II. A. Ọba 8:7-13
II. A. Ọba 8:7-13 Bibeli Mimọ (YBCV)
Eliṣa si wá si Damasku; Benhadadi ọba Siria si nṣe aisàn; a si sọ fun u, wipe, Enia Ọlọrun de ihinyi. Ọba si wi fun Hasaeli pe, Mu ọrẹ lọwọ rẹ, si lọ ipade enia Ọlọrun na, ki o si bère lọwọ Oluwa lọdọ rẹ̀, wipe, Emi o ha sàn ninu arùn yi? Bẹ̃ni Hasaeli lọ ipade rẹ̀, o si mu ọrẹ li ọwọ rẹ̀, ani ninu gbogbo ohun rere Damasku, ogoji ẹrù ibakasiẹ, o si de, o si duro niwaju rẹ̀, o si wipe, Ọmọ rẹ Benhadadi ọba Siria rán mi si ọ, wipe, Emi o ha sàn ninu arùn yi? Eliṣa si wi fun u pe, Lọ, ki o si sọ fun u pe, Iwọ iba sàn nitõtọ: ṣugbọn Oluwa ti fi hàn mi pe, nitõtọ on o kú. On si tẹ̀ oju rẹ̀ mọ ọ gidigidi, titi oju fi tì i; enia Ọlọrun na si sọkun. Hasaeli si wipe, Ẽṣe ti oluwa mi fi nsọkun? On si dahùn pe, Nitoriti mo mọ̀ ibi ti iwọ o ṣe si awọn ọmọ Israeli: awọn odi agbara wọn ni iwọ o fi iná bọ̀, awọn ọdọmọkunrin wọn ni iwọ o fi idà pa, iwọ o si fọ́ ọmọ wẹwẹ́ wọn tútu, iwọ o si là inu awọn aboyun wọn. Hasaeli si wipe, Ṣugbọn kinla? Iranṣẹ rẹ iṣe aja, ti yio fi ṣe nkan nla yi? Eliṣa si dahùn wipe, Oluwa ti fi hàn mi pe, iwọ o jọba lori Siria.
II. A. Ọba 8:7-13 Yoruba Bible (YCE)
Eliṣa lọ sí Damasku ní àkókò kan tí Benhadadi ọba Siria wà lórí àìsàn. Nígbà tí wọ́n sọ fún ọba pé Eliṣa wà ní Damasku, ọba sọ fún Hasaeli, ọ̀kan ninu àwọn iranṣẹ rẹ̀ pé, “Mú ẹ̀bùn lọ́wọ́, kí o sì lọ bá wolii náà, kí o sọ fún un pé kí ó bá mi bèèrè lọ́wọ́ OLUWA bóyá n óo yè ninu àìsàn yìí.” Hasaeli di ogoji ẹrù ràkúnmí tí ó kún fún oniruuru ohun rere tí ó wà ní Damasku, ó lọ bá Eliṣa. Nígbà tí Hasaeli pàdé rẹ̀, ó sọ pé, “Iranṣẹ rẹ, Benhadadi, ọba Siria, rán mi láti bèèrè lọ́wọ́ rẹ bóyá òun óo yè ninu àìsàn òun.” Eliṣa dáhùn pé, “OLUWA ti fi hàn mí pé yóo kú, ṣugbọn lọ sọ fún un pé yóo yè.” Eliṣa tẹjú mọ́ Hasaeli títí ojú fi tì í. Eliṣa sì sọkún. Hasaeli bèèrè pé, “Kí ló dé tí o fi ń sunkún, oluwa mi?” Eliṣa dáhùn pé, “Nítorí pé mo mọ oríṣìíríṣìí nǹkan burúkú tí o óo ṣe sí àwọn ọmọ Israẹli: O óo jó ibi ààbò wọn, o óo fi idà pa àwọn ọmọkunrin wọn, o óo tú àwọn ọmọ wẹ́wẹ́ wọn ká, o óo sì la inú àwọn aboyún wọn.” Hasaeli dáhùn pé, “Ta ni mí, tí n óo fi ṣe nǹkan tí ó lágbára tóbẹ́ẹ̀?” Eliṣa dáhùn pé, “OLUWA ti fi hàn mí pé o óo jọba ní Siria.”
II. A. Ọba 8:7-13 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (BMYO)
Eliṣa lọ sí Damasku, Beni-Hadadi ọba Siria ń ṣe àìsàn. Nígbà tí wọ́n sọ fún ọba pé, “Ènìyàn Ọlọ́run ti wá láti gbogbo ọ̀nà òkè síbí,” ọba sì wí fún Hasaeli pé, “Mú ọrẹ lọ́wọ́ rẹ, sì lọ pàdé ènìyàn Ọlọ́run. Kí o sì béèrè OLúWA láti ọ̀dọ̀ rẹ̀, béèrè lọ́wọ́ rẹ̀ pé ṣé èmi yóò sàn nínú àìsàn yìí?” Hasaeli lọ láti pàdé Eliṣa, ó mú lọ pẹ̀lú rẹ̀ ẹ̀bùn gẹ́gẹ́ bí ogójì ẹrù ìbákasẹ tí gbogbo ìní tí ó dára jù fún wíwò ti Damasku, ó sì wọlé lọ ó sì dúró níwájú rẹ̀, ó sì wí pé, “Ọmọ rẹ Beni-Hadadi ọba Siria rán mi láti béèrè pé, ‘Ṣé èmi yóò sàn nínú àìsàn mi yìí?’ ” Eliṣa da á lóhùn pé, “Lọ kí o lọ sọ fún un pé, ‘Ìwo ìbá sàn nítòótọ́’; ṣùgbọ́n OLúWA ti fihàn mí pé nítòótọ́ òun yóò kùú.” Ó sì ranjú mọ́ ọn pẹ̀lú àtẹjúmọ́ gidigidi títí tí ojú fi ti Hasaeli. Nígbà náà ènìyàn Ọlọ́run bẹ̀rẹ̀ sí ní sọkún. “Kí ni ó dé tí olúwa mi fi ń sọkún?” Hasaeli béèrè. “Nítorí pé èmi mọ ibi tí ìwọ yóò ṣe sí Israẹli,” ó sì dáhùn pé, “Ìwọ yóò fi iná si odi agbára wọn, ìwọ yóò, pa àwọn ọ̀dọ́ ọmọkùnrin wọn pẹ̀lú idà, ìwọ yóò kọlù àwọn ọmọ wẹ́wẹ́ wọn, ìwọ ó sì fọ́ wọn túútúú, ìwọ o sì la inú àwọn aboyún wọn.” Hasaeli sì wí pé. “Báwo ni ìránṣẹ́ rẹ, ajá lásán làsàn yóò ṣe ṣe irú nǹkan ńlá bẹ́ẹ̀?” “OLúWA ti fihàn mí pé ìwọ ni yóò jẹ ọba Siria,” Eliṣa dá a lóhùn.