II. Sam 23:8-12
II. Sam 23:8-12 Bibeli Mimọ (YBCV)
Wọnyi si li orukọ awọn ọkunrin alagbara ti Dafidi ni: ẹniti o joko ni ibujoko Takmoni ni olori awọn balogun, on si ni Adino Esniti ti o pa ẹgbẹ̀rin enia lẹ̃kan. Ẹniti o tẹ̀le e ni Eleasari ọmọ Dodo ara Ahohi, ọkan ninu awọn alagbara ọkunrin mẹta ti o wà pẹlu Dafidi, nigbati nwọn pe awọn Filistini ni ijà, awọn ti o kó ara wọn jọ si ibẹ lati jà, awọn ọmọkunrin Israeli si ti lọ kuro: On si dide, o si kọlù awọn Filistini titi ọwọ́ fi kún u, ọwọ́ rẹ̀ si lẹ̀ mọ idà: Oluwa si ṣiṣẹ igbala nla li ọjọ na; awọn enia si yipada lẹhin rẹ̀ lati ko ikogun. Ẹniti o tẹ̀le e ni Samma ọmọ Agee ará Harari. Awọn Filistini si ko ara wọn jọ lati piyẹ, oko kan si wà nibẹ ti o kún fun ẹwẹ: awọn enia si sa kuro niwaju awọn Filistini. O si duro lagbedemeji ilẹ na, o si gbà a silẹ, o si pa awọn Filistini: Oluwa si ṣe igbala nla kan.
II. Sam 23:8-12 Yoruba Bible (YCE)
Orúkọ àwọn ọmọ ogun Dafidi tí wọ́n jẹ́ akọni ati akikanju nìwọ̀nyí: Ekinni ni, Joṣebu-Baṣebeti, ará Takimoni, òun ni olórí ninu “Àwọn Akọni Mẹta,” ó fi ọ̀kọ̀ bá ẹgbẹrin (800) eniyan jà, ó sì pa gbogbo wọn ninu ogun kan ṣoṣo. Ẹni tí ó tẹ̀lé e ni, Eleasari, ọmọ Dodo, ti ìdílé Ahohi, ó wà pẹlu Dafidi nígbà tí wọ́n pe àwọn ará Filistia níjà, tí wọ́n kó ara wọn jọ fún ogun, tí àwọn ọmọ ogun Israẹli sì sá sẹ́yìn. Ṣugbọn Eleasari dúró gbọningbọnin, ó sì bá àwọn ará Filistia jà títí tí ọwọ́ rẹ̀ fi wo koko mọ́ idà rẹ̀, tí kò sì le jù ú sílẹ̀ mọ́. OLUWA ja àjàṣẹ́gun ńlá ní ọjọ́ náà. Lẹ́yìn tí ogun náà parí ni àwọn ọmọ ogun Israẹli tó pada sí ibi tí Eleasari wà, tí wọ́n lọ kó àwọn ohun ìjà tí ó wà lára àwọn tí ogun pa. Ẹnìkẹta ninu àwọn akọni náà ni Ṣama, ọmọ Agee, ará Harari. Ní àkókò kan, àwọn ará Filistia kó ara wọn jọ sí Lehi, níbi tí oko ewébẹ̀ kan wà. Àwọn ọmọ ogun Israẹli sá fún àwọn ará Filistia, ṣugbọn Ṣama dúró gbọningbọnin ní ojú ogun. Ó jà kíkankíkan, ó sì pa àwọn ará Filistia. OLUWA sì ja àjàṣẹ́gun ńlá ní ọjọ́ náà.
II. Sam 23:8-12 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Wọ̀nyí sì ni orúkọ àwọn akọni ọkùnrin tí Dafidi ní: Joṣebu-Basṣebeti ará Takemoniti ni olórí àwọn Balógun, òun sì ni akọni rẹ̀ tí ó pa ọ̀ọ́dúnrún ènìyàn lẹ́ẹ̀kan náà. Ẹni tí ó tẹ̀lé e ni Eleasari ọmọ Dodo ará Ahohi, ọ̀kan nínú àwọn alágbára ọkùnrin mẹ́ta ti ó wà pẹ̀lú Dafidi, nígbà tí wọ́n pe àwọn Filistini ní ìjà, àwọn ọkùnrin Israẹli sì ti lọ kúrò. Òun sì dìde, ó sì kọlu àwọn Filistini títí ọwọ́ fi kún un, ọwọ́ rẹ̀ sì lẹ̀ mọ́ idà; OLúWA sì ṣiṣẹ́ ìgbàlà ńlá lọ́jọ́ náà, àwọn ènìyàn sì padà bọ̀ lẹ́yìn rẹ̀ láti kó ìkógun. Ẹni tí ó tẹ̀lé e ni Ṣamma ọmọ Agee ará Harari, àwọn Filistini sì kó ara wọn jọ láti piyẹ́, oko kan sì wà níbẹ̀ tí ó kún fun lẹntili: àwọn ọmọ-ogun Israẹli sì sá kúrò níwájú àwọn Filistini. Ṣamma sì dúró láàrín méjì ilẹ̀ náà, ó sì gbà á sílẹ̀, ó sì pa àwọn Filistini OLúWA sì ṣe ìgbàlà ńlá.