II. Pet 2:17-22
II. Pet 2:17-22 Bibeli Mimọ (YBCV)
Awọn wọnyi ni kanga ti kò li omi, ikũku ti ẹfũfu ngbá kiri; awọn ẹniti a pa òkunkun biribiri mọ́ de tití lai. Nitori igbati nwọn ba nsọ̀rọ ihalẹ asan, ninu ifẹkufẹ ara, nipa wọbia, nwọn a mã tan awọn ti nwọn fẹrẹ má ti ibọ tan kuro lọwọ ti nwọn wà ninu iṣina. Nwọn a mã ṣe ileri omnira fun wọn, nigbati awọn pãpã jẹ ẹrú idibajẹ́: nitori ẹniti o ba ṣẹgun ẹni, on na ni isi sọ ni di ẹrú. Nitori lẹhin ti nwọn ba ti yọ tan kuro ninu ẽri aiye, nipa mimọ̀ Oluwa ati Olugbala wa Jesu Kristi, bi nwọn ba si tun fi ara kó o, ti a si ṣẹgun wọn, igbẹhin wọn a buru jù ti iṣaju lọ. Nitori ìba san fun wọn, ki nwọn ki o má mọ̀ ọ̀na ododo, jù lẹhin ti nwọn mọ̀ ọ tan, ki nwọn ki o yipada kuro ninu ofin mimọ́ ti a fifun wọn. Owe otitọ nì ṣẹ si wọn lara, Ajá tún pada si ẽbì ara rẹ̀; ati ẹlẹdẹ ti a ti wẹ̀ mọ́ sinu àfọ ninu ẹrẹ̀.
II. Pet 2:17-22 Yoruba Bible (YCE)
Wọ́n dàbí ìsun omi tí ó ti gbẹ, ati ìkùukùu tí afẹ́fẹ́ ń fẹ́ kiri. Ọlọrun ti pèsè ọ̀gbun tí ó ṣókùnkùn biribiri fún wọn. Ọ̀rọ̀ kàǹkà-kàǹkà lásán, tí kò ní ìtumọ̀, ní ń ti ẹnu wọn jáde. Nípa ìwà ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ara ati ìwà ìbàjẹ́ wọn, wọ́n ń tan àwọn tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ ń kúrò láàrin ìwà ìtànjẹ ti ẹgbẹ́ wọ́n àtijọ́ jẹ. Wọ́n ṣèlérí òmìnira fún àwọn eniyan, bẹ́ẹ̀ sì ni ẹrú ohun ìbàjẹ́ wọn ni àwọn fúnra wọn jẹ́, nítorí tí ohunkohun bá ti borí eniyan, olúwarẹ̀ di ẹrú nǹkan náà. Nítorí bí wọ́n bá ti bọ́ lọ́wọ́ ìbàjẹ́ ayé nípa mímọ Oluwa ati olùgbàlà wa, Jesu Kristi, tí wọ́n tún wá pada sí ìwà àtijọ́, tí ìwà yìí bá tún borí wọn, ìgbẹ̀yìn wọn á wá burú ju ipò tí wọ́n wà lákọ̀ọ́kọ́ lọ. Nítorí ó sàn fún wọn kí wọn má mọ ọ̀nà òdodo ju pé kí wọn wá mọ̀ ọ́n tán kí wọn wá yipada kúrò ninu òfin mímọ́ tí a ti fi kọ́ wọn. Àwọn ni òtítọ́ òwe yìí ṣẹ mọ́ lára pé, “Ajá tún pada lọ kó èébì rẹ̀ jẹ.” Ati òwe kan tí wọn máa ń pa pé, “Ẹlẹ́dẹ̀ tí wọ́n fọ̀ nù yóo tún pada lọ yíràá ninu ẹrọ̀fọ̀.”
II. Pet 2:17-22 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Àwọn wọ̀nyí ni kànga tí kò ní omi, ìkùùkuu tí ẹ̀fúùfù ń gbá kiri; àwọn ẹni tí a pa òkùnkùn biribiri mọ́ dè títí láé. Nítorí ìgbà tí wọ́n bá ń sọ̀rọ̀ ìhàlẹ̀ asán, nínú ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ara, wọn a máa tan àwọn tí wọ́n fẹ́rẹ̀ má tí ì bọ́ tán kúrò lọ́wọ́ àwọn tí wọ́n wà nínú ìṣìnà. Wọn a máa ṣe ìlérí òmìnira fún wọn, nígbà tí àwọn pàápàá jẹ́ ẹrú ìdíbàjẹ́; nítorí ènìyàn tí di ẹrú ohunkóhun tí ó bá ṣe ọ̀gá rẹ̀. Lẹ́yìn tí wọ́n bá ti yọ tán kúrò nínú èérí ayé nípa mímọ́ Olúwa àti Olùgbàlà wá Jesu Kristi, bí wọn bá sì tún fi ara kó o, tí a sì ṣẹ́gun wọn, ìgbẹ̀yìn wọn a burú jú ti ìṣáájú lọ. Nítorí ìbá sàn fún wọn, kí wọn má mọ́ ọ̀nà òdodo, jù pé lẹ́yìn tí wọ́n mọ̀ ọ́n tán, kí wọn yípadà kúrò nínú òfin mímọ́ tí a fi fún wọn. Òwe òtítọ́ náà ṣẹ sí wọn lára: “Ajá tún padà sí èébì ara rẹ̀; àti ẹlẹ́dẹ̀ tí a ti wẹ̀mọ́ tún padà ń yíràá nínú ẹrọ̀fọ̀.”