II. Sam 16:1-4
II. Sam 16:1-4 Bibeli Mimọ (YBCV)
NIGBATI Dafidi si fi diẹ kọja ori oke na, si wõ, Siba iranṣẹ Mefiboṣeti si mbọ̀ wá ipade rẹ̀, ti on ti kẹtẹkẹtẹ́ meji ti a ti dì li asá, ati igba iṣu akara li ori wọn, ati ọgọrun ṣiri ajara gbigbẹ, ati ọgọrun eso ẹrùn, ati igò ọti-waini kan. Ọba si wi fun Siba pe, Kini wọnyi? Siba si wipe, Kẹtẹkẹtẹ wọnyi ni fun awọn ara ile ọba lati ma gùn; ati akara yi, ati eso ẹrùn yi ni fun awọn ọdọmọdekunrin lati jẹ; ati ọti-waini yi ni fun awọn alãrẹ ni ijù lati mu. Ọba si wipe, Ọmọ oluwa rẹ da? Siba si wi fun ọba pe, Wõ, o joko ni Jerusalemu; nitoriti o wipe, Loni ni idile Israeli yio mu ijọba baba mi pada fun mi wá. Ọba si wi fun Siba pe, Wõ, gbogbo nkan ti iṣe ti Mefiboṣeti jẹ tirẹ. Siba si wipe, Mo tũba, jẹki nri ore-ọfẹ loju rẹ, oluwa mi, Ọba.
II. Sam 16:1-4 Yoruba Bible (YCE)
Ní gẹ́rẹ́ tí Dafidi kọjá góńgó orí òkè náà, Siba, iranṣẹ Mẹfiboṣẹti pàdé rẹ̀, ó ń da àwọn kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ bíi mélòó kan bọ̀ tí ó di igba (200) burẹdi rù, pẹlu ọgọrun-un ṣiiri èso resini, ati ọgọrun-un ṣiiri èso tútù mìíràn ati àpò aláwọ kan tí ó kún fún ọtí waini. Dafidi ọba bi í pé, “Kí ni o fẹ́ fi gbogbo nǹkan wọnyi ṣe?” Siba dá a lóhùn pé, “Mo mú àwọn kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ wọnyi wá kí àwọn ìdílé Kabiyesi lè rí nǹkan gùn, mo mú burẹdi, ati èso wọnyi wá kí àwọn ọdọmọkunrin tí wọ́n wà pẹlu rẹ lè rí nǹkan jẹ; ati ọtí waini, kí àwọn tí àárẹ̀ bá mú ninu aṣálẹ̀ lè rí nǹkan mu.” Ọba tún bi í pé, “Níbo ni Mẹfiboṣẹti, ọmọ ọmọ Saulu, ọ̀gá rẹ wà?” Siba dá a lóhùn pé, “Mẹfiboṣẹti dúró sí Jerusalẹmu; nítorí ó dá a lójú pé, nisinsinyii ni àwọn ọmọ Israẹli yóo dá ìjọba Saulu baba-baba rẹ̀ pada fún un.” Ọba bá sọ fún Siba pé, “Gbogbo ohun tí ó jẹ́ ti Mẹfiboṣẹti di tìrẹ láti ìsinsìnyìí lọ.” Siba sọ fún ọba pé, “Kabiyesi, mo júbà, jọ̀wọ́, jẹ́ kí n máa bá ojurere rẹ pàdé nígbà gbogbo.”
II. Sam 16:1-4 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Nígbà tí Dafidi sì fi díẹ̀ kọjá orí òkè náà, sì wò ó, Ṣiba ìránṣẹ́ Mefiboṣeti sì ń bọ̀ wá pàdé rẹ̀, òun àti kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ méjì tí a ti dì ní gàárì, àti igba ìṣù àkàrà lórí wọn, àti ọgọ́rùn-ún síírí àjàrà gbígbẹ, àti ọgọ́rùn-ún èso ẹ̀rún, àti ìgò ọtí wáìnì kan. Ọba sì wí fún Ṣiba pé, “Kí ni wọ̀nyí?” Ṣiba sì wí pé, “Kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ wọ̀nyí ni fún àwọn ará ilé ọba láti máa gùn àti àkàrà yìí, àti èso ẹ̀rún yìí ni fún àwọn ọ̀dọ́mọdékùnrin láti jẹ; àti ọtí wáìnì yìí ni fún àwọn aláàárẹ̀ ní ijù láti mu.” Ọba sì wí pé, “Ọmọ olúwa rẹ dà?” Ṣiba sì wí fún ọba pé, “Wò ó, ó jókòó ní Jerusalẹmu; nítorí tí ó wí pé, ‘Lónìí ni ìdílé Israẹli yóò mú ìjọba baba mi padà wá fún mi.’ ” Ọba sì wí fún Ṣiba pé, “Wò ó, gbogbo nǹkan tí í ṣe ti Mefiboṣeti jẹ́ tìrẹ.” Ṣiba sì wí pé, “Mo túúbá, jẹ́ kí n rí oore-ọ̀fẹ́ lójú rẹ, olúwa mi ọba.”