II. Sam 12:7-12
II. Sam 12:7-12 Bibeli Mimọ (YBCV)
Natani si wi fun Dafidi pe, Iwọ li ọkunrin na. Bayi li Oluwa Ọlọrun Israeli wi, Emi fi ọ jọba lori Israeli, emi si gbà ọ lọwọ Saulu; Emi si fi ile oluwa rẹ fun ọ, ati awọn obinrin oluwa rẹ si aiyà rẹ, emi si fi idile Israeli ati ti Juda fun ọ; iba tilẹ ṣepe eyini kere jù, emi iba si fun ọ ni nkan bayi bayi. Eṣe ti iwọ fi kẹgàn ọ̀rọ Oluwa, ti iwọ fi ṣe nkan ti o buru li oju rẹ̀, ani ti iwọ fi fi idà pa Uria ará Hitti, ati ti iwọ fi mu obinrin rẹ̀ lati fi ṣe obinrin rẹ, o si fi idà awọn ọmọ Ammoni pa a. Njẹ nitorina idà kì yio kuro ni ile rẹ titi lai; nitoripe iwọ gàn mi, iwọ si mu aya Uria ará Hitti lati fi ṣe aya rẹ. Bayi li Oluwa wi, Kiye si i, Emi o jẹ ki ibi ki o dide si ọ lati inu ile rẹ wá, emi o si gbà awọn obinrin rẹ loju rẹ, emi o si fi wọn fun aladugbo rẹ, on o si ba awọn obinrin rẹ sùn niwaju õrun yi. Ati pe iwọ ṣe e ni ikọ̀kọ: ṣugbọn emi o ṣe nkan yi niwaju gbogbo Israeli, ati niwaju õrun.
II. Sam 12:7-12 Yoruba Bible (YCE)
Natani bá dá Dafidi lóhùn pé, “Ìwọ gan-an ni ẹni náà. Ohun tí OLUWA Ọlọrun Israẹli sì ní kí n wí fún ọ nìyí; ó ní, ‘Mo fi ọ́ jọba lórí Israẹli, mo sì gbà ọ́ kúrò lọ́wọ́ Saulu. Mo fún ọ ní ilé oluwa rẹ ati àwọn aya rẹ̀. Mo fi ọ́ jọba lórí Israẹli ati Juda. Ati pé, bí èyí kò bá tó ọ, ǹ bá fún ọ ní ìlọ́po meji rẹ̀. Kí ló dé tí o fi kẹ́gàn ọ̀rọ̀ OLUWA, tí o sì ṣe nǹkan burúkú yìí níwájú rẹ̀. Ìwọ ni o fi Uraya fún ogun pa; tí o jẹ́ kí àwọn Amoni pa á. Lẹ́yìn náà, o gba aya rẹ̀. Nítorí náà, ogun kò ní kúrò ní ìdílé rẹ títí lae; nítorí pé o ti kẹ́gàn mi, o sì ti gba aya Uraya. Èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀. Wò ó! N óo jẹ́ kí ẹnìkan ninu ìdílé rẹ ṣe ibi sí ọ. Ojú rẹ ni yóo ṣe tí n óo fi fi àwọn aya rẹ fún ẹlòmíràn, tí yóo sì máa bá wọn lòpọ̀ ní ọ̀sán gangan. Níkọ̀kọ̀ ni o dá ẹ̀ṣẹ̀ yìí, ṣugbọn níwájú gbogbo Israẹli, ní ọ̀sán gangan, ni n óo ṣe ohun tí mò ń sọ yìí.’ ”
II. Sam 12:7-12 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Natani sì wí fún Dafidi pé, “Ìwọ ni ọkùnrin náà Báyìí ni OLúWA Ọlọ́run Israẹli wí, ‘Èmi fi ọ́ jẹ ọba lórí Israẹli, èmi sì gbà ọ́ lọ́wọ́ Saulu. Èmi sì fi ilé olúwa rẹ fún ọ, àti àwọn obìnrin olúwa rẹ sí àyà rẹ, èmi sì fi ìdílé Israẹli àti ti Juda fún ọ; tí àwọn wọ̀nyí bá sì kéré jù fún ọ èmi ìbá sì fún ọ sí i jù bẹ́ẹ̀ lọ. Èéṣe tí ìwọ fi kẹ́gàn ọ̀rọ̀ OLúWA, tí ìwọ fi ṣe nǹkan tí ó burú lójú rẹ̀, àní tí ìwọ fi fi idà pa Uriah ará Hiti, àti tí ìwọ fi mú obìnrin rẹ̀ láti fi ṣe obìnrin rẹ, o sì fi idà àwọn ọmọ Ammoni pa á. Ǹjẹ́ nítorí náà idà kì yóò kúrò ní ilé rẹ títí láé; nítorí pé ìwọ gàn mí, ìwọ sì mú aya Uriah ará Hiti láti ṣe aya rẹ.’ “Báyìí ni OLúWA wí, Kíyèsi i, ‘Èmi ó jẹ́ kí ibi kí ó dìde sí ọ láti inú ilé rẹ wá, èmi ó sì gba àwọn obìnrin rẹ lójú rẹ, èmi ó sì fi wọ́n fún aládùúgbò rẹ, òun ó sì bá àwọn obìnrin rẹ sùn níwájú òòrùn yìí. Àti pé ìwọ ṣe é ní ìkọ̀kọ̀: Ṣùgbọ́n èmi ó ṣe nǹkan yìí níwájú gbogbo Israẹli, àti níwájú òòrùn.’ ”