II. Sam 21:5-7
II. Sam 21:5-7 Bibeli Mimọ (YBCV)
Nwọn si wi fun ọba pe, ọkunrin ti o run wa, ti o si rò lati pa wa rẹ́ ki a má kù nibikibi ninu gbogbo agbegbe Israeli. Mu ọkunrin meje ninu awọn ọmọ rẹ̀ fun wa, awa o si so wọn rọ̀ fun Oluwa ni Gibea ti Saulu ẹniti Oluwa ti yàn. Ọba si wipe, Emi o fi wọn fun nyin. Ṣugbọn Ọba dá Mefiboṣeti si, ọmọ Jonatani, ọmọ Saulu, nitori ibura Oluwa ti o wà larin wọn, lãrin Dafidi ati Jonatani ọmọ Saulu.
II. Sam 21:5-7 Yoruba Bible (YCE)
Wọ́n dáhùn pé, “Saulu fẹ́ pa wá run, kò sì fẹ́ kí ẹnikẹ́ni ninu wa wà láàyè níbikíbi, ní ilẹ̀ Israẹli. Nítorí náà, fún wa ní meje ninu àwọn ọmọ rẹ̀ ọkunrin, kí á lè so wọ́n kọ́ níwájú OLUWA ní Gibea, ní orí òkè OLUWA.” Dafidi dáhùn pé, “N óo kó wọn lé yín lọ́wọ́.” Ṣugbọn nítorí majẹmu tí ó wà láàrin Dafidi ati Jonatani, Dafidi kò fi ọwọ́ kan Mẹfiboṣẹti, ọmọ Jonatani, ọmọ Saulu.
II. Sam 21:5-7 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Wọ́n sì wí fún ọba pé, “Ọkùnrin tí ó run wá, tí ó sì rò láti pa wá rẹ́ ki a má kù níbikíbi nínú gbogbo agbègbè Israẹli. Mú ọkùnrin méje nínú àwọn ọmọ rẹ̀ fún wá, àwa ó sì so wọ́n rọ̀ fún OLúWA ní Gibeah ti Saulu ẹni tí OLúWA ti yàn.” Ọba sì wí pé, “Èmi ó fi wọ́n fún yín.” Ṣùgbọ́n ọba dá Mefiboṣeti sí, ọmọ Jonatani, ọmọ Saulu, nítorí ìbúra OLúWA tí ó wà láàrín Dafidi àti Jonatani ọmọ Saulu.