II. Pet 3:1-7
II. Pet 3:1-7 Bibeli Mimọ (YBCV)
OLUFẸ, eyi ni iwe keji ti mo nkọ si nyin; ninu mejeji na li emi nrú inu funfun nyin soke nipa riran nyin leti: Ki ẹnyin ki o le mã ranti ọ̀rọ ti a ti ẹnu awọn woli mimọ́ sọ ṣaju, ati ofin Oluwa ati Olugbala wa lati ọdọ awọn aposteli nyin: Ki ẹ kọ́ mọ̀ eyi pe, nigba ọjọ ikẹhin, awọn ẹlẹgan yio de pẹlu ẹgan wọn, nwọn o mã rin nipa ifẹ ara wọn, Nwọn o si mã wipe, Nibo ni ileri wíwa rẹ̀ gbé wà? lati igbati awọn baba ti sùn, ohun gbogbo nlọ bi nwọn ti wà rí lati ìgba ọjọ ìwa. Nitori eyi ni nwọn mọ̃mọ ṣe aifẹ̃mọ, pe nipa ọ̀rọ Ọlọrun li awọn ọrun ti wà lati ìgba atijọ, ati ti ilẹ yọri jade ninu omi, ti o si duro ninu omi: Nipa eyi ti omi bo aiye ti o wà nigbana, ti o si ṣegbe: Ṣugbọn awọn ọrun ati aiye, ti mbẹ nisisiyi, nipa ọ̀rọ kanna li a ti tojọ bi iṣura fun iná, a pa wọn mọ́ dè ọjọ idajọ ati iparun awọn alaiwa-bi-Ọlọrun.
II. Pet 3:1-7 Yoruba Bible (YCE)
Ẹ̀yin àyànfẹ́ mi, èyí ni ìwé keji tí mo kọ si yín. Ninu ìwé mejeeji, mò ń ji yín pẹ́pẹ́, láti ran yín létí àwọn ohun tí ẹ mọ̀, kí ẹ lè fi ọkàn tòótọ́ rò wọ́n jinlẹ̀. Ẹ ranti àwọn ọ̀rọ̀ tí àwọn wolii ti sọ ati òfin Oluwa wa ati Olùgbàlà tí ẹ gbà lọ́wọ́ aposteli yín. Ní àkọ́kọ́, kí ẹ mọ èyí pé ní ọjọ́ ìkẹyìn, àwọn tí wọn óo máa fi ẹ̀sìn ṣe ẹlẹ́yà yóo wá, tí wọn óo máa ṣe ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ara wọn. Wọn óo máa sọ pé, “Kí ni ó ṣẹlẹ̀ sí ìlérí pé Jesu tún ń pada bọ̀? Nítorí láti ìgbà tí àwọn baba wa ninu igbagbọ ti lọ tán, bákan náà ni gbogbo nǹkan rí láti ìṣẹ̀dálẹ̀ ayé!” Nítorí wọ́n fi ojú fo èyí dá pé, láti ìgbà àtijọ́ ni àwọn ọ̀run ti wà, ati pé láti inú omi ni ilẹ̀ ti jáde nípa àṣẹ Ọlọrun. Omi kan náà ni Ọlọrun fi pa ayé tí ó ti wà rí run. Ṣugbọn àṣẹ kan náà ni Ọlọrun fi pa àwọn ọ̀run ati ayé ti àkókò yìí mọ́ kí ó lè dáná sun ún, ó ń fi wọ́n pamọ́ títí di ọjọ́ ìdájọ́ nígbà tí a óo pa àwọn eniyan tí kò bẹ̀rù Ọlọrun run.
II. Pet 3:1-7 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Olùfẹ́, èyí ni ìwé kejì tí mo ń kọ sí yín, nínú méjèèjì náà ni èmi ń ru èrò inú yín sókè nípa rírán yín létí; kí ẹ̀yin lè máa rántí ọ̀rọ̀ tí a ti ẹnu àwọn wòlíì mímọ́ sọ ṣáájú, àti òfin Olúwa àti Olùgbàlà wa láti ọ̀dọ̀ àwọn aposteli yín. Kí ẹ kọ́ mọ èyí pé, nígbà ọjọ́ ìkẹyìn, àwọn ẹlẹ́gàn yóò dé pẹ̀lú ẹ̀gàn wọn. Wọn ó máa rìn nípa ìfẹ́ ara wọn. Wọn ó sì máa wí pé, “Níbo ni ìlérí wíwà rẹ̀ gbé wà? Láti ìgbà tí àwọn baba ti sùn, ohun gbogbo ń lọ bí wọ́n ti wà rí láti ìgbà ọjọ́ yìí wá.” Nítorí èyí ni wọ́n mọ̀ ọ́n mọ̀ ṣe àìfẹ́ ẹ́ mọ̀ pé nípa ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ni àwọn ọ̀run ti wà láti ìgbà àtijọ́ àti tí ilẹ̀ yọrí jáde nínú omi, tí ó sì dúró nínú omi. Nípa èyí tí omi bo ayé tí ó wà nígbà náà tí ó sì ṣègbé. Ṣùgbọ́n àwọn ọ̀run àti ayé, tí ó ń bẹ nísinsin yìí, nípa ọ̀rọ̀ kan náà ni ó ti tò jọ bí ìṣúra fún iná, a pa wọ́n mọ́ de ọjọ́ ìdájọ́ àti ìparun àwọn aláìwà-bí-Ọlọ́run.