II. A. Ọba 8:1-2
II. A. Ọba 8:1-2 Bibeli Mimọ (YBCV)
ELIṢA si wi fun obinrin na, ọmọ ẹniti o ti sọ di ãyè, wipe, Dide, si lọ, iwọ ati ile rẹ, ki o si ṣe atipo nibikibi ti iwọ ba le ṣe atipo: nitoriti Oluwa pe ìyan: yio si mu pẹlu ni ilẹ, li ọdun meje. Obinrin na si dide, o si ṣe gẹgẹ bi ọ̀rọ enia Ọlọrun na: on si lọ pẹlu ile rẹ̀, nwọn si ṣe atipo ni ilẹ awọn ara Filistia li ọdun meje.
II. A. Ọba 8:1-2 Yoruba Bible (YCE)
Eliṣa sọ fún obinrin ará Ṣunemu, ẹni tí Eliṣa jí ọmọ rẹ̀ tí ó kú pé, “OLUWA yóo rán ìyàn sí ilẹ̀ yìí fún ọdún meje, nítorí náà, kí ìwọ ati ẹbí rẹ lọ máa gbé ní ilẹ̀ mìíràn.” Obinrin náà gbọ́ ọ̀rọ̀ Eliṣa, òun ati ẹbí rẹ̀ sì lọ ń gbé ilẹ̀ àwọn ará Filistia fún ọdún meje.
II. A. Ọba 8:1-2 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Nísinsin yìí, Eliṣa wí fún obìnrin náà tí ọmọ rẹ̀ ọkùnrin jí padà sáyé pé, “jáde lọ pẹ̀lú ìdílé rẹ kí o sì lọ dúró fún ìgbà díẹ̀ ní ibikíbi tí o bá le dúró sí, nítorí OLúWA ti pàṣẹ ìyàn ní ìlú tí yóò lò tó ọdún méje.” Obìnrin náà tẹ̀síwájú gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ ènìyàn Ọlọ́run ti sọ. Òun àti ìdílé rẹ̀ sí lọ, wọ́n sì ṣe àtìpó ní ilẹ̀ àwọn ará Filistini fún ọdún méje.