Skip to content
Àmì Ìdánimọ̀ Ohun-èlò Bíbélì

Ṣe àfiwé gbogbo èyà

II. Sam 5:2YBCV(Bibeli Mimọ)

Ati nigba atijọ, nigbati Saulu fi jọba lori wa, iwọ ni ẹniti ima ko Israeli jade, iwọ ni si ma mu wọn bọ̀ wá ile: Oluwa si wi fun ọ pe, Iwọ o bọ́ Israeli awọn enia mi, iwọ o si jẹ olori fun Israeli.

II. Sam 5:2BMYO(Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)

Àti nígbà àtijọ́, nígbà tí Saulu fi jẹ ọba lórí wa, ìwọ ni ẹni tí ó máa ń kó Israẹli jáde, ìwọ sì ni ó máa ń mú wọn bọ̀ wá ilé: OLúWA sì wí fún ọ pé, ‘Ìwọ yóò ṣe olùṣọ́ Israẹli àwọn ènìyàn mi, ìwọ yóò sì jẹ́ olórí fún Israẹli.’ ”

II. Sam 5:2YCE(Yoruba Bible)

Látẹ̀yìn wá, nígbà tí Saulu pàápàá wà lórí oyè, ìwọ ni o máa ń kó àwọn ọmọ Israẹli lọ sógun. OLUWA sì ti ṣèlérí fún ọ pé, ìwọ ni o óo jẹ́ aṣiwaju àwọn eniyan rẹ̀, ati ọba wọn.”