II. Sam 19:9-23
II. Sam 19:9-23 Bibeli Mimọ (YBCV)
Gbogbo awọn enia na si mba ara wọn jà ninu gbogbo ẹya Israeli, pe, Ọba ti gbà wa là lọwọ awọn ọta wa, o si ti gbà wa kuro lọwọ awọn Filistini; on si wa sa kuro ni ilu nitori Absalomu. Absalomu, ti awa fi jọba lori wa si kú li ogun: njẹ ẽṣe ti ẹnyin fi dakẹ ti ẹnyin kò si sọ̀rọ kan lati mu ọba pada wá? Dafidi ọba si ranṣẹ si Sadoku, ati si Abiatari awọn alufa pe, Sọ fun awọn agbà Juda, pe, Ẽṣe ti ẹnyin fi kẹhin lati mu ọba pada wá si ile rẹ̀? ọ̀rọ gbogbo Israeli si ti de ọdọ ọba ani ni ile rẹ̀. Ẹnyin li ará mi, ẹnyin li egungun mi, ati ẹran ara mi: ẹ̃si ti ṣe ti ẹnyin fi kẹhìn lati mu ọba pada wá? Ki ẹnyin ki o si wi fun Amasa pe, Egungun ati ẹran ara mi ki iwọ iṣe bi? ki Ọlọrun ki o ṣe bẹ̃ si mi ati ju bẹ̃ lọ pẹlu, bi iwọ kò ba ṣe olori ogun niwaju mi titi, ni ipò Joabu. On si yi ọkàn gbogbo awọn ọkunrin Juda, ani bi ọkàn enia kan; nwọn si ranṣẹ si ọba, pe, Iwọ pada ati gbogbo awọn iranṣẹ rẹ. Ọba si pada, o si wá si odo Jordani. Juda si wá si Gilgali, lati lọ ipade ọba, ati lati mu ọba kọja odo Jordani. Ṣimei ọmọ Gera, ara Benjamini ti Bahurimu, o yara o si ba awọn ọkunrin Juda sọkalẹ lati pade Dafidi ọba. Ẹgbẹrun ọmọkunrin si wà lọdọ rẹ̀ ninu awọn ọmọkunrin Benjamini, Siba iranṣẹ ile Saulu, ati awọn ọmọkunrin rẹ̀ mẹ̃dogun ati ogún iranṣẹ si pẹlu rẹ̀; nwọn si goke odo Jordani ṣaju ọba. Ọkọ̀ èro kan ti rekọja lati kó awọn enia ile ọba si oke, ati lati ṣe eyiti o tọ li oju rẹ̀. Ṣimei ọmọ Gera wolẹ, o si dojubolẹ niwaju ọba, bi o ti goke odo Jordani. O si wi fun ọba pe, Ki oluwa mi ki o máṣe ka ẹ̀ṣẹ si mi li ọrùn, má si ṣe ranti afojudi ti iranṣẹ rẹ ṣe li ọjọ ti oluwa mi ọba jade ni Jerusalemu, ki ọba ki o má si fi si inu. Nitoripe iranṣẹ rẹ mọ̀ pe on ti ṣẹ̀; si wõ, ni gbogbo idile Josefu emi li o kọ́ wá loni lati sọkalẹ wá pade oluwa mi ọba. Ṣugbọn Abiṣai ọmọ Seruia dahùn o si wipe, Kò ha tọ́ ki a pa Ṣimei nitori eyi? nitoripe on ti bú ẹni-àmi-ororo Oluwa. Dafidi si wipe, Ki li o wà lãrin emi ati ẹnyin, ẹnyin ọmọ Seruia, ti ẹ fi di ọta si mi loni? a ha le pa enia kan loni ni Israeli? o le ṣe pe emi kò mọ̀ pe, loni emi li ọba Israeli? Ọba si wi fun Ṣimei pe, Iwọ kì yio kú. Ọba si bura fun u.
II. Sam 19:9-23 Yoruba Bible (YCE)
Ìjà bẹ́ sílẹ̀ láàrin àwọn ẹ̀yà Israẹli káàkiri. Wọ́n ń wí láàrin ara wọn pé, “Ọba Dafidi ni ó gbà wá lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá wa, òun ni ó gbà wá lọ́wọ́ àwọn ará Filistia, ṣugbọn nisinsinyii, ó ti sá kúrò nílùú fún Absalomu. A fi àmì òróró yan Absalomu ní ọba, ṣugbọn wọ́n ti pa á lójú ogun, nítorí náà, ó yẹ kí ẹnìkan gbìyànjú láti mú Dafidi ọba pada.” Ìròyìn ohun tí àwọn eniyan Israẹli ń wí kan Dafidi ọba lára. Dafidi ọba ranṣẹ sí àwọn alufaa mejeeji: Sadoku, ati Abiatari, láti bèèrè lọ́wọ́ àwọn àgbààgbà Juda pé, “Kí ló dé tí ẹ fi níláti gbẹ́yìn ninu ètò àtidá ọba pada sí ààfin rẹ̀? Ṣebí ìbátan ọba ni yín, ẹ̀jẹ̀ kan náà sì ni yín? Kí ló dé tí ẹ fi níláti gbẹ́yìn ninu ètò àtidá ọba pada sí ààfin rẹ̀.” Dafidi ní kí wọ́n sọ fún Amasa pé, ẹbí òun ni Amasa; ati pé, láti ìgbà náà lọ, Amasa ni òun yóo fi ṣe balogun òun, dípò Joabu. Ó búra pé kí Ọlọrun pa òun bí òun kò bá ṣe bẹ́ẹ̀. Ọ̀rọ̀ tí Dafidi sọ yìí, mú kí àwọn eniyan Juda fara mọ́ ọn, wọ́n sì ranṣẹ sí i pé kí ó pada pẹlu gbogbo àwọn iranṣẹ rẹ̀. Nígbà tí ọba ń pada bọ̀, àwọn eniyan Juda wá sí Giligali láti pàdé rẹ̀ ati láti mú un kọjá odò Jọdani. Ní àkókò yìí kan náà, Ṣimei, ọmọ Gera, ará Bẹnjamini, láti ìlú Bahurimu, sáré lọ sí odò Jọdani láti pàdé Dafidi ọba pẹlu àwọn eniyan Juda. Ẹgbẹrun (1,000) eniyan, láti inú ẹ̀yà Bẹnjamini, ni ó kó lọ́wọ́. Siba, iranṣẹ ìdílé Saulu, náà wá pẹlu àwọn ọmọ rẹ̀ mẹẹdogun, ati ogún iranṣẹ. Wọ́n dé sí etí odò kí ọba tó dé ibẹ̀. Wọ́n rékọjá odò sí òdìkejì, láti dara pọ̀ mọ́ àwọn tí wọn yóo sin ìdílé ọba kọjá odò, ati láti ṣe ohunkohun tí ọba bá fẹ́. Bí ọba ti múra láti kọjá odò náà, Ṣimei wólẹ̀ níwájú rẹ̀. Ó ní, “Kabiyesi, jọ̀wọ́ má dá mi lẹ́bi, má sì ranti àṣìṣe tí mo ṣe ní ọjọ́ tí o kúrò ní Jerusalẹmu, jọ̀wọ́ gbàgbé rẹ̀. Mo mọ̀ pé mo ti ṣẹ̀; Ìdí nìyí, tí ó fi jẹ́ pé èmi ni ẹni àkọ́kọ́ tí ó kọ́ wá pàdé rẹ lónìí, ninu gbogbo ìdílé Josẹfu.” Abiṣai ọmọ Seruaya dáhùn pé, “Pípa ni ó yẹ kí á pa Ṣimei nítorí pé ó ṣépè lé ẹni tí OLUWA fi òróró yàn ní ọba.” Ṣugbọn Dafidi dá Abiṣai ati Joabu ẹ̀gbọ́n rẹ̀ lóhùn pé, “Kí ló kàn yín ninu ọ̀rọ̀ yìí? Kí ni n óo ti ṣe yín sí, ẹ̀yin ọmọ Seruaya, tí ẹ̀ ń ṣe bí ọ̀tá sí mi? Èmi ni ọba Israẹli lónìí, ẹnìkan kò sì ní pa ẹnikẹ́ni ninu àwọn ọmọ Israẹli.” Ó bá dá Ṣimei lóhùn, ó ní, “Mo búra fún ọ pé ẹnikẹ́ni kò ní pa ọ́.”
II. Sam 19:9-23 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Gbogbo àwọn ènìyàn náà sì ń bà ara wọn jà nínú gbogbo ẹ̀yà Israẹli, pé, “ọba ti gbà wá là lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá wa, ó sì ti gbà wá kúrò lọ́wọ́ àwọn Filistini; òun sì wá sá kúrò ní ìlú nítorí Absalomu. Absalomu, tí àwa fi jẹ ọba lórí wa sì kú ní ogun: ǹjẹ́ èéṣe tí ẹ̀yin fi dákẹ́ tí ẹ̀yin kò sì sọ̀rọ̀ kan láti mú ọba padà wá?” Dafidi ọba sì ránṣẹ́ sí Sadoku, àti sí Abiatari àwọn àlùfáà pé, “Sọ fún àwọn àgbàgbà Juda, pé, ‘Èéṣe tí ẹ̀yin fi kẹ́yìn láti mú ọba padà wá sí ilé rẹ̀? Ọ̀rọ̀ gbogbo Israẹli sì ti dé ọ̀dọ̀ ọba àní ní ilé rẹ̀. Ẹ̀yin ni ara mi, ẹ̀yin ni egungun mi, àti ẹran-ara mi: èéṣì ti ṣe tí ẹ̀yin fi kẹ́yìn láti mú ọba padà wá.’ Kí ẹ̀yin sì wí fún Amasa pé, ‘Egungun àti ẹran-ara mi kọ́ ni ìwọ jẹ́ bí? Kí Ọlọ́run ó ṣe bẹ́ẹ̀ sí mi àti jù bẹ́ẹ̀ lọ pẹ̀lú, bí ìwọ kò ba ṣe olórí ogun níwájú mi títí, ní ipò Joabu.’ ” Òun sì yí gbogbo àwọn ọkùnrin Juda lọ́kàn padà àní bí ọkàn ènìyàn kan; wọ́n sì ránṣẹ́ sí ọba, pé, “Ìwọ padà àti gbogbo àwọn ìránṣẹ́ rẹ.” Ọba sì padà, o sì wá sí odò Jordani. Juda sì wá sí Gilgali láti lọ pàdé ọba, àti láti mú ọba kọjá odò Jordani. Ṣimei ọmọ Gera, ará Benjamini ti Bahurimu, ó yára ó sì bá àwọn ọkùnrin Juda sọ̀kalẹ̀ láti pàdé Dafidi ọba. Ẹgbẹ̀rún ọmọkùnrin sì wà lọ́dọ̀ rẹ̀ nínú àwọn ọmọkùnrin Benjamini, Ṣiba ìránṣẹ́ ilé Saulu, àti àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ mẹ́ẹ̀ẹ́dógún àti ogún ìránṣẹ́ sì pẹ̀lú rẹ̀; wọ́n sì gòkè odò Jordani ṣáájú ọba. Ọkọ̀ èrò kan ti rékọjá láti kó àwọn ènìyàn ilé ọba sí òkè, àti láti ṣe èyí tí ó tọ́ lójú rẹ̀. Ṣimei ọmọ Gera wólẹ̀. Ó sì dojúbolẹ̀ níwájú ọba, bí ó tí gòkè odò Jordani. Ó sì wí fún ọba pé, “Kí olúwa mi ó má ṣe ka ẹ̀ṣẹ̀ sí mi lọ́rùn, má sì ṣe rántí àfojúdi tí ìránṣẹ́ rẹ̀ ṣe ni ọjọ́ tí olúwa mi ọba jáde ní Jerusalẹmu, kí ọba má sì fi sí inú. Nítorí pé ìránṣẹ́ rẹ mọ̀ pé èmi ti ṣẹ̀; sì wò ó, mo wá lónìí yìí, ẹni àkọ́kọ́ ní gbogbo ìdílé Josẹfu tí yóò sọ̀kalẹ̀ wá pàdé olúwa mi ọba.” Ṣùgbọ́n Abiṣai ọmọ Seruiah dáhùn ó sì wí pé, “Kò ha tọ́ kí a pa Ṣimei nítorí èyí? Nítorí pé òun ti bú ẹni ààmì òróró OLúWA.” Dafidi sì wí pé, “Kí ni èmi ní ṣe pẹ̀lú yín, ẹ̀yin ọmọ Seruiah tí ẹ dàbí ọ̀tá fún mi lónìí? A ha lè pa ènìyàn kan lónìí ní Israẹli? Tàbí èmi kò ha mọ̀ pé lónìí èmi ni ọba Israẹli.” Ọba sì wí fún Ṣimei pé, “Ìwọ kì yóò kú!” Ọba sì búra fún un.