II. Sam 1:1-16
II. Sam 1:1-16 Bibeli Mimọ (YBCV)
O si ṣe lẹhin ikú Saulu, Dafidi si ti ibi iparun awọn ara Amaleki bọ̀, Dafidi si joko nijọ meji ni Siklagi; O si ṣe ni ijọ kẹta, si wõ, ọkunrin kan si ti ibudo wá lati ọdọ Saulu; aṣọ rẹ̀ si faya, erupẹ si mbẹ li ori rẹ̀: o si ṣe, nigbati on si de ọdọ Dafidi, o wolẹ, o si tẹriba. Dafidi si bi i lere pe, Nibo ni iwọ ti wá? o si wi fun u pe, Lati ibudo Israeli li emi ti sa wá. Dafidi si tun bi lere wipe, Ọràn na ti ri? emi bẹ ọ, sọ fun mi. On si dahun pe, Awọn enia na sa loju ijà, ọ̀pọlọpọ ninu awọn enia na pẹlu si ṣubu; nwọn si kú, Saulu ati Jonatani ọmọ rẹ̀ si kú pẹlu. Dafidi si bi ọmọdekunrin na ti o sọ fun u lere pe, Iwọ ti ṣe mọ̀ pe, Saulu ati Jonatani ọmọ rẹ̀ kú? Ọmọdekunrin na ti o sọ fun u wipe, Bi emi ti ṣe alabapade lori oke Gilboa, si wõ, Saulu fi ara tì ọkọ̀ rẹ̀, si wõ, kẹkẹ́ ati ẹlẹṣin nlepa rẹ̀ kikan. Nigbati o si yi oju wo ẹhin rẹ̀, ti o si ri mi, o pè mi, Emi si da a lohùn pe, Emi nĩ. On si bi mi pe, Iwọ tani? Emi si da a lohùn pe, ara Amaleki li emi. On si tun wi fun mi pe, Duro le mi, emi bẹ ọ ki o si pa mi: nitoriti wahala ba mi, ẹmi mi si wà sibẹ. Emi si duro le e, mo si pa a, nitori ti o da mi loju pe, kò si tun le là mọ lẹhin igbati o ti ṣubu: emi si mu ade ti o wà li ori rẹ̀, ati ibọwọ ti o mbẹ li apa rẹ̀, emi si mu wọn wá ihinyi sọdọ oluwa mi. Dafidi si di aṣọ rẹ̀ mu, o si fà wọn ya, gbogbo awọn ọkunrin ti o wà lọdọ rẹ̀ si ṣe bẹ̃ gẹgẹ. Nwọn si ṣọfọ, nwọn si sọkun, nwọn si gbawẹ titi di aṣalẹ fun Saulu, ati fun Jonatani ọmọ rẹ̀, ati fun awọn enia Oluwa, ati fun ile Israeli; nitoripe nwọn ti ipa idà ṣubu. Dafidi si bi ọmọdekunrin na ti o rò fun u wipe, Nibo ni iwọ ti wá? On si da a li ohùn pe, Ọmọ alejo kan, ara Amaleki li emi iṣe. Dafidi si wi fun u pe, E ti ri ti iwọ kò fi bẹ̀ru lati nà ọwọ́ rẹ lati fi pa ẹni-àmi-ororo Oluwa? Dafidi si pe ọkan ninu awọn ọmọdekunrin, o si wipe, Sunmọ ọ, ki o si kọ lu u. O si kọ lu u, on si kú. Dafidi si wi fun u pe Ẹjẹ rẹ mbẹ li ori ara rẹ; nitoripe ẹnu rẹ li o fi jẹwọ pe, Emi li o pa ẹni-àmi-ororo Oluwa.
II. Sam 1:1-16 Yoruba Bible (YCE)
Lẹ́yìn ikú Saulu, nígbà tí Dafidi pada dé láti ojú ogun, níbi tí ó ti ṣẹgun àwọn ará Amaleki, ó dúró ní ìlú Sikilagi fún ọjọ́ meji. Ní ọjọ́ kẹta, ọdọmọkunrin kan wá, láti inú àgọ́ Saulu, ó ti fa aṣọ rẹ̀ ya, ó sì ku erùpẹ̀ sí orí, láti fi ìbànújẹ́ hàn. Nígbà tí ó dé ọ̀dọ̀ Dafidi, ó wólẹ̀, ó dojúbolẹ̀ níwájú rẹ̀, ó sì kí i tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀. Dafidi bèèrè lọ́wọ́ rẹ̀ pé, “Níbo ni o ti ń bọ̀?” Ọdọmọkunrin náà dáhùn pé, “Láti inú àgọ́ àwọn ọmọ Israẹli ni mo ti sá àsálà.” Dafidi wí fún un pé, “Sọ ohun tí ó ṣẹlẹ̀ fún mi.” Ọdọmọkunrin náà dáhùn pé, “Sísá ni àwọn ọmọ ogun Israẹli sá kúrò lójú ogun, ọpọlọpọ ninu wọn ni wọ́n sì ti pa; wọ́n ti pa Saulu ati Jonatani ọmọ rẹ̀ pẹlu.” Dafidi tún bèèrè lọ́wọ́ rẹ̀ pé, “Báwo ni o ṣe mọ̀ pé Saulu ati Jonatani ọmọ rẹ̀ ti kú?” Ọdọmọkunrin náà dá a lóhùn pé, “Orí òkè Giliboa ni mo wà, ni mo déédé rí Saulu tí ó fara ti ọ̀kọ̀ rẹ̀. Mo sì rí i tí kẹ̀kẹ́ ogun àwọn ọ̀tá ati àwọn ẹlẹ́ṣin wọn ń lépa rẹ̀. Bí ó ti bojú wẹ̀yìn, tí ó rí mi, ó pè mí. Mo sì dá a lóhùn pé, ‘Èmi nìyí.’ Ó bi mí pé, ta ni mí; mo dá a lóhùn pé, ‘Ọ̀kan ninu àwọn ará Amaleki ni mí.’ Saulu bá wí fún mi pé, ‘Sún mọ́ mi níhìn-ín, kí o pa mí, nítorí pé mo ti fara gbọgbẹ́, mò ń jẹ̀rora gidigidi, ṣugbọn ẹ̀mí mi ṣì wà sibẹ.’ Mo bá súnmọ́ Saulu, mo sì pa á. Nítorí mo mọ̀ pé, tí ó bá kúkú ṣubú lulẹ̀, yóo kú náà ni. Mo bá ṣí adé orí rẹ̀, mo sì bọ́ ẹ̀gbà ọrùn ọwọ́ rẹ̀. Àwọn ni mo kó wá fún ọ yìí, Dafidi, oluwa mi.” Ni Dafidi ati gbogbo àwọn tí wọ́n wà pẹlu rẹ̀ bá fa aṣọ wọn ya láti fi ìbànújẹ́ wọn hàn. Wọ́n ṣọ̀fọ̀, wọ́n sọkún, wọ́n sì gbààwẹ̀ títí di ìrọ̀lẹ́; nítorí Saulu ati Jonatani, ọmọ rẹ̀, ati àwọn ọmọ Israẹli, eniyan OLUWA nítorí pé ọpọlọpọ wọn ni wọ́n ti pa lójú ogun. Dafidi bèèrè lọ́wọ́ ọdọmọkunrin tí ó wá ròyìn fún un pé, “Níbo ni o ti wá?” Ọdọmọkunrin náà dáhùn pé, “Ọmọ àlejò ará Amaleki kan, tí ń gbé ilẹ̀ Israẹli ni mí.” Dafidi tún bi í pé, “Báwo ni ẹ̀rù kò ṣe bà ọ́ láti pa ọba, ẹni tí OLUWA fi àmì òróró yàn?” Ni Dafidi bá pàṣẹ pé kí ọ̀kan ninu àwọn ọkunrin tí wọ́n wà lọ́dọ̀ rẹ̀, lọ pa ọdọmọkunrin ará Amaleki náà. Ọkunrin náà bá pa á. Dafidi wí fún ọdọmọkunrin ará Amaleki náà pé, “Ìwọ ni o fa èyí sí orí ara rẹ. Ìwọ ni o dá ara rẹ lẹ́bi, nípa jíjẹ́wọ́ pé, ìwọ ni o pa ọba, ẹni tí OLUWA fi àmì òróró yàn.”
II. Sam 1:1-16 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Lẹ́yìn ikú Saulu, Dafidi ti ibi tí ó ti ṣẹ́gun àwọn ará Amaleki bọ̀, ó sì dúró ní Siklagi ní ọjọ́ méjì. Ní ọjọ́ kẹta, ọkùnrin kan dé láti ibi ibùdó Saulu, pẹ̀lú aṣọ rẹ̀ tí ó ti ya; àti erùpẹ̀ ní orí rẹ̀. Nígbà tí ó dé ọ̀dọ̀ Dafidi, ó wólẹ̀ fún un láti bu ọlá fún un. Dafidi sì béèrè pé, “Ibo ni ìwọ ti wá?” “Èmi sá láti ibùdó àwọn ọmọ Israẹli.” Dafidi béèrè pé, “Kí ni ó ṣẹlẹ̀?” “Sọ fún mi.” Ó wí pé, “Àwọn ọkùnrin náà sá láti ojú ogun. Ọ̀pọ̀ wọn ṣubú, wọ́n sì kú. Saulu àti ọmọ rẹ̀ ọkùnrin Jonatani sì kú pẹ̀lú.” Nígbà náà, ní Dafidi sọ fún ọ̀dọ́mọkùnrin tí ó mú ìròyìn wá fún un pé, “Báwo ni o ṣe mọ̀ pé Saulu àti ọmọkùnrin rẹ̀ Jonatani ti kú.” Ọ̀dọ́mọkùnrin náà sọ pé, “mo wà ní orí òkè Gilboa níbẹ̀ ni Saulu fi ara tí ọkọ̀ rẹ̀, àwọn kẹ̀kẹ́ àti ẹlẹ́ṣin sì ń lépa rẹ̀. Nígbà tí ó wò yíká, tí ó rí mí, ó pè mi, mo sì wí pé, ‘Kí ni mo lè ṣe?’ “Ó bi mí wí pé, ‘Ta ni ìwọ?’ “Mo dáhùn pé, ‘Ará a Amaleki.’ “Nígbà náà ó wí fún mi pé, ‘Dúró lórí ì mi kí o sì pa mí! Èmi wà nínú ìrora ikú, ṣùgbọ́n mo wà láààyè.’ “Nígbà náà, mo dúró lórí i rẹ̀, mo sì pa á nítorí mo mọ̀ wí pé, lẹ́yìn ìgbà tí ó ti ṣubú, kò le è yè mọ́. Mo sì mú adé tí ó wà lórí rẹ̀, idẹ tí ó wà ní apá a rẹ̀, mo sì kó wọn wá síbí fún olúwa mi.” Nígbà náà ni, Dafidi àti gbogbo àwọn tí ó wà pẹ̀lú rẹ̀, di aṣọ wọn mú, wọ́n sì fà á ya. Wọ́n ṣọ̀fọ̀, wọ́n sì sọkún, wọ́n sì gbààwẹ̀ títí di ìrọ̀lẹ́ fún Saulu àti ọmọ rẹ̀ Jonatani àti fún àwọn ọmọ-ogun OLúWA, àti fún àwọn ilé Israẹli, nítorí wọ́n ti ṣubú nípa idà. Dafidi sọ fún ọkùnrin tí ó mú ìròyìn wá fún un pé, “Níbo ni ó ti wá?” O dáhùn pé, “Ọmọ àlejò ni mo jẹ́, ará Amaleki.” Dafidi béèrè lọ́wọ́ rẹ̀ pé, “Kí ni ó dé tí ìwọ kò fi bẹ̀rù láti gbé ọwọ́ rẹ̀ sókè láti fi pa ẹni ààmì òróró OLúWA?” Nígbà náà Dafidi pe ọ̀kan nínú ọkùnrin, ó sì wí pé, “Lọ, gbé e lulẹ̀!” Nígbà náà ó gbé e lulẹ̀, ó sì kú. Nítorí Dafidi wí fún un pé, “Ẹ̀jẹ̀ rẹ yóò wà lórí ara rẹ, nítorí ẹnu ara rẹ ni o fi sọ pé ‘Mo pa ẹni ààmì òróró OLúWA.’ ”