II. Sam 11:3-9
II. Sam 11:3-9 Bibeli Mimọ (YBCV)
Dafidi si ranṣẹ, o si bere obinrin na. Ẹnikan si wipe, Eyi kọ Batṣeba, ọmọbinrin Eliami, aya Uria ará Hitti? Dafidi si rán awọn iranṣẹ, o si mu u; on si wọ inu ile tọ̀ ọ lọ, on si ba a dapọ̀: nigbati o si wẹ ara rẹ̀ mọ́ tan, o si pada lọ si ile rẹ̀. Obinrin na si fẹra kù, o si ranṣẹ o si sọ fun Dafidi, o si wipe, Emi fẹra kù. Dafidi si ranṣẹ si Joabu, pe, Ran Uria ará Hitti si mi. Joabu si ran Uria si Dafidi. Nigbati Uria si de ọdọ rẹ̀, Dafidi si bi i li ere alafia Joabu, ati alafia awọn enia na, ati bi ogun na ti nṣe. Dafidi si wi fun Uria pe, Sọkalẹ lọ si ile rẹ, ki o si wẹ ẹsẹ rẹ. Uria si jade kuro ni ile ọba, onjẹ lati ọdọ ọba wá si tọ̀ ọ lẹhin. Ṣugbọn Uria sùn li ẹnu-ọ̀na ile ọba lọdọ gbogbo iranṣẹ oluwa rẹ̀, kò si sọkalẹ lọ si ile rẹ̀.
II. Sam 11:3-9 Yoruba Bible (YCE)
Dafidi bá rán oníṣẹ́ lọ, láti wádìí aya ẹni tí obinrin náà í ṣe. Ẹnìkan sì sọ fún un pé Batiṣeba ọmọ Eliamu ni, aya Uraya, ará Hiti. Dafidi bá ranṣẹ lọ pè é. Nígbà tí ó dé ọ̀dọ̀ rẹ̀, ó bá a lòpọ̀. Batiṣeba sì ṣẹ̀ṣẹ̀ parí ètò ìwẹ̀nùmọ́ rẹ̀ lẹ́yìn tí ó parí nǹkan oṣù rẹ̀ ni. Ó bá pada lọ sí ilé rẹ̀. Nígbà tí ó yá, ó rí i pé òun lóyún, ó sì rán oníṣẹ́, pé kí wọ́n sọ fún Dafidi ọba. Dafidi bá ranṣẹ sí Joabu, pé kí ó fi Uraya ará Hiti ranṣẹ sí òun, Joabu sì fi ranṣẹ sí Dafidi. Nígbà tí Uraya dé, Dafidi bèèrè alaafia Joabu ati ti gbogbo àwọn ọmọ ogun rẹ̀. Ó bèèrè bí ogun ti ń lọ sí. Lẹ́yìn náà, ó wí fún Uraya pé, “Máa lọ sí ilé rẹ kí o sì sinmi fún ìgbà díẹ̀.” Uraya kúrò lọ́dọ̀ ọba, Dafidi sì di ẹ̀bùn ranṣẹ sí i. Ṣugbọn Uraya kò lọ sí ilé rẹ̀, ó sùn sí ẹnu ọ̀nà ààfin pẹlu àwọn ẹ̀ṣọ́ ọba tí ń ṣọ́ ààfin.
II. Sam 11:3-9 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Dafidi sì ránṣẹ́ ó sì béèrè obìnrin náà. Ẹnìkan sì wí pé, Èyí ha kọ́ ni Batṣeba, ọmọbìnrin Eliamu, aya Uriah ará Hiti. Dafidi sì rán àwọn ìránṣẹ́, ó sì mú un; ó sì wọ inú ilé tọ̀ ọ́ lọ, ó sì bá a dàpọ̀: nígbà tí ó sì wẹ ara rẹ̀ mọ́ tán, ó sì padà lọ sí ilé rẹ̀. Obìnrin náà sì lóyún, ó sì ránṣẹ́ ó sì sọ fún Dafidi, ó sì wí pé, “Èmi ti lóyún.” Dafidi sì ránṣẹ́ sí Joabu, pé: “Rán Uriah ará Hiti sí mi.” Joabu sì rán Uriah sí Dafidi. Nígbà tí Uriah sì dé ọ̀dọ̀ rẹ̀, Dafidi sì bi í léèrè báwo ni Joabu ti ṣe àti àlàáfíà àwọn ènìyàn náà, àti bí ogun náà ti ń ṣe. Dafidi sì wí fún Uriah pé, “Sọ̀kalẹ̀ lọ sí ilé rẹ, kí o sì wẹ ẹsẹ̀ rẹ.” Uriah sì jáde kúrò ní ilé ọba, oúnjẹ láti ọ̀dọ̀ ọba wá sì tọ̀ ọ́ lẹ́yìn. Ṣùgbọ́n Uriah sun ní ẹnu-ọ̀nà ilé ọba lọ́dọ̀ gbogbo ìránṣẹ́ olúwa rẹ̀, kò sì sọ̀kalẹ̀ lọ sí ilé rẹ̀.