II. Pet 2:5-7
II. Pet 2:5-7 Bibeli Mimọ (YBCV)
Ti kò si dá aiye igbãni si, ṣugbọn o pa Noa pẹlu awọn meje miran mọ́, oniwasu ododo, nigbati o mu kikun omi wá sori aiye awọn alaiwà-bi-Ọlọrun; Ti o sọ awọn ilu Sodomu on Gomorra di ẽru, nigbati o fi ifọ́ afọbajẹ dá wọn lẹbi, ti o fi wọn ṣe apẹrẹ fun awọn ti yio jẹ alaiwà-bi-Ọlọrun; O si yọ Loti olõtọ, ẹniti ìwa wọbia awọn enia buburu bà ninu jẹ
II. Pet 2:5-7 Yoruba Bible (YCE)
Bẹ́ẹ̀ ni Ọlọrun kò dáríjì àwọn ará àtijọ́, nígbà tí ó fi ìkún omi pa ayé run pẹlu àwọn tí wọn kò bẹ̀rù rẹ̀, àfi Noa, ọ̀kan ninu àwọn mẹjọ, tí ń waasu òdodo, ni ó gbà là. Bẹ́ẹ̀ tún ni ìlú Sodomu ati Gomora tí ó dá lẹ́bi, tí ó sì dáná sun. Èyí jẹ́ àpẹẹrẹ ohun tí ń bọ̀ wá ṣẹlẹ̀ sí àwọn tí kò bẹ̀rù Ọlọrun. Ṣugbọn ó yọ Lọti tí ó jẹ́ olódodo eniyan, tí ọkàn rẹ̀ bàjẹ́ nítorí ìwàkiwà àwọn tí ń ṣe ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ara wọn.
II. Pet 2:5-7 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Bí òun kò si dá ayé ìgbàanì sí, nígbà tí ó mú ìkún omi wá sórí ayé àwọn aláìwà-bí-Ọlọ́run, ṣùgbọ́n ó pa Noa mọ́, oníwàásù òdodo, pẹ̀lú àwọn ọmọ méje mìíràn. Tí ó sọ àwọn ìlú Sodomu àti Gomorra di eérú, nígbà tí ó fi ìparun pátápátá dá wọn lẹ́bi, tí ó fi wọ́n ṣe àpẹẹrẹ fún àwọn tí yóò jẹ́ aláìwà-bí-Ọlọ́run. Tí ó sì yọ Lọti olóòtítọ́ ènìyàn, ẹni tí ìwà ẹ̀gbin àwọn ènìyàn láìlófin bà nínú jẹ́