II. Sam 4:4
II. Sam 4:4 Bibeli Mimọ (YBCV)
Jonatani ọmọ Saulu si ti bi ọmọkunrin kan ti ẹsẹ rẹ̀ rọ. On si jẹ ọdun marun, nigbati ihìn de niti Saulu ati Jonatani lati Jesreeli wá, olutọ́ rẹ̀ si gbe e, o si sa lọ: o si ṣe, bi o si ti nyara lati sa lọ, on si ṣubu, o si ya arọ. Orukọ rẹ̀ a ma jẹ Mefiboṣeti.
II. Sam 4:4 Yoruba Bible (YCE)
Jonatani ọmọ Saulu ní ọmọkunrin kan, tí ó yarọ, orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Mẹfiboṣẹti. Ọmọ ọdún marun-un ni, nígbà tí wọ́n mú ìròyìn ikú Saulu ati ti Jonatani wá, láti ìlú Jesireeli; ni olùtọ́jú rẹ̀ bá gbé e sá kúrò. Ibi tí ó ti ń fi ìkánjú gbé ọmọ náà sá lọ, ó já ṣubú, ó sì fi bẹ́ẹ̀ yarọ.
II. Sam 4:4 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
(Jonatani ọmọ Saulu sì ti bí ọmọkùnrin kan tí ẹsẹ̀ rẹ̀ rọ, òun sì jẹ́ ọdún márùn-ún, nígbà tí ìròyìn dé ní ti Saulu àti Jonatani láti Jesreeli wá, olùtọ́ rẹ̀ sì gbé e, o sì sálọ, ó sì ṣe, bí ó sì ti ń yára láti sálọ, òun sì ṣubú, ó sì ya arọ. Orúkọ rẹ̀ a máa jẹ́ Mefiboṣeti.)