II. Sam 22:21-31
II. Sam 22:21-31 Bibeli Mimọ (YBCV)
Oluwa san a fun mi gẹgẹ bi ododo mi: o si san a fun mi gẹgẹ bi mimọ́ ọwọ́ mi. Nitoripe emi pa ọ̀na Oluwa mọ, emi kò si fi ìwa buburu yapa kuro lọdọ Ọlọrun mi. Nitoripe gbogbo idajọ rẹ̀ li o wà niwaju mi: ati niti ofin rẹ̀, emi kò si yapa kuro ninu wọn. Emi si wà ninu iwà-titọ si i, emi si pa ara mi mọ kuro ninu ẹ̀ṣẹ mi. Oluwa si san a fun mi gẹgẹ bi ododo mi, gẹgẹ bi ìwa-mimọ́ mi niwaju rẹ̀. Fun alãnu ni iwọ o fi ara rẹ hàn li alãnu, ati fun ẹni-iduro-ṣinṣin li ododo ni iwọ o fi ara rẹ hàn ni iduro-ṣinṣin li ododo. Fun oninu-funfun ni iwọ o fi ara rẹ hàn ni funfun: ati fun ẹni-wiwọ ni iwọ o fi ara rẹ hàn ni wiwọ. Awọn enia ti o wà ninu iyà ni iwọ o si gbàla: ṣugbọn oju rẹ wà lara awọn agberaga, lati rẹ̀ wọn silẹ. Nitori iwọ ni imọlẹ mi, Oluwa: Oluwa yio si sọ okunkun mi di imọlẹ. Nitori nipa rẹ li emi ti là arin ogun kọja: nipa Ọlọrun mi emi ti fò odi kan. Pipe li Ọlọrun li ọ̀na rẹ̀; ọ̀rọ Oluwa li a ti dan wò: on si ni asà fun gbogbo awọn ti o gbẹkẹle e.
II. Sam 22:21-31 Yoruba Bible (YCE)
“OLUWA fún mi ní èrè òdodo mi, ó san ẹ̀san fún mi, nítorí pé mo jẹ́ aláìlẹ́bi. Nítorí pé mo pa àwọn òfin OLUWA mọ́, n kò sì ṣe agídí, kí n yipada kúrò lọ́dọ̀ Ọlọrun mi. Mo ti tẹ̀lé gbogbo òfin rẹ̀, n kò sì ṣe àìgbọràn sí àwọn ìlànà rẹ̀. N kò lẹ́bi níwájú rẹ̀, mo sì ti yẹra fún ẹ̀ṣẹ̀ dídá. Nítorí náà ni OLUWA ṣe san án fún mi, gẹ́gẹ́ bí òdodo mi, ati gẹ́gẹ́ bí mo ti jẹ́ mímọ́ níwájú rẹ̀. “OLUWA, ò máa ṣe olóòótọ́ sí gbogbo àwọn tí wọ́n bá hu ìwà òtítọ́ sí ọ; ò sì máa fi ara rẹ hàn bí aláìlẹ́bi, fún gbogbo àwọn tí kò ní ẹ̀bi. Ọlọrun, mímọ́ ni ọ́, sí gbogbo àwọn tí wọ́n bá mọ́, ṣugbọn o kórìíra gbogbo àwọn eniyan burúkú. Ò máa gba àwọn onírẹ̀lẹ̀, o dójú lé àwọn agbéraga, láti rẹ̀ wọ́n sílẹ̀. “OLUWA, ìwọ ni ìmọ́lẹ̀ mi, ìwọ ni o sọ òkùnkùn mi di ìmọ́lẹ̀. Nípa agbára rẹ, mo lè ṣẹgun àwọn ọ̀tá mi, mo sì lè fo odi kọjá. Ní ti Ọlọrun yìí, pípé ni ọ̀nà rẹ̀, òtítọ́ ni ìlérí OLUWA, ó sì jẹ́ apata fun gbogbo àwọn tí wọ́n bá sápamọ́ sábẹ́ ààbò rẹ̀.
II. Sam 22:21-31 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
“OLúWA sán án fún mi gẹ́gẹ́ bí òdodo mi; ó sì san án fún mi gẹ́gẹ́ bí mímọ́ ọwọ́ mi. Nítorí pé èmi pa ọ̀nà OLúWA mọ́, èmi kò sì fi ìwà búburú yapa kúrò lọ́dọ̀ Ọlọ́run mi. Nítorí pé gbogbo ìdájọ́ rẹ̀ ni ó wà níwájú mi; àti ní ti òfin rẹ̀, èmi kò sì yapa kúrò nínú wọn. Èmi sì wà nínú ìwà títọ́ sí í, èmi sì pa ara mi mọ́ kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀ mi. OLúWA sì san fún mi gẹ́gẹ́ bí òdodo mi, gẹ́gẹ́ bí ìwà mímọ́ mi níwájú rẹ̀. “Fún aláàánú ni ìwọ ó fi ara rẹ̀ hàn ni aláàánú, àti fún ẹni ìdúró ṣinṣin ní òdodo ni ìwọ ó fi ara rẹ hàn ní ìdúró ṣinṣin ní òdodo. Fún onínú funfun ni ìwọ fi ara rẹ hàn ní funfun; àti fún ẹni wíwọ́ ni ìwọ ó fi ara rẹ hàn ní wíwọ́. Àwọn ènìyàn tí ó wà nínú ìyà ni ìwọ ó sì gbàlà; ṣùgbọ́n ojú rẹ wà lára àwọn agbéraga, láti rẹ̀ wọ́n sílẹ̀. Nítorí ìwọ ni ìmọ́lẹ̀ mi, OLúWA; OLúWA yóò sì sọ òkùnkùn mi di ìmọ́lẹ̀. Bẹ́ẹ̀ ni nítorí nípa rẹ̀ ni èmi ti la àárín ogun kọjá; nípa Ọlọ́run mi èmi ti fo odi kan. “Ọlọ́run yìí, pípé ni ọ̀nà rẹ̀; ọ̀rọ̀ OLúWA ni a ti dánwò. Òun sì ni asà fún gbogbo àwọn tí ó gbẹ́kẹ̀lé e.