II. Sam 11:13-15
II. Sam 11:13-15 Bibeli Mimọ (YBCV)
Dafidi si pè e, o si jẹ, o si mu niwaju rẹ̀; o si mu ki ọti ki o pa a: on si jade li alẹ lọ si ibusùn rẹ̀ lọdọ awọn iranṣẹ oluwa rẹ̀, kò si sọkalẹ lọ si ile rẹ̀. O si ṣe li owurọ Dafidi si kọwe si Joabu, o fi rán Uria. O si kọ sinu iwe pe, Fi Uria siwaju ibi tí ogun gbe le, ki ẹ si bó o silẹ, ki nwọn le kọ lù u, ki o si kú.
II. Sam 11:13-15 Yoruba Bible (YCE)
Dafidi pè é kí ó wá bá òun jẹ oúnjẹ alẹ́ ọjọ́ náà, ó sì fún un ní ọtí mu yó, ṣugbọn Uraya kò lọ sí ilé rẹ̀. Kàkà bẹ́ẹ̀, orí aṣọ òtútù rẹ̀ ni ó sùn, pẹlu àwọn ẹ̀ṣọ́ ninu ilé ìṣọ́ ọba, ní ààfin. Nígbà tí ó di òwúrọ̀ ọjọ́ keji, Dafidi kọ ìwé kan sí Joabu, ó sì fi rán Uraya. Ìwé náà kà báyìí pé, “Fi Uraya sí iwájú ogun, níbi tí ogun ti gbóná girigiri. Lẹ́yìn náà, kí ẹ dẹ̀yìn lẹ́yìn rẹ̀, kí ogun lè pa á.”
II. Sam 11:13-15 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Dafidi sì pè é, ó sì jẹ, ó sì mú nítorí rẹ̀; ó sì mu kí ọtí pa á; òun sì jáde ní alẹ́ lọ sí ibùsùn rẹ̀ lọ́dọ̀ àwọn ìránṣẹ́ olúwa rẹ̀, kò sì sọ̀kalẹ̀ lọ sí ilé rẹ̀. Ó sì ṣe ní òwúrọ̀, Dafidi sì kọ̀wé sí Joabu, ó fi rán Uriah. Ó sì kọ sínú ìwé pé, “Fi Uriah síwájú ibi tí ogun gbé le, kí ẹ sì fàsẹ́yìn, kí wọn lè kọlù ú, kí ó sì kú.”