II. Sam 6:1-14
II. Sam 6:1-14 Bibeli Mimọ (YBCV)
DAFIDI si tun ko gbogbo awọn akọni ọkunrin ni Israeli jọ, nwọn si jẹ ẹgbã mẹ̃dogun. Dafidi si dide, o si lọ, ati gbogbo awọn enia ti mbẹ lọdọ rẹ̀, lati Baale ti Juda wá, lati mu apoti-ẹri Ọlọrun ti ibẹ wá, eyi ti a npè orukọ rẹ̀ ni orukọ Oluwa awọn ọmọ-ogun ti o joko lãrin awọn Kerubu. Nwọn si gbe apoti-ẹri Ọlọrun na gun kẹkẹ́ titun kan, nwọn si mu u lati ile Abinadabu wá, eyi ti o wà ni Gibea: Ussa ati Ahio, awọn ọmọ Abinadabu si ndà kẹkẹ́ titun na. Nwọn si mu u lati ile Abinadabu jade wá, ti o wà ni Gibea, pẹlu apoti-ẹri Ọlọrun; Ahio si nrìn niwaju apoti-ẹri na. Dafidi ati gbogbo ile Israeli si ṣire niwaju Oluwa lara gbogbo oniruru elò orin ti a fi igi arere ṣe, ati lara duru, ati lara psalteri, ati lara timbreli, ati lara korneti, ati lara aro. Nigbati nwọn si de ibi ipakà Nakoni, Ussa si nà ọwọ́ rẹ̀ si apoti-ẹri Ọlọrun, o si dì i mu, nitoriti malu kọsẹ. Ibinu Oluwa si ru si Ussa; Ọlọrun si pa a nibẹ nitori iṣiṣe rẹ̀; nibẹ li o si kú li ẹba apoti-ẹri Ọlọrun. Inu Dafidi si bajẹ nitoriti Oluwa ke Ussa kuro: o si pe orukọ ibẹ na ni Peresi-Ussa titi o fi di oni yi. Dafidi si bẹru Oluwa ni ijọ na, o si wipe, Apoti-ẹri Oluwa yio ti ṣe tọ̀ mi wá? Dafidi kò si fẹ mu apoti-ẹri Oluwa sọdọ rẹ̀ si ilu Dafidi: ṣugbọn Dafidi si mu u yà si ile Obedi-Edomu ara Gati. Apoti-ẹri Oluwa si gbe ni ile Obedi-Edomu ara Gati li oṣu mẹta: Oluwa si bukún fun Obedi-Edomu, ati gbogbo ile rẹ̀. A si rò fun Dafidi ọba, pe, Oluwa ti bukún fun ile Obedi-Edomu, ati gbogbo eyi ti iṣe tirẹ̀, nitori apoti-ẹri Ọlọrun. Dafidi si lọ, o si mu apoti-ẹri Ọlọrun na goke lati ile Obedi-Edomu wá si ilu Dafidi ton ti ayọ̀. O si ṣe, nigbati awọn enia ti o rù apoti-ẹri Oluwa ba si ṣi ẹsẹ mẹfa, on a si fi malu ati ẹran abọpa rubọ. Dafidi si fi gbogbo agbara rẹ̀ jó niwaju Oluwa; Dafidi si wọ̀ efodu ọgbọ̀.
II. Sam 6:1-14 Yoruba Bible (YCE)
Dafidi tún pe gbogbo àwọn akikanju ninu àwọn ọmọ ogun Israẹli jọ; wọ́n jẹ́ ọ̀kẹ́ kan ati ẹgbaarun (30,000). Ó kó wọn lọ sí Baala ní Juda láti gbé àpótí ẹ̀rí Ọlọrun wá sí Jerusalẹmu. Orúkọ OLUWA àwọn ọmọ ogun ni wọ́n fi ń pe àpótí ẹ̀rí náà, ìtẹ́ rẹ̀ sì wà lórí àwọn Kerubu tí ó wà lókè àpótí náà. Wọ́n gbé àpótí ẹ̀rí jáde kúrò ní ilé Abinadabu tí ó wà lórí òkè, wọ́n sì gbé e ka orí kẹ̀kẹ́ tuntun kan. Usa ati Ahio ọmọ Abinadabu sì ń ti kẹ̀kẹ́ náà; Ahio ni ó ṣáájú rẹ̀. Dafidi ati gbogbo àwọn ọmọ Israẹli bẹ̀rẹ̀ sí jó níwájú OLUWA, wọ́n sì ń kọrin pẹlu gbogbo agbára wọn. Wọ́n ń lu àwọn ohun èlò orin olókùn tí wọ́n ń pè ní hapu, ati lire; ati ìlù, ati ṣẹ̀kẹ̀rẹ̀ ati aro. Bí wọ́n ti dé ibi ìpakà Nakoni, àwọn mààlúù tí ń fa kẹ̀kẹ́ tí àpótí ẹ̀rí wà lórí rẹ̀ kọsẹ̀, Usa bá yára di àpótí ẹ̀rí náà mú. Inú bí OLUWA sí Usa, OLUWA sì lù ú pa nítorí pé ó fi ọwọ́ kan àpótí ẹ̀rí náà. Usa kú sẹ́gbẹ̀ẹ́ àpótí ẹ̀rí náà. Inú bí Dafidi gidigidi nítorí pé OLUWA lu Usa pa. Láti ìgbà náà ni wọ́n ti ń pe ibẹ̀ ní Peresi Usa, títí di òní olónìí. Ẹ̀rù OLUWA ba Dafidi ní ọjọ́ náà, ó sì wí pé, “Báwo ni n óo ṣe gbé àpótí ẹ̀rí OLUWA wá sọ́dọ̀ mi?” Ọkàn rẹ̀ bá yipada, ó pinnu pé òun kò ní gbé e lọ sí Jerusalẹmu, ìlú Dafidi mọ́. Dípò bẹ́ẹ̀, ó gbé e lọ sí ilé Obedi Edomu, ará ìlú Gati. Àpótí ẹ̀rí OLUWA náà wà níbẹ̀ fún oṣù mẹta, OLUWA sì bukun Obedi Edomu ati ìdílé rẹ̀. Wọ́n bá lọ sọ fún Dafidi pé, “OLUWA ti bukun Obedi Edomu, ati gbogbo ohun tí ó ní, nítorí pé àpótí ẹ̀rí OLUWA wà ní ilé rẹ̀.” Dafidi bá lọ gbé àpótí ẹ̀rí náà kúrò ní ilé rẹ̀ wá sí Jerusalẹmu, pẹlu àjọyọ̀ ńlá. Lẹ́yìn tí àwọn tí wọ́n ru àpótí ẹ̀rí náà ti gbé ìṣísẹ̀ mẹfa, Dafidi dá wọn dúró, ó sì fi akọ mààlúù kan ati ọmọ mààlúù àbọ́pa kan rúbọ sí OLUWA. Dafidi sán aṣọ mọ́dìí, ó sì ń jó pẹlu gbogbo agbára níwájú OLUWA.
II. Sam 6:1-14 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Dafidi sì tún kó gbogbo àwọn akọni ọkùnrin ní Israẹli jọ, wọ́n sì jẹ́ ẹgbàá-mẹ́ẹ̀ẹ́dógún. Dafidi sì dìde, ó sì lọ àti gbogbo àwọn ènìyàn tí ń bẹ́ lọ́dọ̀ rẹ́, láti Baalahi ní Juda wá, láti mú àpótí ẹ̀rí Ọlọ́run tí ibẹ̀ wá, èyí tí a ń pe orúkọ rẹ̀ ní orúkọ OLúWA àwọn ọmọ-ogun tí ó jókòó láàrín àwọn kérúbù. Wọ́n sì gbé àpótí ẹ̀rí Ọlọ́run náà gun kẹ̀kẹ́ tuntun kan, wọ́n sì mú un láti ilé Abinadabu wá, èyí tí ó wà ní Gibeah: Ussa àti Ahio, àwọn ọmọ Abinadabu sì ń dá kẹ̀kẹ́ tuntun náà. Wọ́n sì mú un láti ilé Abinadabu jáde wá, tí ó wà ní Gibeah, pẹ̀lú àpótí ẹ̀rí Ọlọ́run: Ahio sì ń rìn níwájú àpótí ẹ̀rí náà. Dafidi àti gbogbo ilé Israẹli sì ṣiré níwájú OLúWA lára gbogbo onírúurú ohun èlò orin tí a fi igi arère ṣe àti lára ìlù haapu, ní ara tambori, sisitirumu àti lára kimbali. Nígbà tí wọ́n dé sí ilẹ̀ ìpakà Nakoni, Ussa sì na ọwọ́ rẹ̀ sí àpótí ẹ̀rí Ọlọ́run, ó sì dìímú, nítorí tí màlúù kọsẹ̀. Ìbínú OLúWA sì ru sí Ussa; Ọlọ́run sì pa á níbẹ̀ nítorí ìṣísẹ̀ rẹ̀; níbẹ̀ ni ó sì kù ní ẹ̀bá àpótí ẹ̀rí Ọlọ́run. Inú Dafidi sì bàjẹ́ nítorí tí OLúWA gé Ussa kúrò: ó sì pe orúkọ ibẹ̀ ní Pereṣi-Uṣa títí ó fi di òní yìí. Dafidi sì bẹ̀rù OLúWA ní ọjọ́ náà, ó sì wí pé, “Àpótí ẹ̀rí OLúWA yóò ti ṣe tọ̀ mí wá?” Dafidi kò sì fẹ́ mú àpótí ẹ̀rí OLúWA sọ́dọ̀ rẹ̀ sí ìlú Dafidi; ṣùgbọ́n Dafidi sì mú un yà sí ilé Obedi-Edomu ará Gitti. Àpótí ẹ̀rí OLúWA sì gbé ní ilé Obedi-Edomu ará Gitti ní oṣù mẹ́ta; OLúWA sì bùkún fún Obedi-Edomu, àti gbogbo ilé rẹ̀. A sì rò fún Dafidi ọba pé, “OLúWA ti bùkún fún ilé Obedi-Edomu, àti gbogbo èyí tí í ṣe tirẹ̀, nítorí àpótí ẹ̀rí Ọlọ́run.” Dafidi sì lọ, ó sì mú àpótí ẹ̀rí náà gòkè láti ilé Obedi-Edomu wá sí ìlú Dafidi pẹ̀lú ayọ̀. Ó sì ṣe nígbà tí àwọn ènìyàn tí ó ru àpótí ẹ̀rí OLúWA bá sì ṣí ẹsẹ̀ mẹ́fà, òun a sì fi màlúù àti ẹran àbọ́pa rú ẹbọ. Dafidi sì fi gbogbo agbára rẹ̀ jó níwájú OLúWA; Dafidi sì wọ efodu ọ̀gbọ̀.