II. Sam 10:1-19

II. Sam 10:1-19 Bibeli Mimọ (YBCV)

O si ṣe lẹhin eyi, ọba awọn ọmọ Ammoni si kú, Hanuni ọmọ rẹ̀ si jọba ni ipò rẹ̀. Dafidi si wipe, Emi o ṣe ore fun Hanuni ọmọ Nahaṣi gẹgẹ bi baba rẹ̀ si ti ṣe ore fun mi. Dafidi si ranṣẹ lati tù u ninu lati ọwọ́ awọn iranṣẹ rẹ̀ wá, nitori ti baba rẹ̀. Awọn iranṣẹ Dafidi si wá si ilẹ awọn ọmọ Ammoni. Awọn olori awọn ọmọ Ammoni si wi fun Hanuni oluwa wọn pe, Li oju rẹ, ọlá ni Dafidi mbù fun baba rẹ, ti o fi ran awọn olutùnú si ọ? ko ha se pe, Dafidi ran awọn iranṣẹ rẹ̀ si ọ, lati wa wò ilu, ati lati ṣe alami rẹ̀, ati lati bà a jẹ? Hanuni si mu awọn iranṣẹ Dafidi, o fá apakan irungbọ̀n wọn, o si ke abọ̀ kuro ni agbáda wọn, titi o fi de idi wọn, o si rán wọn lọ. Nwọn si sọ fun Dafidi, o si ranṣẹ lọ ipade wọn, nitoriti oju tì awọn ọkunrin na pupọ̀: ọba si wipe. Ẹ duro ni Jeriko titi irungbọ̀n nyin yio fi hù, nigbana ni ki ẹ padà bọ̀. Awọn ọmọ Ammoni si ri pe, nwọn di ẹni irira niwaju Dafidi, awọn ọmọ Ammoni si ranṣẹ, nwọn si fi owo bẹ̀ ogun awọn ara Siria ti Betrehobu; ati Siria ti Soba, ẹgbãwa ẹlẹsẹ ati ti ọba Maaka, ẹgbẹrun ọkunrin, ati ti Iṣtobu ẹgbãfa ọkunrin. Dafidi si gbọ́, o si rán Joabu, ati gbogbo ogun awọn ọkunrin alagbara. Awọn ọmọ Ammoni si jade, nwọn si tẹ́ ogun li ẹnu odi; ara Siria ti Soba, ati ti Rehobu, ati Iṣtobu, ati Maaka, nwọn si tẹ́ ogun ni papa fun ara wọn. Nigbati Joabu si ri i pe ogun na doju kọ on niwaju ati lẹhin, o si yàn ninu gbogbo awọn akikanju ọkunrin ni Israeli, o si tẹ́ ogun kọju si awọn ara Siria. O si fi awọn enia ti o kù le Abiṣai aburo rẹ̀ lọwọ, ki o le tẹ́ ogun kọju si awọn ọmọ Ammoni. O si wipe, Bi agbara awọn ara Siria ba si pọ̀ jù emi lọ, iwọ o si wá ràn mi lọwọ: ṣugbọn bi ọwọ́ awọn ọmọ Ammoni ba si pọ̀ jù ọ lọ, emi o si wá ràn ọ lọwọ. Mu ọkàn le, jẹ ki a ṣe onigboya nitori awọn enia wa, ati nitori awọn ilu Ọlọrun wa; Oluwa o si ṣe eyi ti o dara li oju rẹ̀. Joabu ati awọn enia ti mbẹ lọdọ rẹ̀ si ba awọn ara Siria pade ijà: nwọn si sa niwaju rẹ̀. Nigbati awọn ọmọ Ammoni si ri pe awọn ara Siria sá, awọn si sá niwaju Abiṣai, nwọn si wọ inu ilu lọ. Joabu si pada kuro lẹhin awọn ọmọ Ammoni, o si pada wá si Jerusalemu. Nigbati awọn ara Siria si ri pe nwọn di bibì ṣubu niwaju Israeli, nwọn si ko ara wọn jọ. Hadareseri si ranṣẹ, o si mu awọn ara Siria ti o wà li oke odo jade wá: nwọn si wá si Helami; Ṣobaki olori ogun ti Hadareseri si ṣolori wọn. Nigbati a sọ fun Dafidi, o si ko gbogbo Israeli jọ, nwọn si kọja Jordani, nwọn si wá si Helami. Awọn ara Siria si tẹ́ ogun kọju si Dafidi, nwọn si ba a jà. Awọn ara Siria si sa niwaju Israeli; Dafidi si pa ninu awọn ara Siria ẽdẹgbẹrin awọn onikẹkẹ́, ati ọkẹ meji ẹlẹṣin, nwọn si kọlu Ṣobaki olori ogun wọn, o si kú nibẹ. Nigbati gbogbo awọn ọba ti o wà labẹ Hadareseri si ri pe nwọn di bibì ṣubu niwaju Israeli, nwọn si ba Israeli lajà, nwọn si nsìn wọn. Awọn ara Siria si bẹ̀ru lati ràn awọn ọmọ Ammoni lọwọ mọ.

II. Sam 10:1-19 Yoruba Bible (YCE)

Lẹ́yìn èyí, ni Nahaṣi, ọba Amoni kú, Hanuni, ọmọ rẹ̀ sì gorí oyè. Dafidi ọba wí pé, “N óo ṣe ẹ̀tọ́ fún Hanuni, ọmọ Nahaṣi gẹ́gẹ́ bí baba rẹ̀ ti ṣe ẹ̀tọ́ fún mi.” Dafidi bá rán oníṣẹ́ lọ sọ́dọ̀ rẹ̀ láti tù ú ninu, nítorí ikú baba rẹ̀. Nígbà tí àwọn oníṣẹ́ Dafidi dé Amoni, àwọn àgbààgbà ìlú náà wí fún Hanuni ọba wọn pé, “Ṣé o rò pé baba rẹ ni Dafidi bu ọlá fún tóbẹ́ẹ̀, tí ó fi rán àwọn oníṣẹ́ láti wá tù ọ́ ninu? Rárá o! Amí ni ó rán wọn wá ṣe, kí wọ́n lè wo gbogbo ìlú wò, kí ó baà lè ṣẹgun wa.” Hanuni bá ki àwọn oníṣẹ́ Dafidi mọ́lẹ̀, ó fá apá kan irùngbọ̀n ẹnìkọ̀ọ̀kan wọn, ó gé aṣọ wọn ní déédé ìbàdí, ó sì tì wọ́n jáde. Ìtìjú bá wọn tóbẹ́ẹ̀ gẹ́ẹ́ tí wọn kò lè pada sílé. Nígbà tí Dafidi gbọ́ ohun tí ó ṣẹlẹ̀ sí wọn, ó ranṣẹ sí wọn pé kí wọ́n dúró ní Jẹriko títí tí irùngbọ̀n wọn yóo fi hù, kí wọ́n tó máa pada bọ̀. Nígbà tí àwọn ará Amoni rí i pé àwọn ti di ọ̀tá Dafidi, wọ́n ranṣẹ lọ fi owó gba ọ̀kẹ́ kan (20,000) jagunjagun ninu àwọn ará Siria tí wọ́n ń gbé Betirehobu ati Soba. Wọ́n gba ẹgbẹrun (1,000) lọ́dọ̀ ọba Maaka ati ẹgbaafa (12,000) ninu àwọn ará Tobu. Nígbà tí Dafidi gbọ́, ó rán Joabu ati gbogbo àwọn ọmọ ogun rẹ̀, láti lọ gbógun tì wọ́n. Àwọn ará Amoni jáde sí àwọn ọmọ ogun Israẹli, wọ́n tò sí ẹnubodè wọn ní Raba, tíí ṣe olú ìlú wọn. Gbogbo àwọn ọmọ ogun, ará Siria tí wọ́n wá láti Soba ati Rehobu, ati àwọn ará Tobu ati ti Maaka, àwọn dá dúró ninu pápá. Nígbà tí Joabu rí i pé àwọn ọ̀tá yóo gbógun ti àwọn níwájú ati lẹ́yìn, ó yan àwọn tí wọ́n jẹ́ akikanju jùlọ ninu àwọn ọmọ ogun Israẹli, ó ní kí wọ́n dojú kọ àwọn ará Siria. Ó sì kó gbogbo àwọn ọmọ ogun rẹ̀ yòókù sábẹ́ ọ̀gágun Abiṣai, tí ó jẹ́ arakunrin rẹ̀, Abiṣai bá fi olukuluku sí ipò rẹ̀, wọ́n dojú kọ àwọn ará Amoni. Joabu wí fún un pé, “Bí o bá rí i pé àwọn ará Siria fẹ́ ṣẹgun mi, wá ràn mí lọ́wọ́. Bí èmi náà bá sì rí i pé àwọn ará Amoni fẹ́ ṣẹgun rẹ, n óo wá ràn ọ́ lọ́wọ́. Múra gírí, jẹ́ kí á fi gbogbo agbára wa jà fún àwọn eniyan wa ati fún ìlú Ọlọrun wa. Kí OLUWA wa ṣe èyí tí ó dára lójú rẹ̀.” Joabu ati àwọn ọmọ ogun rẹ̀ tẹ̀síwájú láti gbógun ti àwọn ará Siria, àwọn ará Siria sì sá. Nígbà tí àwọn ará Amoni rí i pé àwọn ará Siria ń sá lọ, àwọn náà sá fún Abiṣai, wọ́n sì pada sinu ìlú. Joabu bá pada lẹ́yìn àwọn ará Amoni, ó sì lọ sí Jerusalẹmu. Nígbà tí àwọn ará Siria rí i pé, àwọn ọmọ ogun Israẹli ti ṣẹgun àwọn, wọ́n kó gbogbo àwọn ọmọ ogun wọn jọ. Hadadeseri ọba, bá ranṣẹ sí àwọn ará Siria tí wọ́n wà ní ìhà ìlà oòrùn odò Yufurate, wọ́n bá wá sí Helamu. Ṣobaki tí ó jẹ́ balogun àwọn ọmọ ogun Hadadeseri, ni aṣiwaju wọn. Nígbà tí Dafidi gbọ́, ó kó gbogbo àwọn ọmọ ogun Israẹli jọ, ó la odò Jọdani kọjá lọ sí Helamu. Olukuluku àwọn ará Siria dúró ní ipò wọn, wọ́n dojú kọ Dafidi, wọ́n sì bá a jagun. Àwọn ọmọ ogun Israẹli lé àwọn ọmọ ogun Siria pada, Dafidi ati àwọn eniyan rẹ̀ pa ẹẹdẹgbẹrin (700) ninu àwọn tí wọ́n gun kẹ̀kẹ́ ogun Siria, ati ọ̀kẹ́ meji (40,000) ninu àwọn ẹlẹ́ṣin wọn. Wọ́n ṣá Ṣobaki tí ó jẹ́ balogun wọn lọ́gbẹ́, ó sì kú sójú ogun. Nígbà tí àwọn ọba tí wọ́n wà lẹ́yìn Hadadeseri rí i pé, àwọn ọmọ Israẹli ti ṣẹgun àwọn, wọ́n bá Israẹli làjà, wọ́n sì ń sìn wọ́n. Láti ìgbà náà ni ẹ̀rù sì ti ń ba àwọn ará Siria láti ran àwọn ará Amoni lọ́wọ́.

II. Sam 10:1-19 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)

Ó sì ṣe lẹ́yìn èyí, ọba àwọn ará Ammoni sì kú, Hanuni ọmọ rẹ̀ sì jẹ ọba ní ipò rẹ̀. Dafidi sì wí pé, “Èmi yóò ṣe oore fún Hanuni ọmọ Nahaṣi gẹ́gẹ́ bí baba rẹ̀ sì ti ṣe oore fún mi.” Dafidi sì ránṣẹ́ láti tù Hanuni nínú láti ọwọ́ àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ wá, nítorí ti baba rẹ̀. Àwọn ìránṣẹ́ Dafidi sì wá sí ilé àwọn ọmọ Ammoni. Àwọn olórí àwọn ọmọ Ammoni sì wí fún Hanuni olúwa wọn pé, “Ǹjẹ́ o rò pé Dafidi ń bu ọlá fún baba rẹ nígbà tí ó rán ènìyàn wá láti bá ọ kẹ́dùn? Kò ha ṣe pé Dafidi rán àwọn ìránṣẹ́ sí ọ láti wo ìlú àti láti yọ́ ọ wò àti láti gbà ọ́.” Hanuni sì mú àwọn ìránṣẹ́ Dafidi ó fá apá kan irùngbọ̀n wọn, ó sì gé ààbọ̀ kúrò ní agbádá wọn, títí ó fi dé ìdí wọn, ó sì rán wọn lọ. Wọ́n sì sọ fún Dafidi, ó sì ránṣẹ́ lọ pàdé wọn, nítorí tí ojú ti àwọn ọkùnrin náà púpọ̀: ọba sì wí pé, “Ẹ dúró ní Jeriko títí irùngbọ̀n yín yóò fi hù, nígbà náà ni kí ẹ tó máa bọ̀.” Àwọn ará Ammoni sì ri pé, wọ́n di ẹni ìríra níwájú Dafidi, àwọn ọmọ Ammoni sì ránṣẹ́, wọ́n sì fi owó bẹ́ ogún àwọn ará Siria ti Beti-Rehobu; àti Siria-Soba, ẹgbàáwàá ẹlẹ́ṣẹ̀ àti ti ọba Maaka, ẹgbẹ̀rún ọkùnrin àti ti Tobu ẹgbàafà ọkùnrin lọ́wẹ̀. Dafidi sì gbọ́, ó sì rán Joabu, àti gbogbo ogún àwọn ọkùnrin alágbára. Àwọn ọmọ Ammoni sì jáde wá, wọ́n sì tẹ́ ogun ní ẹnu odi; ará Siria-Soba, àti ti Rehobu, àti Tobu, àti Maaka, wọ́n sì tẹ ogun ni pápá fún ara wọn. Nígbà tí Joabu sì rí i pé ogun náà dojúkọ òun níwájú àti lẹ́yìn, ó sì yàn nínú gbogbo àwọn akíkanjú ọkùnrin ní Israẹli, ó sì tẹ́ ogun kọjú sí àwọn ará Siria. Ó sì fi àwọn ènìyàn tí ó kù lé Abiṣai àbúrò rẹ̀ lọ́wọ́, kí ó lè tẹ ogun kọjú sí àwọn ọmọ Ammoni. Ó sì wí pé, “Bí agbára àwọn ará Siria bá pọ̀ ju èmi lọ, ìwọ yóò sì wá ràn mí lọ́wọ́: ṣùgbọ́n bí ọwọ́ àwọn ọmọ Ammoni bá sì pọ̀jù ọ́ lọ, èmi ó sì wá ràn ọ́ lọ́wọ́. Mú ọkàn lè, jẹ́ kí a ṣe onígboyà nítorí àwọn ènìyàn wa, àti nítorí àwọn ìlú Ọlọ́run wa; OLúWA yóò sì ṣe èyí tí ó dára lójú rẹ̀.” Joabu àti àwọn ènìyàn tí ń bẹ lọ́dọ̀ rẹ̀ sì bá àwọn ará Siria pàdé ìjà: wọ́n sì sá níwájú rẹ̀. Nígbà tí àwọn ọmọ Ammoni sì rí i pé àwọn ará Siria sá, àwọn pẹ̀lú sì sá níwájú Abiṣai, wọ́n sì wọ inú ìlú lọ. Joabu sì padà kúrò lẹ́yìn àwọn ọmọ Ammoni, ó sì wá sí Jerusalẹmu. Nígbà tí àwọn ará Siria sì rí i pé Àwọn ṣubú níwájú Israẹli: wọ́n sì kó ara wọn jọ Hadadeseri sì ránṣẹ́, ó sì mú àwọn Siria tí ó wà ní òkè odò Eufurate jáde wá: wọ́n sì wá sí Helami; Sobaki olórí ogun Hadadeseri sì ṣe olórí wọn. Nígbà tí a sọ fún Dafidi, ó sì kó gbogbo Israẹli jọ, wọ́n sì kọjá Jordani, wọ́n sì wá sí Helami, Àwọn ará Siria sì tẹ́ ogun kọjú sí Dafidi, wọ́n sì bá a jà. Àwọn ará Siria sì sá níwájú Israẹli, Dafidi sì pa nínú àwọn ará Siria ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀rin àwọn oníkẹ̀kẹ́, àti ọ̀kẹ́ méjì ẹlẹ́ṣin, wọ́n sì kọlu Sobaki olórí ogun wọn, ó sì kú níbẹ̀. Nígbà tí gbogbo àwọn ọba tí ó wà lábẹ́ Hadadeseri sì rí i pé wọ́n di bíbì ṣubú níwájú Israẹli, wọ́n sì bá Israẹli làjà, wọ́n sì ń sìn wọ́n. Àwọn ará Siria sì bẹ̀rù láti máa ran àwọn ọmọ Ammoni lọ́wọ́ mọ́.