náà kúrò ní ilé rẹ̀ wá sí Jerusalẹmu, pẹlu àjọyọ̀ ńlá. Lẹ́yìn tí àwọn tí wọ́n ru àpótí ẹ̀rí náà ti gbé ìṣísẹ̀ mẹfa, Dafidi dá wọn dúró, ó sì fi akọ mààlúù kan ati ọmọ mààlúù àbọ́pa kan rúbọ sí OLUWA. Dafidi sán aṣọ mọ́dìí, ó sì ń jó pẹlu gbogbo agbára níwájú OLUWA. Bẹ́ẹ̀ ni ọba ati gbogbo àwọn ọmọ Israẹli ṣe gbé àpótí ẹ̀rí OLUWA wọ Jerusalẹmu, pẹlu ìhó ayọ̀ ati ìró fèrè. Bí wọ́n ti gbé àpótí ẹ̀rí náà wọ inú ìlú Dafidi, Mikali ọmọ Saulu yọjú wo òde láti ojú fèrèsé, ó rí Dafidi ọba tí ó ń jó tí ó sì ń fò sókè níwájú OLUWA, Mikali sì kẹ́gàn rẹ̀ ninu ọkàn rẹ̀. Wọ́n gbé àpótí ẹ̀rí náà wọnú ìlú, wọ́n sì gbé e sí ààyè rẹ̀, ninu àgọ́ tí Dafidi ti kọ́ sílẹ̀ fún un. Dafidi sì rú ẹbọ sísun ati ẹbọ alaafia sí OLUWA. Nígbà tí ó rú ẹbọ tán, ó súre fún àwọn eniyan náà ní orúkọ OLUWA àwọn ọmọ ogun.
II. Sam 6:12-18 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
A sì rò fún Dafidi ọba pé, “OLúWA ti bùkún fún ilé Obedi-Edomu, àti gbogbo èyí tí í ṣe tirẹ̀, nítorí àpótí ẹ̀rí Ọlọ́run.” Dafidi sì lọ, ó sì mú àpótí ẹ̀rí náà gòkè láti ilé Obedi-Edomu wá sí ìlú Dafidi pẹ̀lú ayọ̀. Ó sì ṣe nígbà tí àwọn ènìyàn tí ó ru àpótí ẹ̀rí OLúWA bá sì ṣí ẹsẹ̀ mẹ́fà, òun a sì fi màlúù àti ẹran àbọ́pa rú ẹbọ. Dafidi sì fi gbogbo agbára rẹ̀ jó níwájú OLúWA; Dafidi sì wọ efodu ọ̀gbọ̀. Bẹ́ẹ̀ ni Dafidi àti gbogbo ilé Israẹli sì gbé àpótí ẹ̀rí OLúWA gòkè wá, pẹ̀lú ìhó ayọ̀, àti pẹ̀lú ìró ìpè. Bí àpótí ẹ̀rí OLúWA sì ti wọ ìlú Dafidi wá; Mikali ọmọbìnrin Saulu sì wo láti ojú fèrèsé, ó sì rí Dafidi ọba ń fò sókè ó sì ń jó níwájú OLúWA; òun sì kẹ́gàn rẹ̀ ní ọkàn rẹ̀. Wọ́n sì mú àpótí ẹ̀rí OLúWA náà wá, wọ́n sì gbé e kalẹ̀ sípò rẹ̀ láàrín àgọ́ náà tí Dafidi pa fún un: Dafidi sì rú ẹbọ sísun àti ẹbọ ìrẹ́pọ̀ níwájú OLúWA. Dafidi sì parí ìṣe ẹbọ sísun àti ẹbọ ìrẹ́pọ̀ náà, ó sì súre fún àwọn ènìyàn náà ní orúkọ OLúWA àwọn ọmọ-ogun.