II. Sam 17:1-2
II. Sam 17:1-2 Bibeli Mimọ (YBCV)
AHITOFELI si wi fun Absalomu pe, Emi o si yan ẹgbãfa ọkunrin emi o si dide, emi o si lepa Dafidi li oru yi. Emi o si yọ si i nigbati ãrẹ̀ ba mu u ti ọwọ́ rẹ̀ si ṣe alaile, emi o si dá ipaiya bá a; gbogbo awọn enia ti o wà lọdọ rẹ̀ yio si sa, emi o si kọlu ọba nikanṣoṣo
II. Sam 17:1-2 Yoruba Bible (YCE)
Lẹ́yìn náà, Ahitofeli wí fún Absalomu pé, “Jẹ́ kí n ṣa ẹgbaafa (12,000) ninu àwọn ọmọ ogun, kí n sì bẹ̀rẹ̀ sí lépa Dafidi lọ lálẹ́ òní. N óo kọlù ú nígbà tí àárẹ̀ bá mú un; tí ọkàn rẹ̀ sì rẹ̀wẹ̀sì; ẹ̀rù yóo bà á, gbogbo àwọn eniyan rẹ̀ yóo sì sá lọ. Ọba nìkan ṣoṣo ni n óo pa.
II. Sam 17:1-2 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Ahitofeli sì wí fún Absalomu pé, “Èmi ó yan ẹgbàafà ọkùnrin èmi ó sì dìde, èmi ó sì lépa Dafidi lóru yìí. Èmi ó sì yọ sí i nígbà tí àárẹ̀ bá mú un tí ọwọ́ rẹ̀ sì ṣe aláìle, èmi ó sì dá a ní ìjì: gbogbo àwọn ènìyàn tí ó wà lọ́dọ̀ rẹ̀ yóò sì sá, èmi ó sì kọlu ọba nìkan ṣoṣo.