II. Pet 2:4-9
II. Pet 2:4-9 Bibeli Mimọ (YBCV)
Nitoripe bi Ọlọrun kò ba dá awọn angẹli si ti nwọn ṣẹ, ṣugbọn ti o sọ wọn si isalẹ ọrun apadi, ti o si fi wọn sinu ọgbun òkunkun biribiri awọn ti a pamọ́ de idajọ; Ti kò si dá aiye igbãni si, ṣugbọn o pa Noa pẹlu awọn meje miran mọ́, oniwasu ododo, nigbati o mu kikun omi wá sori aiye awọn alaiwà-bi-Ọlọrun; Ti o sọ awọn ilu Sodomu on Gomorra di ẽru, nigbati o fi ifọ́ afọbajẹ dá wọn lẹbi, ti o fi wọn ṣe apẹrẹ fun awọn ti yio jẹ alaiwà-bi-Ọlọrun; O si yọ Loti olõtọ, ẹniti ìwa wọbia awọn enia buburu bà ninu jẹ: (Nitori ọkunrin olõtọ nì bi o ti ngbe ãrin wọn, ti o nri, ti o si ngbọ́, lojojumọ ni ìwa buburu wọn mba ọkàn otitọ rẹ̀ jẹ́): Oluwa mọ̀ bi ã ti íyọ awọn ẹni ìwa-bi-Ọlọrun kuro ninu idanwo ati bi ã ti ípa awọn alaiṣõtọ ti a njẹ niya mọ dè ọjọ idajọ
II. Pet 2:4-9 Yoruba Bible (YCE)
Nítorí Ọlọrun kò dáríjì àwọn angẹli tí ó ṣẹ̀ ẹ́, ṣugbọn ó jù wọ́n sinu ọ̀gbun tí ó ṣókùnkùn biribiri ní ọ̀run àpáàdì títí di ọjọ́ ìdájọ́. Bẹ́ẹ̀ ni Ọlọrun kò dáríjì àwọn ará àtijọ́, nígbà tí ó fi ìkún omi pa ayé run pẹlu àwọn tí wọn kò bẹ̀rù rẹ̀, àfi Noa, ọ̀kan ninu àwọn mẹjọ, tí ń waasu òdodo, ni ó gbà là. Bẹ́ẹ̀ tún ni ìlú Sodomu ati Gomora tí ó dá lẹ́bi, tí ó sì dáná sun. Èyí jẹ́ àpẹẹrẹ ohun tí ń bọ̀ wá ṣẹlẹ̀ sí àwọn tí kò bẹ̀rù Ọlọrun. Ṣugbọn ó yọ Lọti tí ó jẹ́ olódodo eniyan, tí ọkàn rẹ̀ bàjẹ́ nítorí ìwàkiwà àwọn tí ń ṣe ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ara wọn. Nítorí ohun tí ojú rẹ̀ ń rí ati ohun tí etí rẹ̀ ń gbọ́ ń ba ọkàn ọkunrin olódodo yìí jẹ́ lojoojumọ bí ó ti ń gbé ààrin àwọn eniyan burúkú yìí. Oluwa mọ ọ̀nà láti yọ àwọn olùfọkànsìn kúrò ninu ìdánwò, ṣugbọn ó pa àwọn alaiṣododo mọ́ de ìyà Ọjọ́ Ìdájọ́.
II. Pet 2:4-9 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Nítorí pé bi Ọlọ́run kò bá dá àwọn angẹli si nígbà tí wọn ṣẹ̀, ṣùgbọ́n ti ó sọ wọ́n sí ìsàlẹ̀ ọ̀run àpáàdì tí ó sì fi wọ́n sínú ọ̀gbun òkùnkùn biribiri nínú ìfipamọ́ títí dé ìdájọ́. Bí òun kò si dá ayé ìgbàanì sí, nígbà tí ó mú ìkún omi wá sórí ayé àwọn aláìwà-bí-Ọlọ́run, ṣùgbọ́n ó pa Noa mọ́, oníwàásù òdodo, pẹ̀lú àwọn ọmọ méje mìíràn. Tí ó sọ àwọn ìlú Sodomu àti Gomorra di eérú, nígbà tí ó fi ìparun pátápátá dá wọn lẹ́bi, tí ó fi wọ́n ṣe àpẹẹrẹ fún àwọn tí yóò jẹ́ aláìwà-bí-Ọlọ́run. Tí ó sì yọ Lọti olóòtítọ́ ènìyàn, ẹni tí ìwà ẹ̀gbin àwọn ènìyàn láìlófin bà nínú jẹ́; (nítorí ọkùnrin olóòtítọ́ náà bí ó ti ń gbé àárín wọn, tí ó ń rí, tí ó sì ń gbọ́, lójoojúmọ́ ni ìwà búburú wọn ń bá ọkàn òtítọ́ rẹ̀ jẹ́) Bí ó bá rí bẹ́ẹ̀, Olúwa mọ bí a tí ń yọ àwọn ẹni ìwà-bí-Ọlọ́run kúrò nínú ìdánwò àti bí a ti ń pa àwọn aláìṣòótọ́ mo fún ọjọ́ ìdájọ́ nígbà tí wọn yóò tẹ̀síwájú nínú ìjìyà ẹ̀ṣẹ̀ wọn.