II. Sam 22:2-4
II. Sam 22:2-4 Bibeli Mimọ (YBCV)
O si wipe, Oluwa li apata mi; ati odi mi, ati olugbala mi; Ọlọrun apata mi; emi o gbẹkẹle e: asà mi, ati iwo igbala mi, ibi isadi giga mi, ati ibi ãbò mi, olugbala mi; iwọ li o ti gbà mi kuro lọwọ agbara. Emi o kepe Oluwa, ti o yẹ lati ma yìn: a o si gbà mi lọwọ awọn ọta mi.
II. Sam 22:2-4 Yoruba Bible (YCE)
“OLUWA ni àpáta mi, ààbò mi, ati olùgbàlà mi; Ọlọrun mi, àpáta mi, ọ̀dọ̀ ẹni tí mo sá pamọ́ sí. Àpáta mi ati ìgbàlà mi, ààbò mi ati ibi ìpamọ́ mi, olùgbàlà mi, ìwọ ni o gbà mí lọ́wọ́ ìwà ipá. Mo ké pe OLUWA, ẹni tí ìyìn yẹ, Ó sì gbà mí lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá mi.
II. Sam 22:2-4 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Ó sì wí pé: “OLúWA ni àpáta mi, àti Olùgbàlà mi; Ọlọ́run mi, àpáta mi, nínú ẹni tí èmi ní ààbò, àti ìwo ìgbàlà mi, ibi ìsádi gíga mi. Àti ibi ìlùmọ̀ mi, Olùgbàlà mi; ìwọ ni ó ti gbà mí kúrò lọ́wọ́ ìwà ipá. “Èmi ké pe OLúWA, tí ó yẹ láti máa yìn, ó sì gbà mí lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá mi.