II. Sam 22:1-51

II. Sam 22:1-51 Bibeli Mimọ (YBCV)

DAFIDI si sọ ọ̀rọ orin yi si Oluwa li ọjọ ti Oluwa gbà a kuro li ọwọ́ gbogbo awọn ọta rẹ̀, ati kuro li ọwọ́ Saulu. O si wipe, Oluwa li apata mi; ati odi mi, ati olugbala mi; Ọlọrun apata mi; emi o gbẹkẹle e: asà mi, ati iwo igbala mi, ibi isadi giga mi, ati ibi ãbò mi, olugbala mi; iwọ li o ti gbà mi kuro lọwọ agbara. Emi o kepe Oluwa, ti o yẹ lati ma yìn: a o si gbà mi lọwọ awọn ọta mi. Nigbati ibilu irora ikú yi mi ka kiri, ti awọn iṣàn enia buburu dẹruba mi; Ọjá ipo-okú yi mi ka kiri; ikẹkun ikú ti ṣaju mi. Ninu ipọnju mi emi ke pe Oluwa, emi si gbe ohùn mi soke si Ọlọrun mi: o si gbohùn mi lati tempili rẹ̀ wá, igbe mi si wọ̀ eti rẹ̀. Ilẹ si mì, o si wariri; ipilẹ ọrun wariri, o si mì, nitoriti o binu. Ẽfin si jade lati iho-imu rẹ̀ wa, ina lati ẹnu rẹ̀ wa si njonirun, ẹyín si nràn nipasẹ rẹ̀. O tẹ ori ọrun ba pẹlu, o si sọkalẹ; okunkun biri-biri si mbẹ li atẹlẹsẹ rẹ̀. O si gun ori kerubu, o si fò: a si ri i lori iyẹ afẹfẹ. O si fi okunkun ṣe ibujoko yi ara rẹ̀ ka, ati agbajọ omi, ani iṣududu awọ sanma. Nipasẹ imọlẹ iwaju rẹ̀ ẹyin-iná ràn. Oluwa san ãra lati ọrun wá, ọga-ogo julọ si fọhùn rẹ̀. O si ta ọfà, o si tú wọn ka; o kọ màna-mána, o si ṣẹ wọn. Iṣàn ibu okun si fi ara hàn, ipilẹ aiye fi ara hàn, nipa ibawi Oluwa, nipa fifún ẽmi ihò imu rẹ̀. O ranṣẹ lati oke wá, o mu mi; o fà mi jade lati inu omi nla wá. O gbà mi lọwọ ọta mi alagbara, lọwọ awọn ti o korira mi: nitoripe nwọn li agbara jù mi lọ. Nwọn ṣaju mi li ọjọ ipọnju mi; ṣugbọn Oluwa li alafẹhinti mi. O si mu mi wá si àye nla: o gbà mi, nitoriti inu rẹ̀ dùn si mi. Oluwa san a fun mi gẹgẹ bi ododo mi: o si san a fun mi gẹgẹ bi mimọ́ ọwọ́ mi. Nitoripe emi pa ọ̀na Oluwa mọ, emi kò si fi ìwa buburu yapa kuro lọdọ Ọlọrun mi. Nitoripe gbogbo idajọ rẹ̀ li o wà niwaju mi: ati niti ofin rẹ̀, emi kò si yapa kuro ninu wọn. Emi si wà ninu iwà-titọ si i, emi si pa ara mi mọ kuro ninu ẹ̀ṣẹ mi. Oluwa si san a fun mi gẹgẹ bi ododo mi, gẹgẹ bi ìwa-mimọ́ mi niwaju rẹ̀. Fun alãnu ni iwọ o fi ara rẹ hàn li alãnu, ati fun ẹni-iduro-ṣinṣin li ododo ni iwọ o fi ara rẹ hàn ni iduro-ṣinṣin li ododo. Fun oninu-funfun ni iwọ o fi ara rẹ hàn ni funfun: ati fun ẹni-wiwọ ni iwọ o fi ara rẹ hàn ni wiwọ. Awọn enia ti o wà ninu iyà ni iwọ o si gbàla: ṣugbọn oju rẹ wà lara awọn agberaga, lati rẹ̀ wọn silẹ. Nitori iwọ ni imọlẹ mi, Oluwa: Oluwa yio si sọ okunkun mi di imọlẹ. Nitori nipa rẹ li emi ti là arin ogun kọja: nipa Ọlọrun mi emi ti fò odi kan. Pipe li Ọlọrun li ọ̀na rẹ̀; ọ̀rọ Oluwa li a ti dan wò: on si ni asà fun gbogbo awọn ti o gbẹkẹle e. Nitori tani iṣe Ọlọrun, bikoṣe Oluwa? tabi tani iṣe apáta, bikoṣe Ọlọrun wa? Ọlọrun alagbara li o fun mi li agbara, o si sọ ọ̀na mi di titọ́. O ṣe ẹsẹ mi bi ẹsẹ agbọnrin: o si mu mi duro ni ibi giga mi. O kọ ọwọ́ mi ni ogun jijà; tobẹ̃ ti apá mi fà ọrun idẹ. Iwọ si ti fun mi li asà igbala rẹ: irẹlẹ rẹ si ti sọ mi di nla. Iwọ si sọ itẹlẹ mi di nla li abẹ mi; tobẹ̃ ti ẹsẹ mi kò fi yọ̀. Emi ti lepa awọn ọta mi, emi si ti run wọn; emi kò pẹhinda titi emi fi run wọn. Emi ti pa wọn run, emi si ti fọ́ wọn, nwọn kò si le dide mọ: nwọn ṣubu labẹ ẹsẹ mi. Iwọ si ti fi agbara di mi li amure fun ijà: awọn ti o ti dide si mi ni iwọ si ti tẹ̀ li ori ba fun mi. Iwọ si mu awọn ọta mi pẹhindà fun mi, emi si pa awọn ti o korira mi run. Nwọn wò, ṣugbọn kò si ẹnikan lati gbà wọn; nwọn wò Oluwa, ṣugbọn kò da wọn lohùn. Nigbana ni emi si gun wọn wẹwẹ bi erupẹ ilẹ, emi si tẹ̀ wọn mọlẹ bi ẹrẹ̀ ita, emi si tẹ wọn gbọrọ. Iwọ si gbà mi kuro lọwọ ijà awọn enia mi, iwọ pa mi mọ ki emi ki o le ṣe olori awọn ajeji orilẹ-ède: awọn enia ti emi kò ti mọ̀ yio ma sìn mi. Awọn alejo yio fi ẹ̀tan tẹriba fun mi: bi nwọn ba ti gbọ́ iró mi, nwọn o si gbọ́ ti emi. Ìpaiyà yio dé bá awọn alejo, nwọn o si ma bẹ̀ru nibi kọ́lọfin wọn. Oluwa mbẹ; olubukun si ni apata mi: gbigbega si li Ọlọrun apata igbala mi. Ọlọrun li ẹniti ngbẹsan mi, ati ẹniti nrẹ̀ awọn enia silẹ labẹ mi. On ni o gbà mi kuro lọwọ awọn ọta mi: iwọ si gbe mi soke ju awọn ti o dide si mi lọ: iwọ si gbà mi kuro lọwọ ọkunrin ìwa agbara. Nitorina emi o fi ọpẹ fun ọ. Oluwa, larin awọn ajeji orilẹ-ède: emi o si kọrin si orukọ rẹ. On ni ile-iṣọ igbala fun ọba rẹ̀: o si fi ãnu hàn fun ẹni-ami-ororo rẹ̀; fun Dafidi, ati fun iru-ọmọ rẹ̀ titi lailai.

II. Sam 22:1-51 Yoruba Bible (YCE)

Nígbà tí OLUWA gba Dafidi lọ́wọ́ gbogbo àwọn ọ̀tá rẹ̀ ati lọ́wọ́ Saulu, Dafidi kọ orin yìí sí OLUWA pé: “OLUWA ni àpáta mi, ààbò mi, ati olùgbàlà mi; Ọlọrun mi, àpáta mi, ọ̀dọ̀ ẹni tí mo sá pamọ́ sí. Àpáta mi ati ìgbàlà mi, ààbò mi ati ibi ìpamọ́ mi, olùgbàlà mi, ìwọ ni o gbà mí lọ́wọ́ ìwà ipá. Mo ké pe OLUWA, ẹni tí ìyìn yẹ, Ó sì gbà mí lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá mi. “Ikú yí mi káàkiri, bí ìgbì omi; ìparun sì bò mí mọ́lẹ̀ bíi ríru omi; isà òkú ya ẹnu sílẹ̀ dè mí, ewu ikú sì dojú kọ mí. Ninu ìpọ́njú mi, mo ké pe OLUWA mo ké pe Ọlọrun mi, ó gbọ́ ohùn mi láti inú tẹmpili rẹ̀; ó sì tẹ́tí sí igbe mi. “Ayé mì, ó sì wárìrì; ìpìlẹ̀ àwọn ọ̀run sì wárìrì, ó mì tìtì, nítorí ibinu Ọlọrun. Èéfín jáde láti ihò imú rẹ̀, iná ajónirun sì jáde láti ẹnu rẹ̀; ẹ̀yinná tí ó pọ́n rẹ̀rẹ̀ ń ti ọ̀dọ̀ rẹ̀ jáde. Ó tẹ àwọn ọ̀run ba, ó sì sọ̀kalẹ̀; ìkùukùu tí ó ṣókùnkùn sì wà ní abẹ́ ẹsẹ̀ rẹ̀. Ó gun orí Kerubu, ó fò, afẹ́fẹ́ ni ó fi ṣe ìyẹ́ tí ó fi ń fò. Ó fi òkùnkùn bo ara, ìkùukùu tí ó ṣókùnkùn, tí ó sì kún fún omi ni ó fi ṣe ìbòrí. Ẹ̀yinná tí ń jó ń jáde, láti inú ìmọ́lẹ̀ tí ó wà níwájú rẹ̀. “OLUWA sán ààrá láti ọ̀run wá, ayé sì gbọ́ ohùn ọ̀gá ògo. Ó ta ọpọlọpọ ọfà, ó sì tú wọn ká. Ó tan mànàmáná, wọ́n sì ń sá. Ìsàlẹ̀ òkun di gbangba, ìpìlẹ̀ ayé sì ṣí sílẹ̀, nígbà tí OLUWA bá wọn wí, tí ó sì fi ibinu jágbe mọ́ wọn. “OLUWA nawọ́ sílẹ̀ láti òkè wá, ó dì mí mú, ó fà mí jáde kúrò ninu omi jíjìn. Ó gbà mí lọ́wọ́ ọ̀tá mi, tí ó lágbára; ati lọ́wọ́ gbogbo àwọn tí wọ́n kórìíra mi; nítorí pé wọ́n lágbára jù mí lọ. Nígbà tí mo wà ninu ìpọ́njú; wọ́n gbógun tì mí, ṣugbọn OLUWA dáàbò bò mí. Ó ràn mí lọ́wọ́, ó kó mi yọ ninu ewu, ó sì gbà mí là, nítorí pé inú rẹ̀ dùn sí mi. “OLUWA fún mi ní èrè òdodo mi, ó san ẹ̀san fún mi, nítorí pé mo jẹ́ aláìlẹ́bi. Nítorí pé mo pa àwọn òfin OLUWA mọ́, n kò sì ṣe agídí, kí n yipada kúrò lọ́dọ̀ Ọlọrun mi. Mo ti tẹ̀lé gbogbo òfin rẹ̀, n kò sì ṣe àìgbọràn sí àwọn ìlànà rẹ̀. N kò lẹ́bi níwájú rẹ̀, mo sì ti yẹra fún ẹ̀ṣẹ̀ dídá. Nítorí náà ni OLUWA ṣe san án fún mi, gẹ́gẹ́ bí òdodo mi, ati gẹ́gẹ́ bí mo ti jẹ́ mímọ́ níwájú rẹ̀. “OLUWA, ò máa ṣe olóòótọ́ sí gbogbo àwọn tí wọ́n bá hu ìwà òtítọ́ sí ọ; ò sì máa fi ara rẹ hàn bí aláìlẹ́bi, fún gbogbo àwọn tí kò ní ẹ̀bi. Ọlọrun, mímọ́ ni ọ́, sí gbogbo àwọn tí wọ́n bá mọ́, ṣugbọn o kórìíra gbogbo àwọn eniyan burúkú. Ò máa gba àwọn onírẹ̀lẹ̀, o dójú lé àwọn agbéraga, láti rẹ̀ wọ́n sílẹ̀. “OLUWA, ìwọ ni ìmọ́lẹ̀ mi, ìwọ ni o sọ òkùnkùn mi di ìmọ́lẹ̀. Nípa agbára rẹ, mo lè ṣẹgun àwọn ọ̀tá mi, mo sì lè fo odi kọjá. Ní ti Ọlọrun yìí, pípé ni ọ̀nà rẹ̀, òtítọ́ ni ìlérí OLUWA, ó sì jẹ́ apata fun gbogbo àwọn tí wọ́n bá sápamọ́ sábẹ́ ààbò rẹ̀. Ta ni Ọlọrun bí kò ṣe OLUWA? Ta sì ni àpáta ààbò bí kò ṣe Ọlọrun wa? Ọlọrun yìí ni ààbò mi tí ó lágbára, ó mú gbogbo ewu kúrò ní ọ̀nà mi. Ó fún ẹsẹ̀ mi lókun láti sáré bí àgbọ̀nrín, ó sì mú kí n wà ní àìléwu lórí àwọn òkè. Ó kọ́ mi ní ogun jíjà, tóbẹ́ẹ̀ tí mo lè lo ọrun idẹ. “O fún mi ní àpáta ìgbàlà rẹ, ìrànlọ́wọ́ rẹ ni ó sọ mí di ẹni ńlá. Ìwọ ni o kò jẹ́ kí ọwọ́ ọ̀tá tẹ̀ mí, bẹ́ẹ̀ ni o kò jẹ́ kí ẹsẹ̀ mí kí ó yẹ̀. Mo lépa àwọn ọ̀tá mi, mo sì ṣẹgun wọn n kò pada lẹ́yìn wọn títí tí mo fi pa wọ́n run. Mo pa wọ́n run, mo bì wọ́n lulẹ̀; wọn kò sì lè dìde mọ́; wọ́n ṣubú lábẹ́ ẹsẹ̀ mi. Ìwọ ni o fún mi lágbára láti jagun, o jẹ́ kí àwọn ọ̀tá mi rì lábẹ́ mi. O mú kí àwọn ọ̀tá mi sá fún mi, mo sì pa àwọn tí wọ́n kórìíra mi run. Wọ́n wá ìrànlọ́wọ́ káàkiri, ṣugbọn kò sí ẹni tí ó lè gbà wọ́n; wọ́n pe OLUWA, ṣugbọn kò dá wọn lóhùn. Mo fọ́ wọn túútúú, wọ́n sì dàbí erùpẹ̀ ilẹ̀; mo tẹ̀ wọ́n mọ́lẹ̀, wọ́n sì dàbí ẹrọ̀fọ̀ lójú títì. “Ìwọ ni o gbà mí lọ́wọ́ ìjà àwọn eniyan mi, o sì mú kí ìjọba mi dúró lórí àwọn orílẹ̀ èdè; àwọn eniyan tí n kò mọ̀ rí di ẹni tí ó ń sìn mí. Àwọn àjèjì ń wólẹ̀ níwájú mi, ẹsẹ̀kẹsẹ̀ tí wọ́n bá ti gbúròó mi, ni wọ́n ń mú àṣẹ mi ṣẹ. Ẹ̀rù ba àwọn àjèjì, wọ́n gbọ̀n jìnnìjìnnì jáde ní ibi ààbò wọn. “OLUWA wà láàyè, ìyìn ni fún àpáta ààbò mi. Ẹ gbé Ọlọrun mi ga, ẹni tíí ṣe àpáta ìgbàlà mi. Ọlọrun ti jẹ́ kí n gbẹ̀san lára àwọn ọ̀tá mi, ó ti tẹ orí àwọn orílẹ̀-èdè ba lábẹ́ mi; ó sì fà mí yọ lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá mi. “OLUWA, ìwọ ni o gbé mi ga ju àwọn ọ̀tá mi lọ, o sì dáàbò bò mí, lọ́wọ́ àwọn oníwà ipá. Nítorí náà, n óo máa yìn ọ́ láàrin àwọn orílẹ̀-èdè, n óo máa kọ orin ìyìn sí orúkọ rẹ. Ọlọrun fi ìṣẹ́gun ńlá fún ọba rẹ̀, ó sì fi ìfẹ́ tí kì í yẹ̀ han ẹni tí ó fi àmì òróró yàn, àní Dafidi ati arọmọdọmọ rẹ̀ laelae!”

II. Sam 22:1-51 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)

Dafidi sì kọ ọ̀rọ̀ orin yìí sí OLúWA ní ọjọ́ tí OLúWA gbà á kúrò lọ́wọ́ gbogbo àwọn ọ̀tá rẹ̀, àti kúrò lọ́wọ́ Saulu. Ó sì wí pé: “OLúWA ni àpáta mi, àti Olùgbàlà mi; Ọlọ́run mi, àpáta mi, nínú ẹni tí èmi ní ààbò, àti ìwo ìgbàlà mi, ibi ìsádi gíga mi. Àti ibi ìlùmọ̀ mi, Olùgbàlà mi; ìwọ ni ó ti gbà mí kúrò lọ́wọ́ ìwà ipá. “Èmi ké pe OLúWA, tí ó yẹ láti máa yìn, ó sì gbà mí lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá mi. Nígbà tí ìbìlù ìrora ikú yí mi káàkiri; tí àwọn ìṣàn ènìyàn búburú dẹ́rùbà mí. Ọ̀já isà òkú yí mi káàkiri; ìkẹ́kùn ikú dojúkọ mí. “Nínú ìpọ́njú mi, èmi ké pé OLúWA, èmi sì gbé ohùn mi sókè sí Ọlọ́run mi. Ó sí gbóhùn mi láti tẹmpili rẹ̀ igbe mí wọ etí rẹ̀. Ilẹ̀ sì mì, ó sì wárìrì; ìpìlẹ̀ ọ̀run wárìrì, ó sì mì, nítorí tí ó bínú. Èéfín ti ihò imú rẹ̀ jáde wá; Iná ajónirun ti ẹnu rẹ̀ jáde wá, ẹ̀yin iná bú jáde láti inú rẹ̀. Ó tẹ orí ọ̀run ba pẹ̀lú, ó sì sọ̀kalẹ̀; òkùnkùn biribiri sì ń bẹ ní àtẹ́lẹsẹ̀ rẹ̀. Ó sì gun orí kérúbù, ó sì fò: a sì rí i lórí ìyẹ́ afẹ́fẹ́. Ó sì fi òkùnkùn ṣe ibùjókòó yí ara rẹ̀, àti àgbájọ omi, àní ìṣúdudu ìkùùkuu àwọ̀ sánmọ̀. Nípasẹ̀ ìmọ́lẹ̀ iwájú rẹ̀ ẹ̀yín iná ràn. OLúWA sán àrá láti ọ̀run wá, Ọ̀gá-ògo jùlọ sì fọhùn rẹ̀. Ó sì ta ọfà, ó sì tú wọn ká; ó kọ mànàmànà, ó sì ṣẹ́ wọn. Ìṣàn ibú Òkun sì fi ara hàn, ìpìlẹ̀ ayé fi ara hàn, nípa ìbáwí OLúWA, nípa fífún èémí ihò imú rẹ̀. “Ó ránṣẹ́ láti òkè wá, ó mú mi; ó fà mí jáde láti inú omi ńlá wá. Ó gbà mí lọ́wọ́ ọ̀tá mi alágbára, lọ́wọ́ àwọn tí ó kórìíra mi: nítorí pé wọ́n lágbára jù mí lọ. Wọ́n wá láti borí mi lọ́jọ́ ìpọ́njú mi: ṣùgbọ́n OLúWA ni aláfẹ̀yìntì mi. Ó sì mú mi wá sí ààyè ńlá: ó gbà mi, nítorí tí inú rẹ̀ dún sí mi. “OLúWA sán án fún mi gẹ́gẹ́ bí òdodo mi; ó sì san án fún mi gẹ́gẹ́ bí mímọ́ ọwọ́ mi. Nítorí pé èmi pa ọ̀nà OLúWA mọ́, èmi kò sì fi ìwà búburú yapa kúrò lọ́dọ̀ Ọlọ́run mi. Nítorí pé gbogbo ìdájọ́ rẹ̀ ni ó wà níwájú mi; àti ní ti òfin rẹ̀, èmi kò sì yapa kúrò nínú wọn. Èmi sì wà nínú ìwà títọ́ sí í, èmi sì pa ara mi mọ́ kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀ mi. OLúWA sì san fún mi gẹ́gẹ́ bí òdodo mi, gẹ́gẹ́ bí ìwà mímọ́ mi níwájú rẹ̀. “Fún aláàánú ni ìwọ ó fi ara rẹ̀ hàn ni aláàánú, àti fún ẹni ìdúró ṣinṣin ní òdodo ni ìwọ ó fi ara rẹ hàn ní ìdúró ṣinṣin ní òdodo. Fún onínú funfun ni ìwọ fi ara rẹ hàn ní funfun; àti fún ẹni wíwọ́ ni ìwọ ó fi ara rẹ hàn ní wíwọ́. Àwọn ènìyàn tí ó wà nínú ìyà ni ìwọ ó sì gbàlà; ṣùgbọ́n ojú rẹ wà lára àwọn agbéraga, láti rẹ̀ wọ́n sílẹ̀. Nítorí ìwọ ni ìmọ́lẹ̀ mi, OLúWA; OLúWA yóò sì sọ òkùnkùn mi di ìmọ́lẹ̀. Bẹ́ẹ̀ ni nítorí nípa rẹ̀ ni èmi ti la àárín ogun kọjá; nípa Ọlọ́run mi èmi ti fo odi kan. “Ọlọ́run yìí, pípé ni ọ̀nà rẹ̀; ọ̀rọ̀ OLúWA ni a ti dánwò. Òun sì ni asà fún gbogbo àwọn tí ó gbẹ́kẹ̀lé e. Nítorí ta ni Ọlọ́run, bí kò ṣe OLúWA? Ta ni àpáta, bí kò ṣe Ọlọ́run wa. Ọlọ́run alágbára ni ó fún mi ní agbára, ó sì sọ ọ̀nà mi di títọ́. Ó ṣe ẹsẹ̀ mi bí ẹsẹ̀ abo àgbọ̀nrín; ó sì mú mi dúró ní ibi gíga mi. Ó kọ́ ọwọ́ mi ní ogun jíjà; tó bẹ́ẹ̀ tí apá mi fa ọrun idẹ. Ìwọ sì ti fún mi ní asà ìgbàlà rẹ̀, ìrẹ̀lẹ̀ rẹ̀ sì ti sọ mí di ńlá. Ìwọ sì sọ ìtẹ̀lẹ̀ di ńlá ní abẹ́ mi; tó bẹ́ẹ̀ tí ẹsẹ̀ mi kò fi yọ̀. “Èmi ti lépa àwọn ọ̀tá mi, èmi sì ti run wọ́n, èmi kò pẹ̀yìndà títí èmi fi run wọ́n. Èmi ti pa wọ́n run, èmi sì ti fọ́ wọn, wọn kò sì le dìde mọ́: wọ́n ṣubú lábẹ́ mi. Ìwọ sì ti fi agbára dì mí ní àmùrè fún ìjà; àwọn tí ó ti dìde sí mi ni ìwọ sì ti tẹ̀ lórí ba fún mi. Ìwọ sì mú àwọn ọ̀tá mi pẹ̀yìndà fún mi, èmi ó sì pa àwọn tí ó kórìíra mi run. Wọ́n wò, ṣùgbọ́n kò sí ẹnìkan láti gbà wọ́n; wọ́n wo OLúWA, ṣùgbọ́n kò dá àwọn lóhùn. Nígbà náà ni èmi sì gún wọn wẹ́wẹ́ bí erùpẹ̀ ilẹ̀, èmi sì tẹ̀ wọ́n mọ́lẹ̀ bí ẹrẹ̀ ìta, èmi sì tẹ́ wọn gbọrọ. “Ìwọ sì gbà mí kúrò lọ́wọ́ ìjà àwọn ènìyàn mi, ìwọ pa mi mọ́ ki èmi lè ṣe olórí àwọn àjèjì orílẹ̀-èdè. Àwọn ènìyàn tí èmi kò tí mọ̀ yóò máa sìn mí. Àwọn àjèjì wá láti tẹríba fún mi; bí wọ́n bá ti gbúròó mi, wọ́n á sì gbọ́ tèmi. Àyà yóò pá àwọn àlejò, wọ́n ó sì fi ìbẹ̀rù sá kúrò níbi kọ́lọ́fín wọn. “OLúWA ń bẹ́; olùbùkún sì ni àpáta mi! Gbígbéga sì ni Ọlọ́run àpáta ìgbàlà mi. Ọlọ́run ni ẹni tí ń gbẹ̀san mi, àti ẹni tí ń rẹ àwọn ènìyàn sílẹ̀ lábẹ́ mi. Àti ẹni tí ó gbà mí kúrò lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá mi. Ìwọ sì gbé mi sókè ju àwọn tí ó kórìíra mi lọ; ìwọ sì gbà mí kúrò lọ́wọ́ àwọn ọkùnrin oníwà ipá. Nítorí náà èmi ó fi ọpẹ́ fún ọ, OLúWA, láàrín àwọn àjèjì orílẹ̀-èdè: èmi ó sì kọrin sí orúkọ rẹ. “Òun ni ilé ìṣọ́ ìgbàlà fún ọba rẹ̀; ó sì fi àánú hàn fún ẹni ààmì òróró rẹ̀, fún Dafidi, àti fún irú-ọmọ rẹ̀ títí láéláé.”