II. Sam 5:6-7
II. Sam 5:6-7 Bibeli Mimọ (YBCV)
Ati ọba ati awọn ọmọkunrin rẹ̀ si lọ Jerusalemu sọdọ awọn ara Jebusi, awọn enia ilẹ na: awọn ti o si ti wi fun Dafidi pe, Bikoṣepe iwọ ba mu awọn afọju ati awọn arọ kuro, iwọ ki yio wọ ìhin wá: nwọn si wipe, Dafidi ki yio lè wá sihin. Ṣugbọn Dafidi si fi agbara gbà ilu odi Sioni: eyi na ni iṣe ilu Dafidi.
II. Sam 5:6-7 Yoruba Bible (YCE)
Nígbà tí ó yá, Dafidi ati àwọn ọmọ ogun rẹ̀ gbógun ti ìlú Jerusalẹmu. Àwọn ará Jebusi tí wọn ń gbé ibẹ̀ nígbà náà wí fún Dafidi pé, “O kò lè wọ inú ìlú yìí wá, àwọn afọ́jú ati àwọn arọ lásán ti tó láti lé ọ dànù.” Wọ́n lérò pé Dafidi kò le ṣẹgun ìlú náà. Ṣugbọn Dafidi jagun gba Sioni, ìlú olódi wọn. Sioni sì di ibi tí wọn ń pè ní ìlú Dafidi.
II. Sam 5:6-7 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Àti ọba àti àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ sì lọ sí Jerusalẹmu sọ́dọ̀ àwọn ará Jebusi, àwọn ènìyàn ilẹ̀ náà; àwọn tí ó sì ti wí fún Dafidi pé, “Bí kò ṣe pé ìwọ bá mú àwọn afọ́jú àti àwọn arọ kúrò, ìwọ kì yóò wọ ìhín wá” wọ́n sì wí pé, “Dafidi kì yóò lè wá síhìn-ín.” Ṣùgbọ́n Dafidi fi agbára gba ìlú odi Sioni: èyí náà ni í ṣe ìlú Dafidi.