II. Sam 24:2-17
II. Sam 24:2-17 Bibeli Mimọ (YBCV)
Ọba si wi fun Joabu olori ogun, ti mbẹ lọdọ rẹ̀ pe, Lọ nisisiyi si gbogbo ẹyà Israeli lati Dani titi de Beerṣeba, ki ẹ si kà iye awọn enia, ki emi le mọ̀ iye awọn enia na. Joabu si wi fun ọba pe, Ki Oluwa Ọlọrun rẹ ki o fi kún iye awọn enia na, iyekiye ki o wu ki wọn jẹ, li ọrọrún; oju oluwa mi ọba yio si ri i: ṣugbọn ẽtiṣe ti oluwa mi ọba fi fẹ nkan yi? Ṣugbọn ọ̀rọ ọba si bori ti Joabu, ati ti awọn olori ogun. Joabu ati awọn olori ogun si jade lọ kuro niwaju ọba, lati lọ ika awọn enia Israeli. Nwọn si kọja odo Jordani, nwọn si pagọ ni Aroeri, ni iha apá ọtún ilu ti o wà lagbedemeji afonifoji Gadi, ati si iha Jaseri: Nwọn si wá si Gileadi, ati si ilẹ Tatimhodṣi; nwọn si wá si Dan-jaani ati yikakiri si Sidoni, Nwọn si wá si ilu olodi Tire, ati si gbogbo ilu awọn Hifi, ati ti awọn ara Kenaani: nwọn si jade lọ siha gusu ti Juda, ani si Beerṣeba. Nwọn si la gbogbo ilẹ na ja, nwọn si wá si Jerusalemu li opin oṣù kẹsan ati ogunjọ. Joabu si fi iye ti awọn enia na jasi le ọba lọwọ: o si jẹ oji ọkẹ ọkunrin alagbara ní Israeli, awọn onidà: awọn ọkunrin Juda si jẹ ọkẹ mẹ̃dọgbọn enia. Ẹ̀rí ọkàn si bẹrẹ si da Dafidi lãmú lẹhin igbati o kà awọn enia na tan. Dafidi si wi fun Oluwa pe, Emi ṣẹ̀ gidigidi li eyi ti emi ṣe: ṣugbọn, emi bẹ̀ ọ, Oluwa, fi ẹ̀ṣẹ iranṣẹ rẹ jì i, nitoripe emi huwà aṣiwere gidigidi. Dafidi si dide li owurọ, ọ̀rọ Oluwa si tọ Gadi wolĩ wá, ariran Dafidi, wipe, Lọ, ki o si wi fun Dafidi pe, Bayi li Oluwa wi, emi fi nkan mẹta lọ̀ ọ; yàn ọkan ninu wọn, emi o si ṣe e si ọ. Gadi si tọ Dafidi wá, o si bi i lere pe, Ki iyàn ọdun meje ki o tọ̀ ọ wá ni ilẹ rẹ bi? tabi ki iwọ ki o ma sá li oṣu mẹta niwaju awọn ọta rẹ, nigbati nwọn o ma le ọ? tabi ki arùn iparun ijọ mẹta ki o wá si ilẹ rẹ? rõ nisisiyi, ki o si mọ̀ èsi ti emi o mu pada tọ̀ ẹniti o rán mi. Dafidi si wi fun Gadi pe, Iyọnu nla ba mi: jẹ ki a fi ara wa le Oluwa li ọwọ́; nitoripe ãnu rẹ̀ pọ̀: ki o má si ṣe fi mi le enia li ọwọ́. Oluwa si rán arùn iparun si Israeli lati owurọ̀ titi de akoko ti a da: ẹgbã marundilogoji enia si kú ninu awọn enia na lati Dani titi fi de Beerṣeba. Nigbati angeli na si nawọ́ rẹ̀ si Jerusalemu lati pa a run, Oluwa si kãnu nitori ibi na, o si sọ fun angeli ti npa awọn enia na run pe, O to: da ọwọ́ rẹ duro wayi. Angeli Oluwa na si wà nibi ipaka Arauna ara Jebusi. Dafidi si wi fun Oluwa nigbati o ri angeli ti nkọlu awọn enia pe, Wõ, emi ti ṣẹ̀, emi si ti huwà buburu: ṣugbọn awọn agutan wọnyi, kini nwọn ha ṣe? jẹ ki ọwọ́ rẹ, emi bẹ̀ ọ, ki o wà li ara mi, ati li ara idile baba mi.
II. Sam 24:2-17 Yoruba Bible (YCE)
Dafidi bá pàṣẹ fún Joabu, ati àwọn ọ̀gágun rẹ̀, tí wọ́n wà pẹlu rẹ̀, ó ní, “Ẹ lọ sí gbogbo ẹ̀yà Israẹli, láti Dani títí dé Beeriṣeba, kí ẹ sì ka gbogbo àwọn eniyan tí wọ́n wà níbẹ̀, kí n lè mọ iye wọn.” Ṣugbọn Joabu bi ọba léèrè pé, “Kí OLUWA Ọlọrun rẹ jẹ́ kí àwọn ọmọ Israẹli pọ̀ jù báyìí lọ, ní ìlọ́po ọ̀nà ọgọrun-un (100), nígbà tí oluwa mi ṣì wà láàyè; ṣugbọn, kí ló dé tí kabiyesi fi fẹ́ ka àwọn eniyan wọnyi?” Ṣugbọn àṣẹ tí ọba pa ni ó borí. Ni Joabu ati àwọn ọ̀gágun rẹ̀ bá jáde kúrò níwájú ọba, wọ́n bá lọ ka àwọn ọmọ Israẹli. Wọ́n ré odò Jọdani kọjá, wọ́n pàgọ́ sí ìhà gúsù Aroeri, ìlú tí ó wà ní ààrin àfonífojì, ní agbègbè Gadi. Láti ibẹ̀ ni wọ́n ti lọ sí ìhà àríwá, títí dé Jaseri. Wọ́n lọ sí Gileadi, ati sí Kadeṣi ní ilẹ̀ àwọn ará Hiti. Lẹ́yìn náà, wọ́n lọ sí Dani. Láti Dani, wọ́n lọ sí apá ìwọ̀ oòrùn títí dé Sidoni. Lẹ́yìn náà, wọ́n lọ sí apá gúsù. Wọ́n dé ìlú olódi ti Tire, títí lọ dé gbogbo ìlú àwọn ará Hifi, ati ti àwọn ará Kenaani. Níkẹyìn, wọ́n wá sí Beeriṣeba ní apá ìhà gúsù Juda. Oṣù mẹsan-an ati ogúnjọ́ ni ó gbà wọ́n láti lọ káàkiri gbogbo ilẹ̀ Israẹli, lẹ́yìn náà, wọ́n pada sí Jerusalẹmu. Joabu sọ iye àwọn eniyan tí ó kà fún ọba: Ogoji ọ̀kẹ́ (800,000) ni àwọn ọkunrin tí wọ́n tó ogun jà ní ilẹ̀ Israẹli, àwọn ti ilẹ̀ Juda sì jẹ́ ọ̀kẹ́ mẹẹdọgbọn (500,000). Ṣugbọn lẹ́yìn ìgbà tí Dafidi ka àwọn eniyan náà tán, ẹ̀rí ọkàn rẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí dà á láàmú. Ó bá wí fún OLUWA pé, “Ohun tí mo ṣe yìí burú gan-an, ẹ̀ṣẹ̀ ńlá gbáà ni. Jọ̀wọ́, dáríjì èmi iranṣẹ rẹ, ìwà òmùgọ̀ gbáà ni mo hù.” Nígbà tí Dafidi jí ní òwúrọ̀, OLUWA rán wolii Gadi, aríran rẹ̀ sí i pé, “Lọ sọ fún Dafidi pé mo fi nǹkan mẹta siwaju rẹ̀; kí ó yan ọ̀kan tí ó fẹ́ kí n ṣe sí òun ninu mẹtẹẹta.” Gadi bá lọ sọ ohun tí OLUWA wí fún Dafidi. Ó bèèrè pé, “Èwo ni o fẹ́ yàn ninu mẹtẹẹta yìí, ekinni, kí ìyàn mú ní ilẹ̀ rẹ fún ọdún mẹta; ekeji, kí o máa sá fún àwọn ọ̀tá rẹ fún oṣù mẹta; ẹkẹta, kí àjàkálẹ̀ àrùn jà fún ọjọ́ mẹta ní gbogbo ilẹ̀ rẹ? Rò ó dáradára, kí o sì sọ èyí tí o fẹ́, kí n lọ sọ fún OLUWA.” Dafidi dá Gadi lóhùn pé, “Ìdààmú ńlá ni ó dé bá mi yìí, ṣugbọn ó yá mi lára kí OLUWA jẹ wá níyà ju pé kí ó fi mí lé eniyan lọ́wọ́ lọ; nítorí pé, aláàánú ni OLUWA.” Nítorí náà, OLUWA fi àjàkálẹ̀ àrùn bá Israẹli jà. Ó bẹ̀rẹ̀ láti òwúrọ̀ títí di àkókò tí ó yàn jákèjádò ilẹ̀ Israẹli. Láti Dani títí dé Beeriṣeba, gbogbo àwọn tí ó kú jẹ́ ọ̀kẹ́ mẹta ati ẹgbaarun (70,000). Nígbà tí angẹli OLUWA náà fẹ́ bẹ̀rẹ̀ láti máa pa Jerusalẹmu run, OLUWA yí ọkàn pada nípa jíjẹ tí ó ń jẹ àwọn eniyan náà níyà. Ó bá wí fún angẹli náà pé, “Ó tó gẹ́ẹ́, dáwọ́ dúró.” Níbi ìpakà Arauna ará Jebusi kan ni angẹli náà wà nígbà náà. Nígbà tí Dafidi rí angẹli tí ó ń pa àwọn eniyan náà, ó wí fún OLUWA pé, “Èmi ni mo ṣẹ̀, èmi ni mo ṣe burúkú. Kí ni àwọn eniyan wọnyi ṣe? Èmi ati ìdílé baba mi ni ó yẹ kí ó jẹ níyà.”
II. Sam 24:2-17 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Ọba sì wí fún Joabu Olórí ogun, tí ń bẹ lọ́dọ̀ rẹ̀ pé, “Lọ ní ìsinsin yìí sí gbogbo ẹ̀yà Israẹli láti Dani títí dé Beerṣeba, kí ẹ sì ka iye àwọn ènìyàn, kí èmi lè mọ iye àwọn ènìyàn náà!” Joabu sì wí fún ọba pé, “Kí OLúWA Ọlọ́run rẹ fi kún iye àwọn ènìyàn náà, iyekíye tí ó wù kí wọn jẹ́, ní ọ̀rọ̀ọ̀rún, ojú olúwa mi ọba yóò sì rí i: ṣùgbọ́n èétiṣe tí olúwa mi ọba fi fẹ́ nǹkan yìí?” Ṣùgbọ́n ọ̀rọ̀ ọba borí ti Joabu, àti ti àwọn olórí ogun. Joabu àti àwọn olórí ogun sì jáde lọ kúrò níwájú ọba, láti lọ ka àwọn ènìyàn Israẹli. Wọ́n sì kọjá odò Jordani, wọ́n sì pàgọ́ ní Aroeri, ní ìhà apá ọ̀tún ìlú tí ó wà láàrín Àfonífojì Gadi, àti sí ìhà Jaseri. Wọ́n sì wá sí Gileadi, àti sí ilé Tatimi Hodṣi; wọ́n sì wá sí Dani Jaani àti yíkákiri sí Sidoni, Wọ́n sì wá sí ìlú olódi Tire, àti sí gbogbo ìlú àwọn Hifi, àti ti àwọn ará Kenaani: wọ́n sì jáde lọ síhà gúúsù ti Juda, àní sí Beerṣeba. Wọ́n sì la gbogbo ilẹ̀ náà já, wọ́n sì wá sí Jerusalẹmu ní òpin oṣù kẹsànán àti ogúnjọ́. Joabu sì fi iye tí àwọn ènìyàn náà jásí lé ọba lọ́wọ́: ó sì jẹ́ òjì ọ̀kẹ́ ọkùnrin alágbára ní Israẹli, àwọn onídà: àwọn ọkùnrin Juda sì jẹ́ ọ̀kẹ́ mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n ènìyàn. OLúWA Àyà Dafidi sì gbọgbẹ́ lẹ́yìn ìgbà tí ó ka àwọn ènìyàn náà tán. Dafidi sì wí fún OLúWA pé, “Èmi ṣẹ̀ gidigidi ní èyí tí èmi ṣe: ṣùgbọ́n, èmi bẹ̀ ọ, OLúWA, fi ẹ̀ṣẹ̀ ìránṣẹ́ rẹ jì ní, nítorí pé èmi hùwà aṣiwèrè gidigidi!” Dafidi sì dìde ní òwúrọ̀, ọ̀rọ̀ OLúWA sì tọ Gadi wòlíì wá, aríran Dafidi wí pé: “Lọ kí o sì wí fún Dafidi pé, ‘Báyìí ni OLúWA wí, èmi fi nǹkan mẹ́ta lọ̀ ọ́; yan ọ̀kan nínú wọn, kí èmi ó sì ṣe é sí ọ.’ ” Gadi sì tọ Dafidi wá, ó sì bi í léèrè pé, “Kí ìyàn ọdún méje ó tọ̀ ọ́ wá ní ilẹ̀ rẹ bí? Tàbí kí ìwọ máa sá ní oṣù mẹ́ta níwájú àwọn ọ̀tá rẹ, nígbà tí wọn ó máa lé ọ? Tàbí kí ààrùn ìparun ọjọ́ mẹ́ta ó wá sí ilẹ̀ rẹ? Rò ó nísinsin yìí, kí o sì mọ èsì tí èmi ó mú padà tọ ẹni tí ó rán mi.” Dafidi sì wí fún Gadi pé, “Ìyọnu ńlá bá mi. Jẹ́ kí a fi ara wa lé OLúWA ní ọwọ́; nítorí pé àánú rẹ̀ pọ̀; kí ó má sì ṣe fi mí lé ènìyàn ní ọwọ́.” OLúWA sì rán ààrùn ìparun sí Israẹli láti òwúrọ̀ títí dé àkókò tí a dá: ẹgbàá-márùn-dínlógójì (70,000) ènìyàn sì kú nínú àwọn ènìyàn náà láti Dani títí fi dé Beerṣeba. Nígbà tí angẹli náà sì nawọ́ rẹ̀ sí Jerusalẹmu láti pa á run, OLúWA sì káàánú nítorí ibi náà, ó sì sọ fún angẹli tí ń pa àwọn ènìyàn náà run pé, “Ó tó, dá ọwọ́ rẹ dúró wàyí!” Angẹli OLúWA náà sì wà níbi ìpakà Arauna ará Jebusi. Dafidi sì wí fún OLúWA nígbà tí ó rí angẹli tí ń kọlu àwọn ènìyàn pé, “Wò ó, èmi ti ṣẹ̀, èmi sì ti hùwà búburú ṣùgbọ́n àwọn àgùntàn wọ̀nyí, kín ni wọ́n ha ṣe? Jẹ́ kí ọwọ́ rẹ, èmi bẹ̀ ọ́, kí ó wà lára mi àti ìdílé baba mi.”