II. Sam 4:5-8
II. Sam 4:5-8 Bibeli Mimọ (YBCV)
Awọn ọmọ Rimmoni, ara Beeroti, Rekabu ati Baana si lọ, nwọn si wá si ile Iṣboṣeti li ọsangangan, on si dubulẹ lori ibusun kan li ọjọkanri. Si wõ, nwọn si wá si arin ile na, nwọn si ṣe bi ẹnipe nwọn nfẹ mu alikama; nwọn si gun u labẹ inu: Rekabu ati Baana arakunrin rẹ̀ si sa lọ. Nigbati nwọn wọ ile na lọ, on si dubulẹ lori ibusun rẹ̀ ninu iyẹwu rẹ̀, nwọn si lu u pa, nwọn si bẹ ẹ li ori, nwọn gbe ori rẹ̀, nwọn si fi gbogbo oru rìn ni pẹtẹlẹ na. Nwọn si gbe ori Iṣboṣeti tọ̀ Dafidi wá ni Hebroni, nwọn si wi fun ọba pe, Wõ, ori Iṣboṣeti ọmọ Saulu ọta rẹ, ti o ti nwá ẹmi rẹ kiri; Oluwa ti gbẹ̀san fun ọba oluwa mi loni lara Saulu ati lara iru-ọmọ rẹ̀.
II. Sam 4:5-8 Yoruba Bible (YCE)
Ní ọjọ́ kan, Rekabu ati Baana, àwọn ọmọ Rimoni ará Beeroti, gbéra, wọ́n lọ sí ilé Iṣiboṣẹti, wọ́n débẹ̀ ní ọwọ́ ọ̀sán, ní àkókò tí Iṣiboṣẹti ń sun oorun ọ̀sán lọ́wọ́. Oorun ti gbé obinrin tí ó wà ní ẹnu ọ̀nà, tí ń fẹ́ ọkà lọ́wọ́ lọ, ó sùn lọ fọnfọn. Rekabu ati Baana bá rọra yọ́ wọlé. Nígbà tí wọ́n wọlé, wọ́n bá a níbi tí ó sùn sí lórí ibùsùn ninu yàrá rẹ̀, wọ́n lù ú pa, wọ́n sì gé orí rẹ̀. Wọ́n gbé orí rẹ̀, wọ́n gba ọ̀nà àfonífojì odò Jọdani lọ, wọ́n sì fi gbogbo òru ọjọ́ náà rìn. Nígbà tí wọ́n dé Heburoni, wọ́n gbé orí rẹ̀ tọ Dafidi ọba lọ, wọ́n sì wí fún un pé, “Orí Iṣiboṣẹti, ọmọ Saulu, ọ̀tá rẹ, tí ó ń wá ọ̀nà láti pa ọ́ nìyí; oluwa mi, ọba, OLUWA ti mú kí ó ṣeéṣe láti gbẹ̀san, lára Saulu ati àwọn ọmọ rẹ̀.”
II. Sam 4:5-8 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Àwọn ọmọ Rimoni, ará Beeroti, Rekabu àti Baanah sì lọ wọ́n sì wá síh ilé Iṣboṣeti ní ọ̀sán gangan, òun sì sinmi lórí ibùsùn kan ní ọjọ́-kanrí. Sì wò ó, bí olùṣọ́ ẹnu-ọ̀nà ilé náà ti ń gbọn àwọn pàǹtí, ó tòògbé ó sì sùn lọ, wọ́n sì wá sí àárín ilé náà, wọ́n sì ṣe bí ẹni pé wọ́n ń fẹ́ mú alikama; (wọ́n sì gún un lábẹ́ inú: Rekabu àti Baanah arákùnrin rẹ̀ sì sálọ). Nígbà tí wọ́n wọ ilé náà lọ, òun sì dùbúlẹ̀ lórí ibùsùn rẹ̀ nínú iyàrá rẹ̀, wọ́n sì pa á, wọ́n sì bẹ́ ẹ lórí, wọ́n gbé orí sálọ, wọ́n sì fi gbogbo òru rìn ni pẹ̀tẹ́lẹ̀ náà. Wọ́n sì gbé orí Iṣboṣeti tọ Dafidi wá ní Hebroni, wọ́n sì wí fún ọba pé, “Wò ó, orí Iṣboṣeti ọmọ Saulu ọ̀tá rẹ, tí ó ti ń wá ẹ̀mí rẹ kiri, OLúWA ti gbẹ̀san fún ọba olúwa mi lónìí lára Saulu àti lára irú-ọmọ rẹ̀.”