II. Sam 12:13-15
II. Sam 12:13-15 Bibeli Mimọ (YBCV)
Dafidi si wi fun Natani pe, Emi ṣẹ̀ si Oluwa. Natani si wi fun Dafidi pe, Oluwa pẹlu si ti mu ẹ̀ṣẹ rẹ kuro; iwọ kì yio kú. Ṣugbọn nitori nipa iwa yi, iwọ fi aye silẹ fun awọn ọta Oluwa lati sọ ọ̀rọ òdi, ọmọ na ti a o bi fun ọ, kiku ni yio ku. Natani si lọ si ile rẹ̀. Oluwa si fi arùn kọlù ọmọ na ti obinrin Uria bi fun Dafidi, o si ṣe aisàn pupọ.
II. Sam 12:13-15 Yoruba Bible (YCE)
Dafidi bá dáhùn pé, “Mo ti ṣẹ̀ sí OLUWA.” Natani dá a lóhùn pé, “OLUWA ti dáríjì ọ́, o kò sì ní kú. Ṣugbọn nítorí pé ohun tí o ṣe yìí jẹ́ àfojúdi sí OLUWA, ọmọ tí ó bí fún ọ yóo kú.” Natani bá lọ sí ilé rẹ̀.
II. Sam 12:13-15 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Dafidi sì wí fún Natani pé, “Èmi ṣẹ̀ sí OLúWA!” Natani sì wí fún Dafidi pé, “OLúWA pẹ̀lú sì ti mú ẹ̀ṣẹ̀ rẹ kúrò; ìwọ kì yóò kú. Ṣùgbọ́n nítorí nípa ìwà yìí, ìwọ fi ààyè sílẹ̀ fún àwọn ọ̀tá OLúWA láti sọ ọ̀rọ̀-òdì, ọmọ náà tí a ó bí fún ọ, kíkú ní yóò kú.” Natani sì lọ sí ilé rẹ̀ OLúWA sì fi ààrùn kọlu ọmọ náà tí obìnrin Uriah bí fún Dafidi, ó sì ṣe àìsàn púpọ̀.