II. Sam 23:1-7
II. Sam 23:1-7 Bibeli Mimọ (YBCV)
WỌNYI si li ọ̀rọ ikẹhin Dafidi. Dafidi ọmọ Jesse, ani ọkunrin ti a ti gbega, ẹni-ami-ororo Ọlọrun Jakobu, ati olorin didùn Israeli wi pe, Ẹmi Oluwa sọ ọ̀rọ nipa mi, ọ̀rọ rẹ̀ si mbẹ li ahọn mi. Ọlọrun Israeli ní, Apata Israeli sọ fun mi pe, Ẹnikan ti nṣe alakoso enia lododo, ti nṣakoso ni ibẹru Ọlọrun. Yio si dabi imọlẹ owurọ nigbati õrun ba là, owurọ ti kò ni ikũku, nigbati koriko tutu ba hù lati ilẹ wa nipa itanṣan lẹhin òjo. Lõtọ ile mi kò ri bẹ niwaju Ọlọrun, ṣugbọn o ti ba mi da majẹmu ainipẹkun, ti a tunṣe ninu ohun gbogbo, ti a si pamọ: nitoripe gbogbo eyi ni igbala mi, ati gbogbo ifẹ mi, ile mi kò le ṣe ki o ma dagbà? Ṣugbọn gbogbo awọn ọmọ Beliali yio dabi ẹgún ẹ̀wọn ti a ṣatì, nitoripe a kò le fi ọwọ́ kó wọn. Ṣugbọn ọkunrin ti yio tọ́ wọn yio fi irin ati ọpa ọ̀kọ sagbàra yi ara rẹ̀ ka: nwọn o si jona lulu nibi kanna.
II. Sam 23:1-7 Yoruba Bible (YCE)
Ọ̀rọ̀ ìkẹyìn Dafidi nìyí; àní, ọ̀rọ̀ ìjìnlẹ̀ Dafidi, ọmọ Jese, tí a gbé ga ní Israẹli, ẹni àmì òróró Ọlọrun Jakọbu, olórin dídùn ní Israẹli: “Ẹ̀mí OLUWA ń gba ẹnu mi sọ̀rọ̀, ọ̀rọ̀ rẹ̀ wà ní ẹnu mi. Ọlọrun Israẹli ti sọ̀rọ̀, Àpáta Israẹli ti wí fún mi pé, ‘Ẹni yòówù tí ó bá fi òtítọ́ jọba, tí ó ṣe àkóso pẹlu ìbẹ̀rù Ọlọrun, a máa tàn sí wọn bí ìmọ́lẹ̀ òwúrọ̀, bí oòrùn tí ó ń ràn ní òwúrọ̀ kutukutu, ní ọjọ́ tí kò sí ìkùukùu; ó dàbí òjò tí ń mú kí koríko hù jáde láti inú ilẹ̀.’ “Bẹ́ẹ̀ ni yóo rí fún arọmọdọmọ mi níwájú Ọlọrun, nítorí pé, ó ti bá mi dá majẹmu ayérayé nípa ohun gbogbo, majẹmu tí kò lè yipada, ati ìlérí tí kò ní yẹ̀. Yóo ṣe ohun tí mo fẹ́ fún mi. Yóo ràn mí lọ́wọ́, yóo fún mi ní ìfẹ́ ọkàn mi. Ṣugbọn àwọn tí wọn kò mọ Ọlọrun dàbí igi ẹ̀gún tí a gbé sọnù, kò sí ẹni tí ó lè fi ọwọ́ lásán gbá wọn mú. Ẹni tí yóo fọwọ́ kan ẹ̀gún gbọdọ̀ lo ohun èlò tí a fi irin ṣe tabi igi ọ̀kọ̀, láti fi wọ́n jóná patapata.”
II. Sam 23:1-7 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Wọ̀nyí sì ni ọ̀rọ̀ ìkẹyìn Dafidi. “Dafidi ọmọ Jese, àní ọkùnrin tí a ti gbéga, ẹni ààmì òróró Ọlọ́run Jakọbu, àti olórin dídùn Israẹli wí pé: “Ẹ̀mí OLúWA sọ ọ̀rọ̀ nípa mi, ọ̀rọ̀ rẹ̀ sì ń bẹ ní ahọ́n mi. Ọlọ́run Israẹli ni, àpáta Israẹli sọ fún mi pé: ‘Ẹnìkan ti ń ṣe alákòóso ènìyàn lódodo, tí ń ṣàkóso ní ìbẹ̀rù Ọlọ́run. Yóò sì dàbí ìmọ́lẹ̀ òwúrọ̀ nígbà tí oòrùn bá là, òwúrọ̀ tí kò ní ìkùùkuu, nígbà tí koríko tútù bá hù wá láti ilẹ̀ lẹ́yìn òjò.’ “Lóòtítọ́ ilé mi kò rí bẹ́ẹ̀ níwájú Ọlọ́run, ṣùgbọ́n ó ti bá mi dá májẹ̀mú àìnípẹ̀kun, tí a túnṣe nínú ohun gbogbo, tí a sì pamọ́; nítorí pé gbogbo èyí ni ìgbàlà, àti gbogbo ìfẹ́ mi, ilé mi kò lè ṣe kí ó má dàgbà. Ṣùgbọ́n gbogbo àwọn ọmọ Beliali yóò dàbí ẹ̀gún ẹ̀wọ̀n tí a ṣá tì, nítorí pé a kò lè fi ọwọ́ kó wọn. Ṣùgbọ́n ọkùnrin tí yóò tọ́ wọn yóò fi irin àti ọ̀pá ọ̀kọ̀ ṣagbára yí ara rẹ̀ ká; wọ́n ó jóná lúúlúú níbìkan náà.”