II. Sam 12:1-3
II. Sam 12:1-3 Bibeli Mimọ (YBCV)
OLUWA si ran Natani si Dafidi. On si tọ̀ ọ wá, o si wi fun u pe, Ọkunrin meji mbẹ ni ilu kan; ọkan jẹ ọlọrọ̀, ekeji si jẹ talaka. Ọkunrin ọlọrọ̀ na si ni agutan ati malu li ọ̀pọlọpọ, Ṣugbọn ọkunrin talaka na kò si ni nkan, bikoṣe agutan kekere kan, eyi ti o ti rà ti o si ntọ́: o si dagba li ọwọ́ rẹ̀ pẹlu awọn ọmọ rẹ̀; a ma jẹ ninu onjẹ rẹ̀, a si ma mu ninu ago rẹ̀, a si ma dubulẹ li aiya rẹ̀, o si dabi ọmọbinrin kan fun u.
II. Sam 12:1-3 Yoruba Bible (YCE)
OLUWA rán Natani wolii sí Dafidi. Natani bá tọ Dafidi lọ, ó sì sọ fún un pé, “Àwọn ọkunrin meji wà ninu ìlú kan, ọ̀kan jẹ́ ọlọ́rọ̀, ekeji sì jẹ́ talaka. Ọkunrin ọlọ́rọ̀ yìí ní ọpọlọpọ agbo mààlúù, ati agbo aguntan. Ṣugbọn ọkunrin talaka yìí kò ní nǹkankan, àfi ọmọ aguntan kékeré kan tí ó rà, tí ó sì ń tọ́jú títí tí ó fi dàgbà ninu ilé rẹ̀, pẹlu àwọn ọmọ rẹ̀. Ninu oúnjẹ tí òun pàápàá ń jẹ ni ó ti ń fún un jẹ, igbá tí ọkunrin yìí fi ń mu omi ni ó fi ń bu omi fún ọmọ aguntan rẹ̀ mu. A sì máa gbé e jókòó lórí ẹsẹ̀, bí ẹni pé ọmọ rẹ̀ gan-an ni.
II. Sam 12:1-3 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
OLúWA sì rán Natani sí Dafidi òun sì tọ̀ ọ́ wá, ó sì wí fún un pé, “Ọkùnrin méjì ń bẹ ní ìlú kan; ọ̀kan jẹ́ ọlọ́rọ̀, èkejì sì jẹ́ tálákà. Ọkùnrin ọlọ́rọ̀ náà sì ní àgùntàn àti màlúù lọ́pọ̀lọpọ̀. Ṣùgbọ́n ọkùnrin tálákà náà kò sì ní nǹkan bí kò ṣe àgùntàn kékeré kan èyí tí ó sì ń tọ́: ó sì dàgbà ní ọwọ́ rẹ̀ pẹ̀lú àwọn ọmọ rẹ̀; a máa jẹ nínú oúnjẹ rẹ̀, a sí máa mu nínú ago rẹ̀, a sì máa dùbúlẹ̀ ní àyà rẹ̀, ó sì dàbí ọmọbìnrin kan fún un.