II. Pet 1:5-11
II. Pet 1:5-11 Bibeli Mimọ (YBCV)
Ati nitori eyi nã pãpã, ẹ mã ṣe aisimi gbogbo, ẹ fi ìwarere kún igbagbọ́, ati ìmọ kún ìwarere; Ati airekọja kún ìmọ; ati sũru kún airekọja; ati ìwa-bi-Ọlọrun kún sũru; Ati ifẹ ọmọnikeji kún ìwa-bi-Ọlọrun; ati ifẹni kún ifẹ ọmọnikeji. Nitori bi ẹnyin bá ni nkan wọnyi ti nwọn bá si pọ̀, nwọn kì yio jẹ ki ẹ ṣe ọ̀lẹ tabi alaileso ninu ìmọ Oluwa wa Jesu Kristi. Nitori ẹniti o ba ṣe alaini nkan wọnyi, o fọju, kò le riran li òkẽre, o si ti gbagbé pe a ti wẹ̀ on nù kuro ninu ẹ̀ṣẹ rẹ̀ atijọ. Nitorina, ará, ẹ tubọ mã ṣe aisimi lati sọ ìpe ati yiyàn nyin di dajudaju: nitori bi ẹnyin ba nṣe nkan wọnyi, ẹnyin kì yio kọsẹ lai. Nitori bayi li a ó pese fun nyin lọpọlọpọ lati wọ ijọba ainipẹkun ti Oluwa ati Olugbala wa Jesu Kristi.
II. Pet 1:5-11 Yoruba Bible (YCE)
Nítorí èyí, kí ẹ ní ìtara láti fi ìwà ọmọlúwàbí kún igbagbọ yín, kí ẹ sì fi ìmọ̀ kún ìwà ọmọlúwàbí. Ẹ fi ìkóra-ẹni-níjàánu kún ìmọ̀, kí ẹ fi ìgboyà kún ìkóra-ẹni-níjàánu, kí ẹ sì fi ìfọkànsìn kún ìgboyà. Ẹ fi ìṣoore fún àwọn onigbagbọ kún ìfọkànsìn, kí ẹ sì fi ìfẹ́ kún ìṣoore fún àwọn onigbagbọ. Nítorí tí ẹ bá ní àwọn nǹkan wọnyi; tí wọn ń dàgbà ninu yín, ìgbé-ayé yín kò ní jẹ́ lásán tabi kí ó jẹ́ aláìléso ninu mímọ Jesu Kristi. Afọ́jú ni ẹni tí kò bá ní àwọn nǹkan wọnyi, olúwarẹ̀ kò ríran jìnnà, kò sì lè ronú ẹ̀yìn-ọ̀la. Irú ẹni bẹ́ẹ̀ ti gbàgbé ìwẹ̀mọ́ ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ àtijọ́. Ẹ̀yin ará, ìdí rẹ̀ nìyí tí ẹ fi gbọdọ̀ túbọ̀ ní ìtara láti fi pípè tí a pè yín ati yíyàn tí a yàn yín hàn. Tí ẹ bá ń ṣe àwọn nǹkan wọnyi, ẹ kò ní kùnà. Bẹ́ẹ̀ ni ẹ óo ti ṣe ní ẹ̀tọ́ láti rìn gaara wọ ìjọba ayérayé ti Oluwa wa, ati Olùgbàlà Jesu Kristi.
II. Pet 1:5-11 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Àti nítorí ìdí èyí, ẹ máa ṣe àìsimi gbogbo, ẹ fi ìwà rere kún ìgbàgbọ́, àti ìmọ̀ kún ìwà rere; àti àìrékọjá kún ìmọ̀; àti sùúrù kún àìrékọjá; àti ìwà-bí-Ọlọ́run kún sùúrù. Àti ìfẹ́ ọmọnìkejì kún ìwà-bí-Ọlọ́run; àti ìfẹ́ni kún ìfẹ́ ọmọnìkejì. Nítorí bí ẹ̀yin bá ní nǹkan wọ̀nyí tí wọ́n bá sì pọ̀, wọn kì yóò jẹ́ kí ẹ ṣe ọ̀lẹ tàbí aláìléso nínú ìmọ̀ Olúwa wa Jesu Kristi. Ṣùgbọ́n ẹni tí ó bá ṣe aláìní nǹkan wọ̀nyí, kò lè ríran ní òkèèrè, ó fọjú, ó sì ti gbàgbé pé a ti wẹ òun nù kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ àtijọ́. Nítorí náà, ará ẹ túbọ̀ máa ṣe àìsimi láti sọ ìpè àti yíyàn yín di dájúdájú: nítorí bí ẹ̀yin bá ń ṣe nǹkan wọ̀nyí, ẹ̀yin kì yóò ṣubú. Nítorí báyìí ni a ó pèsè fún yín lọ́pọ̀lọpọ̀ láti wọ ìjọba àìnípẹ̀kun ti Olúwa àti Olùgbàlà wa Jesu Kristi.