II. Sam 13:1-39
II. Sam 13:1-39 Bibeli Mimọ (YBCV)
O si ṣe, lẹhin eyi, Absalomu ọmọ Dafidi ni aburo obinrin kan ti o ṣe arẹwà, orukọ rẹ̀ a si ma jẹ́ Tamari; Amnoni ọmọ Dafidi si fẹràn rẹ̀. Amnoni si banujẹ titi o fi ṣe aisan nitori Tamari aburo rẹ̀ obinrin; nitoripe wundia ni; o si ṣe ohun ti o ṣoro li oju Amnoni lati ba a ṣe nkan kan. Ṣugbọn Amnoni ni ọrẹ́ kan, orukọ rẹ̀ a si ma jẹ Jonadabu, ọmọ Ṣimea ẹgbọ́n Dafidi: Jonadabu si jẹ alarekereke enia gidigidi. O si wi fun u pe, ẽṣe ti iwọ ọmọ ọba nfi nrù lojojumọ bayi? o kì yio ha sọ fun mi? Amnoni si wi fun u pe, emi fẹ Tamari aburo Absalomu arakunrin mi. Jonadabu si wi fun u pe, dubulẹ ni ibusùn rẹ ki iwọ ki o si ṣe bi ẹnipe ara rẹ kò yá: baba rẹ yio si wá iwò ọ, iwọ o si wi fun u pe, Jọ̀wọ jẹ ki Tamari aburo mi ki o wá ki o si fun mi li onjẹ ki o si se onjẹ na niwaju mi ki emi ki o ri i, emi o si jẹ ẹ li ọwọ́ rẹ̀. Amnoni si dubulẹ, o si ṣe bi ẹnipe on ṣaisan: ọba si wá iwò o, Amnoni si wi fun ọba pe, Jọwọ, jẹ ki Tamari aburo mi ki o wá, ki o si din akarà meji li oju mi, emi o si jẹ li ọwọ́ rẹ̀. Dafidi si ranṣẹ si Tamari ni ile pe, Lọ si ile Amnoni ẹgbọ́n rẹ, ki o si ṣe ti onjẹ fun u. Tamari si lọ si ile Amnoni ẹgbọ́n rẹ̀, on si mbẹ ni ibulẹ. Tamari si mu iyẹfun, o si pò o, o si fi ṣe akara li oju rẹ̀, o si din akara na. On si mu awo na, o si dà a sinu awo miran niwaju rẹ̀; ṣugbọn o kọ̀ lati jẹ. Amnoni si wipe, jẹ ki gbogbo ọkunrin jade kuro lọdọ mi. Nwọn si jade olukuluku ọkunrin kuro lọdọ rẹ̀. Amnoni si wi fun Tamari pe, mu onjẹ na wá si yara, emi o si jẹ lọwọ rẹ. Tamari si mu akara ti o ṣe, o si mu u tọ̀ Amnoni ẹgbọ́n rẹ̀ ni iyẹwu. Nigbati o si sunmọ ọ lati fi onjẹ fun u, on si di i mu, o si wi fun u pe, wá dubulẹ tì mi, aburo mi. On si da a lohùn wipe, Bẹ̃kọ ẹgbọ́n mi, máṣe tẹ́ mi; nitoripe ko tọ́ ki a ṣe iru nkan bẹ̃ ni Israeli, iwọ máṣe huwa were yi. Ati emi, nibo li emi o gbe itiju mi wọ̀? iwọ o si dabi ọkan ninu awọn aṣiwere ni Israeli. Njẹ nitorina, emi bẹ̀ ọ, sọ fun ọba; nitoripe on kì yio kọ̀ lati fi mi fun ọ. Ṣugbọn o kọ̀ lati gbọ́ ohùn rẹ̀; o si fi agbara mu u, o si ṣẹgun rẹ̀, o si ba a dapọ̀. Amnoni si korira rẹ̀ gidigidi, irira na si wá jù ifẹ ti on ti ni si i ri lọ. Amnoni si wi fun u pe, Dide, ki o si ma lọ. On si wi fun u pe, Ko ha ni idi bi; lilé ti iwọ nlé mi yi buru jù eyi ti iwọ ti ṣe si mi lọ. Ṣugbọn on ko fẹ gbọ́ tirẹ̀. On si pe ọmọ-ọdọ rẹ̀ ti iṣe iranṣẹ rẹ̀, o si wi fun u pe, Jọwọ, tì obinrin yi sode fun mi, ki o si ti ilẹkùn mọ ọ. On si ni aṣọ alaràbara kan li ara rẹ̀: nitori iru aṣọ awọ̀leke bẹ̃ li awọn ọmọbinrin ọba ti iṣe wundia ima wọ̀. Iranṣẹ rẹ̀ si mu u jade, o si ti ilẹkun mọ ọ. Tamari si bu ẽru si ori rẹ̀, o si fa aṣọ alaràbara ti mbẹ lara rẹ̀ ya, o si ka ọwọ́ rẹ̀ le ori, o si nkigbe bi o ti nlọ. Absalomu ẹgbọ́n rẹ̀ si bi i lere pe, Amnoni ẹgbọ́n rẹ ba ọ ṣe bi? njẹ aburo mi, dakẹ; ẹgbọ́n rẹ ni iṣe; má fi nkan yi si ọkàn rẹ. Tamari si joko ni ibanujẹ ni ile Absalomu ẹgbọ́n rẹ̀. Ṣugbọn nigbati Dafidi ọba gbọ́ gbogbo nkan wọnyi, inu rẹ̀ bajẹ gidigidi. Absalomu ko si ba Amnoni sọ nkan, rere, tabi buburu: nitoripe Absalomu korira Amnoni nitori eyi ti o ṣe, ani ti o fi agbara mu Tamari aburo rẹ̀. O si ṣe, lẹhin ọdun meji, Absalomu si ni olurẹrun agutan ni Baal-hasori, eyiti o gbè Efraimu: Absalomu si pe gbogbo awọn ọmọ ọba. Absalomu si tọ̀ ọba wá, o si wipe, Wõ, jọwọ, iranṣẹ rẹ ni olurẹrun agutan, emi bẹ̀ ọ, jẹ ki ọba, ati awọn iranṣẹ rẹ̀ ba iranṣẹ rẹ lọ. Ọba si wi fun Absalomu pe, Bẹ̃kọ, ọmọ mi, mo bẹ̀ ọ, má jẹ ki gbogbo wa lọ, ki a má mu ọ nawo pupọ. O si rọ̀ ọ gidigidi, ṣugbọn on kò fẹ lọ, o si sure fun u. Absalomu si wi pe, Bi kò ba le ri bẹ̃, emi bẹ̀ ọ, jẹ ki Amnoni ẹgbọ́n mi ba wa lọ. Ọba si wipe, Idi rẹ̀ ti yio fi ba ọ lọ? Absalomu si rọ̀ ọ, on si jẹ ki Amnoni ati gbogbo awọn ọmọ ọba ba a lọ. Absalomu si fi aṣẹ fun awọn iranṣẹ rẹ̀ pe, Ki ẹnyin ki o ma kiyesi akoko ti ọti-waini yio mu ọkàn Amnoni dùn, emi o si wi fun nyin pe, Kọlu Amnoni; ki ẹ si pa a: ẹ má bẹ̀ru: ṣe emi li o fi aṣẹ fun nyin? ẹ ṣe giri, ki ẹ ṣe bi alagbara ọmọ. Awọn iranṣẹ Absalomu si ṣe si Amnoni gẹgẹ bi Absalomu ti paṣẹ. Gbogbo awọn ọmọ ọba si dide, olukuluku gun ibaka rẹ̀, nwọn si sa. O si ṣe, nigbati nwọn mbẹ li ọ̀na, ihìn si de ọdọ Dafidi pe, Absalomu pa gbogbo awọn ọmọ ọba, ọkan kò si kù ninu wọn. Ọba si dide, o si fa aṣọ rẹ̀ ya, o si dubulẹ ni ilẹ; gbogbo awọn iranṣẹ rẹ̀ ti nwọn duro tì i si fa aṣọ wọn ya. Jonadabu ọmọ Ṣimea arakonrin Dafidi si dahùn o si wipe, Ki oluwa mi ọba ki o máṣe rò pe nwọn ti pa gbogbo awọn ọdọmọde-kọnrin awọn ọmọ ọba; nitoripe Amnoni nikanṣoṣo li o kú: nitori lati ẹnu Absalomu wá li a ti pinnu rẹ̀ lati ọjọ ti o ti fi agbara mu Tamari aburo rẹ̀. Njẹ ki oluwa mi ọba ki o máṣe fi nkan yi si ọkàn pe, gbogbo awọn ọmọ ọba li o kú: nitori Amnoni nikanṣoṣo li o kú. Absalomu si sa. Ọdọmọkunrin na ti nṣọ̀na si gbe oju rẹ̀ soke, o si ri pe, ọ̀pọ enia mbọ̀ li ọ̀na lẹhin rẹ̀ lati iha oko wá. Jonadabu si wi fun ọba pe, Wõ, awọn ọmọ ọba mbọ̀: gẹgẹ bi ọ̀rọ iranṣẹ rẹ, bẹ̃ li o ri. O si ṣe, nigbati o ti pari ọ̀rọ isọ, si wõ, awọn ọmọ ọba de, nwọn si gbe ohùn wọn soke, nwọn si sọkun: ọba ati gbogbo awọn iranṣẹ rẹ̀ pẹlu si sọkun nlanla. Absalomu si sa, o si tọ̀ Talmai lọ, ọmọ Ammihudu, ọba Geṣuri. Dafidi si nkãnu nitori ọmọ rẹ̀ lojojumọ. Absalomu si sa, o si lọ si Geṣuri, o si gbe ibẹ li ọdun mẹta. Ọkàn Dafidi ọba si fà gidigidi si Absalomu: nitoriti o ti gbà ipẹ̀ niti Amnoni: o sa ti kú.
II. Sam 13:1-39 Yoruba Bible (YCE)
Absalomu ọmọ Dafidi ní arabinrin kan tí ó jẹ́ arẹwà, orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Tamari. Dafidi tún ní ọmọkunrin mìíràn tí ń jẹ́ Amnoni. Amnoni yìí fẹ́ràn Tamari lọpọlọpọ. Amnoni fẹ́ràn rẹ̀ tóbẹ́ẹ̀ gẹ́ẹ́ tí ó di àìsàn sí i lára. Wundia ni Tamari, kò tíì mọ ọkunrin rí; nítorí náà ó dàbí ẹni pé kò ṣeéṣe fún Amnoni láti bá a ṣe nǹkankan. Ṣugbọn Amnoni ní ọ̀rẹ́ kan, tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Jonadabu, ọmọ Ṣimea, ọ̀kan ninu àwọn arakunrin Dafidi. Jonadabu yìí jẹ́ alárèékérekè eniyan. Ní ọjọ́ kan, ó bèèrè lọ́wọ́ Amnoni pé, “Ṣebí ọmọ ọba ni ọ́, kí ló dé tí ò ń rù lojoojumọ? Sọ fún mi.” Amnoni dá a lóhùn pé, “Ìfẹ́ Tamari, àbúrò Absalomu, arakunrin mi, ni ó wọ̀ mí lọ́kàn tóbẹ́ẹ̀.” Jonadabu dáhùn, ó ní, “Lọ dùbúlẹ̀ lórí ibùsùn rẹ, kí o sì ṣe bí ẹni pé ara rẹ kò yá. Nígbà tí baba rẹ bá wá bẹ̀ ọ́ wò, wí fún un pé, kí ó jọ̀wọ́ kí ó jẹ́ kí Tamari arabinrin rẹ wá fún ọ ní oúnjẹ. Sọ fún un pé, o fẹ́ kí ó wá se oúnjẹ náà lọ́dọ̀ rẹ níbi tí o ti lè máa rí i, kí ó sì fi ọwọ́ ara rẹ̀ gbé e fún ọ.” Amnoni bá dùbúlẹ̀, ó ṣe bí ẹni tí ó ń ṣàìsàn. Nígbà tí Dafidi ọba lọ bẹ̀ ẹ́ wò, Amnoni wí fún un pé, “Jọ̀wọ́, jẹ́ kí Tamari, arabinrin mi, wá ṣe àkàrà díẹ̀ lọ́dọ̀ mi níhìn-ín, níbi tí mo ti lè máa rí i, kí ó sì gbé e wá fún mi.” Dafidi bá ranṣẹ pe Tamari ninu ààfin, ó ní kí ó lọ sinu ilé Amnoni, kí ó lọ tọ́jú oúnjẹ fún un. Tamari lọ, ó bá Amnoni lórí ibùsùn níbi tí ó dùbúlẹ̀ sí. Ó bu ìyẹ̀fun díẹ̀, ó pò ó, ó gé e ní ìwọ̀n àkàrà bíi mélòó kan, níbi tí Amnoni ti lè máa rí i. Lẹ́yìn náà, ó gbé e sórí iná títí tí ó fi jinná, ó sì dà á sinu àwo kan, ó gbé e fún un. Ṣugbọn Amnoni kọ̀, kò jẹ ẹ́, ó ní kí ó sọ fún gbogbo àwọn tí wọ́n wà ninu ilé kí wọ́n jáde, gbogbo wọn bá jáde. Amnoni bá sọ fún un pé, “Gbé e tọ̀ mí wá ninu yàrá mi, kí o sì gbé e kalẹ̀ níwájú mi.” Tamari bá gbé àkàrà náà, ó sì tọ Amnoni lọ láti gbé e kalẹ̀ níwájú rẹ̀ ninu yàrá. Bí ó ti ń gbé e fún un, ni Amnoni gbá a mú, ó wí fún un pé, “Wá, mo fẹ́ bá ọ lòpọ̀.” Tamari dáhùn pé, “Rárá, má fi ipá mú mi, nítorí ẹnìkan kò gbọdọ̀ dán irú rẹ̀ wò ní Israẹli, má hùwà òmùgọ̀; níbo ni mo fẹ́ fi ojú sí láàrin gbogbo eniyan? Ohun ìtìjú patapata ni yóo sì jẹ́ fún ìwọ náà ní Israẹli. Jọ̀wọ́, bá ọba sọ̀rọ̀, mo mọ̀ dájúdájú pé yóo fi mí fún ọ.” Ṣugbọn Amnoni kọ̀, kò gbọ́ ohun tí Tamari sọ fún un. Nígbà tí ó sì jẹ́ pé Amnoni lágbára jù ú lọ, ó fi tipátipá bá a lòpọ̀. Lẹ́yìn náà, Amnoni kórìíra rẹ̀ gidigidi. Ìkórìíra náà pọ̀ tóbẹ́ẹ̀ tí ó tún wá ju bí ó ti nífẹ̀ẹ́ rẹ̀ tẹ́lẹ̀ lọ. Ó ní kí ó bọ́ sóde, kí ó máa lọ. Tamari dá a lóhùn pé, “Rárá, arakunrin mi, lílé tí ò ń lé mi jáde yìí burú ju ipá tí o fi bá mi lòpọ̀ lọ.” Ṣugbọn Amnoni kọ̀, kò gbọ́ tirẹ̀. Kàkà bẹ́ẹ̀, Amnoni pe iranṣẹ rẹ̀ kan, ó wí fún un pé, “Mú obinrin yìí jáde kúrò níwájú mi, tì í sóde, kí o sì ti ìlẹ̀kùn mọ́ ọn.” Iranṣẹ náà bá ti Tamari jáde, ó sì ti ìlẹ̀kùn mọ́ ọn. Aṣọ àwọ̀kanlẹ̀ alápá gígùn, irú èyí tí àwọn ọmọ ọba, obinrin, tí kò tíì wọlé ọkọ máa ń wọ̀, ni Tamari wọ̀. Tamari bá ku eérú sí orí, ó fa aṣọ rẹ̀ ya, ó káwọ́ lórí, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí sọkún bí ó ti ń lọ. Nígbà tí Absalomu, ẹ̀gbọ́n Tamari, rí i, ó bi í léèrè pé, “Ṣé Amnoni bá ọ lòpọ̀ ni? Jọ̀wọ́, arabinrin mi, gbé ọ̀rọ̀ náà kúrò lọ́kàn, ọmọ baba kan náà ni ẹ̀yin mejeeji, nítorí náà, má sọ fún ẹnikẹ́ni.” Tamari bá ń gbé ilé Absalomu. Òun nìkan ni ó dá wà, inú rẹ̀ sì bàjẹ́ pupọ. Nígbà tí Dafidi ọba gbọ́ ohun tí ó ṣẹlẹ̀, inú bí i gidi. Absalomu kórìíra Amnoni gan-an nítorí pé ó fi ipá bá Tamari, àbúrò rẹ̀, lòpọ̀, ṣugbọn kò bá a sọ nǹkankan; ìbáà ṣe rere ìbáà sì ṣe burúkú. Lẹ́yìn ọdún meji tí nǹkan yìí ṣẹlẹ̀, Absalomu lọ rẹ́ irun aguntan rẹ̀ ní Baali Hasori, lẹ́bàá ìlú Efuraimu, ó sì pe gbogbo àwọn ọmọ ọba patapata lọkunrin sibẹ. Ó lọ sí ọ̀dọ̀ Dafidi ọba, ó wí fún un pé, “Kabiyesi, iranṣẹ rẹ ń rẹ́ irun aguntan rẹ̀, mo sì fẹ́ kí kabiyesi ati gbogbo àwọn oníṣẹ́ rẹ̀ wá síbi àjọ̀dún náà.” Ọba ní, “Rárá, ọmọ mi, bí gbogbo wa bá lọ, wahala náà yóo pọ̀jù fún ọ.” Absalomu rọ ọba títí, ṣugbọn ó kọ̀ jálẹ̀. Ọba bá súre fún un, ó ní kí ó máa lọ. Absalomu dáhùn pé, “Ó dára, bí o kò bá lè lọ, ṣé o óo jẹ́ kí Amnoni arakunrin mi lọ?” Ọba bá bèèrè pé, “Nítorí kí ni yóo ṣe ba yín lọ?” Ṣugbọn Absalomu rọ Dafidi títí tí ó fi gbà pé kí Amnoni ati àwọn ọmọ ọba yòókù lọkunrin bá a lọ. Absalomu sì se àsè rẹpẹtẹ, bí ẹni pé ọba ni ó fẹ́ ṣe lálejò. Absalomu wí fún àwọn iranṣẹ rẹ̀ pé, “Ẹ máa kíyèsí Amnoni, nígbà tí ó bá mu ọtí yó, bí mo bá ti fun yín ní àṣẹ pé kí ẹ pa á, pípa ni kí ẹ pa á, ẹ má bẹ̀rù; èmi ni mo ran yín. Ẹ mú ọkàn gírí kí ẹ sì ṣe bí akikanju.” Àwọn iranṣẹ náà bá tẹ̀lé àṣẹ rẹ̀, wọ́n sì pa Amnoni. Gbogbo àwọn ọmọ Dafidi yòókù bá gun kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ wọn, wọ́n sì sá lọ. Nígbà tí wọn ń sá bọ̀ wálé, àwọn kan wá sọ fún Dafidi pé, “Absalomu ti pa gbogbo àwọn ọmọ rẹ, ati pé kò ṣẹ́ku ẹyọ ẹnìkan.” Ọba dìde, ó fa aṣọ rẹ̀ ya láti fi ìbànújẹ́ rẹ̀ hàn, ó sì sùn sórí ilẹ̀ lásán, àwọn iranṣẹ rẹ̀ tí wọ́n wà pẹlu rẹ̀ fa aṣọ tiwọn náà ya. Ṣugbọn Jonadabu, ọmọ Ṣimea, arakunrin Dafidi, wí fún ọba pé, “Kabiyesi, ẹnikẹ́ni kò pa gbogbo àwọn ọmọ rẹ. Amnoni nìkan ni Absalomu pàṣẹ pé kí wọ́n pa. Láti ìgbà tí Amnoni ti fi ipá bá Tamari, arabinrin rẹ̀ lòpọ̀, ni ó ti pinnu láti ṣe ohun tí ó ṣe yìí. Nítorí náà, kí oluwa mi má gba ìròyìn tí wọ́n mú wá gbọ́, pé gbogbo àwọn ọmọ rẹ̀ ni wọ́n ti kú. Amnoni nìkan ni wọ́n pa.” Absalomu sá lọ ní àkókò yìí. Kò pẹ́ rárá, lẹ́yìn náà, ọmọ ogun tí ń ṣọ́ ọ̀nà tí ó wọ ìlú rí ogunlọ́gọ̀ eniyan, wọ́n ń bọ̀ láti ọ̀nà Horonaimu, lẹ́bàá òkè. Jonadabu bá sọ fún ọba pé, “Àwọn ọmọ oluwa mi ni wọ́n ń bọ̀ yìí, gẹ́gẹ́ bí mo ti wí.” Ó fẹ́rẹ̀ má tíì dákẹ́ ọ̀rọ̀ tí ó ń sọ, tí àwọn ọmọ Dafidi fi wọlé, tí wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí sọkún, Dafidi ati àwọn iranṣẹ rẹ̀ náà sì sọkún tẹ̀dùntẹ̀dùn. Ṣugbọn Absalomu sá lọ sọ́dọ̀ Talimai, ọmọ Amihudu, ọba Geṣuri, Dafidi sì ń ṣọ̀fọ̀ ọmọ rẹ̀ lojoojumọ. Absalomu wà ní Geṣuri níbi tí ó sá lọ fún ọdún mẹta. Nígbà tí ó yá tí Dafidi gbé ìbànújẹ́ ikú Amnoni ọmọ rẹ̀ kúrò lára, ọkàn Absalomu ọmọ rẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí fà á.
II. Sam 13:1-39 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Ó sì ṣe, lẹ́yìn èyí, Absalomu ọmọ Dafidi ní àbúrò obìnrin kan tí ó ṣe arẹwà, orúkọ rẹ̀ a sì máa jẹ́ Tamari; Amnoni ọmọ Dafidi sì fẹ́ràn rẹ̀. Amnoni sì banújẹ́ títí ó fi ṣe àìsàn nítorí Tamari àbúrò rẹ̀ obìnrin; nítorí pé wúńdíá ni; ó sì ṣe ohun tí ó ṣòro lójú Amnoni láti bá a dàpọ̀. Ṣùgbọ́n Amnoni ní ọ̀rẹ́ kan, orúkọ rẹ̀ a sì máa jẹ́ Jonadabu, ọmọ Ṣimea ẹ̀gbọ́n Dafidi: Jonadabu sì jẹ́ alárékérekè ènìyàn gidigidi. Ó sì wí fún un pé, “Èéṣe tí ìwọ ọmọ ọba ń fi ń rù lójoojúmọ́ báyìí? Ǹjẹ́ o kò ní sọ fún mi?” Amnoni sì wí fún un pé, “Èmi fẹ́ Tamari àbúrò Absalomu arákùnrin mi.” Jonadabu sì wí fún un pé, “Dùbúlẹ̀ ní ibùsùn rẹ kí ìwọ sì díbọ́n pé, ìwọ kò sàn: baba rẹ yóò sì wá wò ọ́, ìwọ ó sì wí fún un pé, ‘Jọ̀wọ́ jẹ́ kí Tamari àbúrò mi wá kí ó sì fún mi ní oúnjẹ kí ó sì ṣe oúnjẹ náà níwájú mi kí èmi ó rí i, èmi ó sì jẹ ẹ́ ní ọwọ́ rẹ̀.’ ” Amnoni sì dùbúlẹ̀, ó sì díbọ́n pé òun ṣàìsàn: ọba sì wá wò ó, Amnoni sì wí fún ọba pé, “Jọ̀wọ́, jẹ́ kí Tamari àbúrò mi ó wá, kí ó sì dín àkàrà méjì lójú mi, èmi ó sì jẹ ní ọwọ́ rẹ̀.” Dafidi sì ránṣẹ́ sí Tamari ní ilé pé, “Lọ sí ilé Amnoni ẹ̀gbọ́n rẹ, kí ó sì se oúnjẹ fún un.” Tamari sì lọ sí ilé Amnoni ẹ̀gbọ́n rẹ̀, òun sì ń bẹ ní ìdùbúlẹ̀. Tamari sì mú ìyẹ̀fun, ó sì pò ó, ó sì fi ṣe àkàrà lójú rẹ̀, ó sì dín àkàrà náà. Òun sì mú àwo náà, ó sì dà á sínú àwo mìíràn níwájú rẹ̀; ṣùgbọ́n ó kọ̀ láti jẹ. Amnoni sì wí pé, “Jẹ́ kí gbogbo ọkùnrin jáde kúrò lọ́dọ̀ mi!” Wọ́n sì jáde olúkúlùkù ọkùnrin kúrò lọ́dọ̀ rẹ̀. Amnoni sì wí fún Tamari pé, “Mú oúnjẹ náà wá sí yàrá, èmi ó sì jẹ ẹ́ lọ́wọ́ rẹ.” Tamari sì mú àkàrà tí ó ṣe, ó sì mú un tọ Amnoni ẹ̀gbọ́n rẹ̀ ní yàrá. Nígbà tí ó sì súnmọ́ ọn láti fi oúnjẹ fún un, òun sì dìímú, ó sì wí fún un pé, “Wá dùbúlẹ̀ tì mí, àbúrò mi.” Òun sì dá a lóhùn wí pé, “Bẹ́ẹ̀ kọ́ ẹ̀gbọ́n mi, má ṣe tẹ́ mi; nítorí pé kò tọ kí a ṣe irú nǹkan bẹ́ẹ̀ ní Israẹli, ìwọ má ṣe hùwà òmùgọ̀ yìí. Àti èmi, níbo ni èmi ó gbé ìtìjú mi wọ̀? Ìwọ ó sì dàbí ọ̀kan nínú àwọn aṣiwèrè ní Israẹli. Ǹjẹ́ nítorí náà, èmi bẹ̀ ọ́, sọ fún ọba; nítorí pé òun kì yóò kọ̀ láti fi mí fún ọ.” Ṣùgbọ́n ó kọ̀ láti gbọ́ ohùn rẹ̀; ó sì fi agbára mú un, ó sì ṣẹ́gun rẹ̀, ó sì bá a dàpọ̀. Amnoni sì kórìíra rẹ̀ gidigidi, ìríra náà sì wá ju ìfẹ́ tí òun ti ní sí i rí lọ. Amnoni sì wí fún un pé, “Dìde, kí o sì máa lọ!” Òun sì wí fún un pé, “Kó ha ní ìdí bí! Lílé tí ìwọ ń lé mi yìí burú ju èyí tí ìwọ ti ṣe sí mi lọ.” Ṣùgbọ́n òun kò fẹ́ gbọ́ tirẹ̀. Òun sì pe ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ̀ tí í ṣe ìránṣẹ́ rẹ̀, ó sì wí fún un pé, “Jọ̀wọ́, ti obìnrin yìí sóde fún mi, kí o sì ti ìlẹ̀kùn mọ́ ọn.” Òun sì ní aṣọ aláràbarà kan lára rẹ̀: nítorí irú aṣọ àwọ̀lékè bẹ́ẹ̀ ni àwọn ọmọbìnrin ọba tí í ṣe wúńdíá máa ń wọ̀. Ìránṣẹ́ rẹ̀ sì mú un jáde, ó sì ti ìlẹ̀kùn mọ́ ọn. Tamari sì bu eérú sí orí rẹ̀, ó sì fa aṣọ aláràbarà tí ń bẹ lára rẹ̀ ya, ó sì ká ọwọ́ rẹ̀ lé orí, ó sì ń kígbe bí ó ti ń lọ. Absalomu ẹ̀gbọ́n rẹ̀ sì bí i léèrè pé, “Amnoni ẹ̀gbọ́n rẹ bá ọ sùn bí? Ǹjẹ́ àbúrò mi, dákẹ́; ẹ̀gbọ́n rẹ ní í ṣe; má fi nǹkan yìí sí ọkàn rẹ.” Tamari sì jókòó ní ìbànújẹ́ ní ilé Absalomu ẹ̀gbọ́n rẹ̀. Ṣùgbọ́n nígbà tí Dafidi ọba gbọ́ gbogbo nǹkan wọ̀nyí, inú rẹ̀ bàjẹ́ gidigidi. Absalomu kò sì bá Amnoni sọ nǹkan rere, tàbí búburú: nítorí pé Absalomu kórìíra Amnoni nítorí èyí tí ó ṣe, àní tí ó fi agbára mú Tamari àbúrò rẹ̀. Ó sì ṣe, lẹ́yìn ọdún méjì, Absalomu sì ní olùrẹ́run àgùntàn ní Baali-Hasori, èyí tí ó gbé Efraimu: Absalomu sì pe gbogbo àwọn ọmọ ọba. Absalomu sì tọ ọba wá, ó sì wí pé, “Wò ó, jọ̀wọ́, ìránṣẹ́ rẹ ní olùrẹ́run àgùntàn, èmi bẹ̀ ọ́, jẹ́ kí ọba, àti àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ bá ìránṣẹ́ rẹ lọ.” Ọba sì wí fún Absalomu pé, “Bẹ́ẹ̀ kọ, ọmọ mi, mo bẹ̀ ọ́, má ṣe jẹ́ kí gbogbo wa lọ, kí a má bá à mú ọ náwó púpọ̀.” Ó sì rọ̀ ọ́ gidigidi, ṣùgbọ́n òun kò fẹ́ lọ, òun sì súre fún un. Absalomu sì wí pé, “Bí kò bá le rí bẹ́ẹ̀, èmi bẹ̀ ọ́, jẹ́ kí Amnoni ẹ̀gbọ́n mi bá wa lọ.” Ọba sì wí pé, “Ìdí rẹ̀ tí yóò fi bá ọ lọ.” Absalomu sì rọ̀ ọ́, òun sì jẹ́ kí Amnoni àti gbogbo àwọn ọmọ ọba bá a lọ. Absalomu sì fi àṣẹ fún àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ pé, “Kí ẹ̀yin máa kíyèsi àkókò tí ọtí-wáinì yóò mú ọkàn Amnoni dùn, èmi ó sì wí fún yín pé, ‘Kọlu Amnoni,’ kí ẹ sì pa á. Ẹ má bẹ̀rù. Ṣé èmi ni ó fi àṣẹ fún yin? Ẹ ṣe gírí, kí ẹ ṣe bí alágbára ọmọ.” Àwọn ìránṣẹ́ Absalomu sì ṣe sí Amnoni gẹ́gẹ́ bí Absalomu ti pàṣẹ. Gbogbo àwọn ọmọ ọba sì dìde, olúkúlùkù gun ìbáaka rẹ̀, wọ́n sì sá. Nígbà tí wọ́n ń bẹ lọ́nà, ìròyìn sì dé ọ̀dọ̀ Dafidi pé, “Absalomu pa gbogbo àwọn ọmọ ọba, ọ̀kan kò sì kù nínú wọn.” Ọba sì dìde, ó sì fa aṣọ rẹ̀ ya, ó sì dùbúlẹ̀ ni ilẹ̀; gbogbo àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ tí wọ́n dúró tì í sì fà aṣọ wọn ya. Jonadabu ọmọ Ṣimea arákùnrin Dafidi sì dáhùn ó sì wí pé, “Kí olúwa mi ọba má ṣe rò pé wọ́n ti pa gbogbo àwọn ọ̀dọ́mọdékùnrin àwọn ọmọ ọba; nítorí pé Amnoni nìkan ṣoṣo ni ó kú: nítorí láti ẹnu Absalomu wá ni a ti pinnu rẹ̀ láti ọjọ́ tí ó ti fi agbára mú Tamari àbúrò rẹ̀. Ǹjẹ́ kí olúwa mi ọba má ṣe fi nǹkan yìí sí ọkàn pé gbogbo àwọn ọmọ ọba ni o kú: nítorí Amnoni nìkan ṣoṣo ni ó kú.” Absalomu sì sá. Ọ̀dọ́mọkùnrin náà ti ń ṣọ́nà sì gbé ojú rẹ̀ sókè, o si rí i pé, “ọ̀pọ̀ ènìyàn ń bọ́ lọ́nà lẹ́yìn rẹ̀ láti ìhà òkè wá.” Jonadabu sì wí fún ọba pé, “Wò ó, àwọn ọmọ ọba ń bọ́; gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ ìránṣẹ́ rẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni ó rí.” Nígbà tí ó sì parí ọ̀rọ̀ tí ó ń sọ, sì wò ó àwọn ọmọ ọba dé, wọ́n sì gbé ohùn wọn sókè, wọ́n sì sọkún: ọba àti gbogbo àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ pẹ̀lú sì sọkún ńláńlá. Absalomu sì sá, ó sì tọ Talmai lọ, ọmọ Ammihudu, ọba Geṣuri. Dafidi sì ń káàánú nítorí ọmọ rẹ̀ lójoojúmọ́. Absalomu sì sá, ó sì lọ sí Geṣuri ó sì gbé ibẹ̀ lọ́dún mẹ́ta. Ọkàn Dafidi ọba sì fà gidigidi sí Absalomu: nítorí tí ó tí gba ìpẹ̀ ní ti Amnoni: ó sá à ti kú.