II. Sam 23:13-17
II. Sam 23:13-17 Bibeli Mimọ (YBCV)
Awọn mẹta ninu ọgbọ̀n olori si sọkalẹ, nwọn si tọ Dafidi wá li akoko ikore ninu iho Adullamu: ọ̀wọ́ awọn Filistini si do ni afonifoji Refaimu. Dafidi si wà ninu odi, ibudo awọn Filistini si wà ni Betlehemu nigbana. Dafidi si k'ongbẹ, o wi bayi pe, Tani yio fun mi mu ninu omi kanga ti mbẹ ni Betlehemu, eyi ti o wà ni ihà ẹnu-bodè? Awọn ọkunrin alagbara mẹta si la ogun awọn Filistini lọ, nwọn si fa omi lati inu kanga Betlehemu wá, eyi ti o wà ni iha ẹnu-bode, nwọn si mu tọ Dafidi wá: on kò si fẹ mu ninu rẹ̀, ṣugbọn o tú u silẹ fun Oluwa. On si wipe, Ki a ma ri, Oluwa, ti emi o fi ṣe eyi; ṣe eyi li ẹ̀jẹ awọn ọkunrin ti o lọ ti awọn ti ẹmi wọn li ọwọ́? nitorina on kò si fẹ mu u. Nkan wọnyi li awọn ọkunrin alagbara mẹtẹta yi ṣe.
II. Sam 23:13-17 Yoruba Bible (YCE)
Nígbà tí àkókò ìbẹ̀rẹ̀ ìkórè súnmọ́ tòsí, mẹta ninu àwọn ọgbọ̀n akọni náà lọ sí inú ihò àpáta tí ó wà ní Adulamu, níbi tí Dafidi wà nígbà náà, nígbà tí ọ̀wọ́ àwọn ọmọ ogun Filistini pàgọ́ wọn sí àfonífojì Refaimu. Dafidi wà ní orí òkè kan tí wọ́n mọ odi yípo, ọ̀wọ́ àwọn ọmọ ogun Filistini kan ti gba Bẹtilẹhẹmu, wọ́n sì wà níbẹ̀. Ọkàn ilé fa Dafidi pupọ tóbẹ́ẹ̀ tí ó fi wí pé, “Báwo ni ìbá ti dùn tó, kí ẹnìkan bu omi wá fún mi mu, láti inú kànga tí ó wà ní ẹnubodè Bẹtilẹhẹmu.” Àwọn akọni ọmọ ogun mẹta yìí bá fi tipátipá la àgọ́ àwọn ará Filistia kọjá, wọ́n pọn omi láti inú kànga náà, wọ́n sì gbé e wá fún Dafidi. Ṣugbọn Dafidi kọ̀, kò mu ún. Kàkà bẹ́ẹ̀, ó dà á sílẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ẹbọ ohun mímú fún OLUWA. Ó sì wí pé, “OLUWA, kò yẹ kí n mu omi yìí, nítorí pé, yóo dàbí ẹni pé ẹ̀jẹ̀ àwọn ọkunrin mẹta yìí, tí wọ́n fi orí la ikú lọ ni mò ń mu.” Nítorí náà, ó kọ̀, kò mu ún. Ìṣẹ̀lẹ̀ yìí jẹ́ ara àwọn nǹkan ìgboyà tí àwọn akọni ọmọ ogun mẹta náà ṣe.
II. Sam 23:13-17 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Mẹ́ta nínú àwọn ọgbọ̀n ìjòyè sọ̀kalẹ̀, wọ́n sì tọ Dafidi wá ní àkókò ìkórè nínú ihò Adullamu: ọ̀wọ́ àwọn Filistini sì dó sí Àfonífojì Refaimu. Dafidi sì wà nínú odi, ibùdó àwọn Filistini sì wà ní Bẹtilẹhẹmu nígbà náà. Dafidi sì ń pòǹgbẹ, ó wí báyìí pé, “Ta ni yóò fún mi mu nínú omí kànga tí ń bẹ ní Bẹtilẹhẹmu, èyí tí ó wà ní ìhà ẹnu-bodè.” Àwọn ọkùnrin alágbára mẹ́ta sì la ogún àwọn Filistini lọ, wọ́n sì fa omi láti inú kànga Bẹtilẹhẹmu wá, èyí tí ó wà ní ìhà ẹnu-bodè, wọ́n sì mú tọ Dafidi wá: òun kò sì fẹ́ mu nínú rẹ̀, ṣùgbọ́n ó tú u sílẹ̀ fún OLúWA. Òun sì wí pé, “Kí a má rí, OLúWA, tí èmi ó fi ṣe èyí; ṣé èyí ni ẹ̀jẹ̀ àwọn ọkùnrin tí ó lọ tí àwọn tí ẹ̀mí wọn lọ́wọ́?” Nítorí náà òun kò sì fẹ́ mú un. Nǹkan wọ̀nyí ni àwọn ọkùnrin alágbára mẹ́tẹ̀ẹ̀ta yìí ṣe.