II. A. Ọba 5:1-27

II. A. Ọba 5:1-27 Bibeli Mimọ (YBCV)

NJẸ Naamani, olori-ogun ọba Siria, jẹ enia nla niwaju oluwa rẹ̀, ati ọlọla, nitori nipa rẹ̀ ni Oluwa ti fi iṣẹgun fun Siria: on si jẹ alagbara akọni ọkunrin ṣugbọn adẹtẹ̀ ni. Awọn ara Siria si ti jade lọ ni ẹgbẹ́-ẹgbẹ́, nwọn si ti mu ọmọbinrin kekere kan ni igbèkun lati ilẹ Israeli wá; on si duro niwaju obinrin Naamani. On si wi fun iya rẹ̀ pe, oluwa mi iba wà niwaju woli ti mbẹ ni Samaria! nitõtọ on iba wò o sàn kuro ninu ẹ̀tẹ rẹ̀. On si wọle, o si sọ fun oluwa rẹ̀ pe, Bayi bayi li ọmọdebinrin ti o ti ilẹ Israeli wá wi. Ọba Siria si wipe, Wá na, lọ, emi o si fi iwe ranṣẹ si ọba Israeli. On si jade lọ, o si mu talenti fàdakà mẹwa lọwọ, ati ẹgbãta iwọ̀n wurà, ati ipãrọ aṣọ mẹwa. On si mu iwe na tọ̀ ọba Israeli wá, wipe, Njẹ nisisiyi nigbati iwe yi ba de ọdọ rẹ, kiyesi i, emi rán Naamani iranṣẹ mi si ọ, ki iwọ ki o le wò o sàn kuro ninu ẹ̀tẹ rẹ̀. O si ṣe, nigbati ọba Israeli kà iwe na tan, o si fà aṣọ rẹ̀ ya, o si wipe, Emi ha iṣe Ọlọrun, lati pa ati lati sọ di ãyè, ti eleyi fi ranṣẹ si mi lati ṣe awòtan enia kan kuro ninu ẹ̀tẹ rẹ̀? nitorina, ẹ rò o wò, mo bẹ̀ nyin, ki ẹ si wò o bi on ti nwá mi ni ijà. O si ṣe, nigbati Eliṣa enia Ọlọrun gbọ́ pe, ọba Israeli fà aṣọ rẹ̀ ya, o si ranṣẹ si ọba wipe, Ẽṣe ti iwọ fi fà aṣọ rẹ ya? jẹ ki o tọ̀ mi wá nisisiyi, on o si mọ̀ pe, woli kan mbẹ ni Israeli. Bẹ̃ni Naamani de pẹlu awọn ẹṣin rẹ̀ ati pẹlu kẹkẹ́ rẹ̀, o si duro li ẹnu-ọ̀na ile Eliṣa. Eliṣa si ràn iranṣẹ kan si i wipe, Lọ, ki o si wẹ̀ ni Jordani nigba meje, ẹran-ara rẹ yio si tun bọ̀ sipò fun ọ, iwọ o si mọ́. Ṣugbọn Naamani binu, o si pada lọ, o si wipe, Kiyesi, i, mo rò ninu mi pe, dajudaju on o jade tọ̀ mi wá, yio si duro, yio si kepè orukọ Oluwa Ọlọrun rẹ̀, yio si fi ọwọ rẹ̀ pa ibẹ̀ na, yio si ṣe awòtan ẹ̀tẹ na. Abana ati Farpari, awọn odò Damasku kò ha dara jù gbogbo awọn omi Israeli lọ? emi kì iwẹ̀ ninu wọn ki emi si mọ́? Bẹ̃li o yipada, o si jade lọ ni irúnu. Awọn iranṣẹ rẹ̀ si sunmọ ọ, nwọn si ba a sọ̀rọ, nwọn si wipe, Baba mi, woli iba wi fun ọ pe, ki o ṣe ohun nla kan, iwọ kì ba ti ṣe e bi? melomelo, nigbati o wi fun ọ pe, Wẹ̀, ki o si mọ́? Nigbana ni o sọ̀kalẹ, o si tẹ̀ ara rẹ̀ bọ inu Jordani nigba meje, gẹgẹ bi ọ̀rọ enia Ọlọrun: ẹran-ara rẹ̀ si tún pada bọ̀ gẹgẹ bi ẹran-ara ọmọ kekere, on si mọ́. O si pada tọ̀ enia Ọlọrun na lọ, on, ati gbogbo ẹgbẹ́ rẹ̀, nwọn si wá, nwọn duro niwaju rẹ̀: on si wipe, wõ, nisisiyi ni mo to mọ̀ pe, Kò si Ọlọrun ni gbogbo aiye, bikòṣe ni Israeli: njẹ nisisiyi, emi bẹ̀ ọ, gbà ẹbun lọwọ iranṣẹ rẹ. Ṣugbọn on wipe, Bi Oluwa ti mbẹ, niwaju ẹniti emi duro, emi kì yio gbà nkan. O si rọ̀ ọ ki o gbà, ṣugbọn on kọ̀. Naamani si wipe, Njẹ, emi bẹ̀ ọ, a kì yio ha fi erupẹ ẹrù ibàka meji fun iranṣẹ rẹ? nitori lati oni lọ iranṣẹ rẹ kì yio rubọ sisun, bẹ̃ni kì yio rubọ si awọn ọlọrun miran, bikòṣe si Oluwa. Ninu nkan yi ni ki Oluwa ki o darijì iranṣẹ rẹ, nigbati oluwa mi ba lọ si ile Rimmoni lati foribalẹ nibẹ, ti on ba si fi ara tì ọwọ mi, ti emi tẹ̀ ara mi ba ni ile Rimmoni: nigbati mo ba tẹ̀ ara mi ba ni ile Rimmoni, ki Oluwa ki o darijì iranṣẹ rẹ ninu nkan yi. On si wi fun u pe, Mã lọ ni alãfia. Bẹ̃ni o si jade lọ jinà diẹ kuro lọdọ rẹ̀. Ṣugbọn Gehasi, iranṣẹ Eliṣa enia Ọlọrun na wipe, Kiyesi i, oluwa mi ti dá Naamani ara Siria yi si, niti kò gbà nkan ti o mu wá lọwọ rẹ̀: ṣugbọn, bi Oluwa ti mbẹ, emi o sare bá a, emi o si gbà nkan lọwọ rẹ̀. Bẹ̃ni Gehasi lepa Naamani. Nigbati Naamani ri ti nsare bọ̀ lẹhin on, o sọ̀kalẹ kuro ninu kẹkẹ́ lati pade rẹ̀, o si wipe, Alafia kọ? On si wipe, Alafia ni. Oluwa mi rán mi, wipe, Kiyesi i, nisisiyi ni ọdọmọkunrin meji ninu awọn ọmọ woli ti òke Efraimu wá ọdọ mi; emi bẹ̀ o, fun wọn ni talenti fadakà kan, ati ipàrọ aṣọ meji. Naamani si wipe, Fi ara balẹ, gbà talenti meji. O si rọ̀ ọ, o si dì talenti fadakà meji sinu apò meji, pẹlu ipàrọ aṣọ meji, o si gbé wọn rù ọmọ-ọdọ rẹ̀ meji; nwọn si rù wọn niwaju rẹ̀. Nigbati o si de ibi ile ìṣọ, o gbà wọn lọwọ wọn, o si tò wọn sinu ile: o si jọ̀wọ awọn ọkunrin na lọwọ lọ, nwọn si jade lọ. Ṣugbọn on wọ̀ inu ile lọ, o si duro niwaju oluwa rẹ̀. Eliṣa si wi fun u pe, Gehasi, nibo ni iwọ ti mbọ̀? On si wipe, Iranṣẹ rẹ kò lọ ibikibi. On si wi fun u pe, Ọkàn mi kò ha ba ọ lọ, nigbati ọkunrin na fi yipada kuro ninu kẹkẹ́ rẹ̀ lati pade rẹ? Eyi ha iṣe akokò ati gbà fadakà, ati lati gbà aṣọ, ati ọgbà-olifi ati ọgbà-ajara, ati àgutan, ati malu, ati iranṣékunrin ati iranṣẹbinrin? Nitorina ẹ̀tẹ Naamani yio lẹ mọ ọ, ati iru-ọmọ rẹ titi lai. On si jade kuro niwaju rẹ̀, li adẹtẹ̀ ti o funfun bi ojodidì.

II. A. Ọba 5:1-27 Yoruba Bible (YCE)

Naamani, olórí ogun Siria, jẹ́ eniyan pataki ati ọlọ́lá níwájú ọba Siria, nítorí pé nípasẹ̀ rẹ̀ ni OLUWA ṣe fún ilẹ̀ Siria ní ìṣẹ́gun. Ó jẹ́ akọni jagunjagun, ṣugbọn adẹ́tẹ̀ ni. Iyawo Naamani ní iranṣẹbinrin kékeré kan tí àwọn ará Siria mú lẹ́rú wá láti ilẹ̀ Israẹli, nígbà tí wọ́n lọ bá wọn jagun. Ní ọjọ́ kan, ọmọbinrin náà sọ fún ọ̀gá rẹ̀ pé, “Bí oluwa mi Naamani bá lọ sí ọ̀dọ̀ wolii tí ó wà ní Samaria, yóo rí ìwòsàn gbà.” Nígbà tí Naamani gbọ́, ó sọ ohun tí ọmọbinrin náà sọ fún ọba. Ọba Siria dáhùn pé, “Tètè lọ, n óo sì fi ìwé ranṣẹ sí ọba Israẹli.” Naamani mú ìwọ̀n talẹnti fadaka mẹ́wàá ati ẹgbaata (6,000) ìwọ̀n ṣekeli wúrà ati ìpààrọ̀ aṣọ mẹ́wàá, ó bá lọ sí ọ̀dọ̀ ọba Israẹli pẹlu ìwé náà. Ohun tí wọ́n kọ sinu ìwé náà nìyí, “Ẹni tí ó mú ìwé yìí wá ni Naamani, iranṣẹ mi, mo rán an wá sọ́dọ̀ rẹ kí o lè wò ó sàn ninu àrùn ẹ̀tẹ̀ rẹ̀.” Nígbà tí ọba Israẹli ka ìwé náà ó fa aṣọ rẹ̀ ya láti fi ìbẹ̀rù rẹ̀ hàn, ó sì wí pé, “Èmi ha í ṣe Ọlọrun tí ó ní agbára ikú ati ìyè bí, tí ọba Siria fi rò wí pé mo lè wo eniyan sàn kúrò ninu ẹ̀tẹ̀? Èyí fi hàn pé ó ń wá ìjà ni.” Nígbà tí Eliṣa gbọ́ pé ọba Israẹli ti fa aṣọ rẹ̀ ya, ó ranṣẹ sí i pé, “Kí ló dé tí o fi fa aṣọ rẹ ya? Mú ọkunrin náà wá sọ́dọ̀ mi, kí ó lè mọ̀ pé wolii kan wà ní Israẹli.” Naamani bá lọ ti òun ti àwọn ẹṣin ati kẹ̀kẹ́-ogun rẹ̀, ó sì dúró lẹ́nu ọ̀nà ilé Eliṣa. Eliṣa rán iranṣẹ kan kí ó sọ fún un pé kí ó lọ wẹ ara rẹ̀ ninu odò Jọdani ní ìgbà meje, yóo sì rí ìwòsàn. Ṣugbọn Naamani fi ibinu kúrò níbẹ̀, ó ní, “Mo rò pé yóo jáde wá, yóo gbadura sí OLUWA Ọlọrun rẹ̀, yóo fi ọwọ́ rẹ̀ pa ibẹ̀, yóo sì ṣe àwòtán ẹ̀tẹ̀ náà ni. Ṣé àwọn odò Abana ati odò Faripari tí wọ́n wà ní Damasku kò dára ju gbogbo àwọn odò tí wọ́n wà ní Israẹli lọ ni? Ṣebí mo lè wẹ̀ ninu wọn kí n sì mọ́!” Ó bá yipada, ó ń bínú lọ. Àwọn iranṣẹ rẹ̀ bá gbà á níyànjú pé, “Baba, ṣé bí wolii náà bá sọ pé kí o ṣe ohun tí ó le ju èyí lọ, ṣé o kò ní ṣe é? Kí ló dé tí o kò lè wẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ó ti wí, kí o sì rí ìwòsàn gbà?” Naamani bá lọ sí odò Jọdani, ó wẹ̀ ní ìgbà meje gẹ́gẹ́ bí Eliṣa ti pàṣẹ fún un, ó rí ìwòsàn, ara rẹ̀ sì jọ̀lọ̀ bí ara ọmọde. Lẹ́yìn náà ó pada pẹlu àwọn iranṣẹ rẹ̀ sọ́dọ̀ Eliṣa, ó ní, “Nisinsinyii ni mo mọ̀ pé kò sí ọlọrun mìíràn ní gbogbo ayé àfi Ọlọrun Israẹli. Nítorí náà jọ̀wọ́ gba ẹ̀bùn yìí lọ́wọ́ iranṣẹ rẹ.” Ṣugbọn Eliṣa dáhùn pé, “Mo fi OLUWA tí mò ń sìn búra pé n kò ní gba nǹkankan lọ́wọ́ rẹ.” Naamani rọ̀ ọ́ kí ó gbà wọ́n, ṣugbọn ó kọ̀. Naamani bá ní, “Jọ̀wọ́ fún mi ní ààyè láti bu erùpẹ̀ ẹrù kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ meji lọ sílé nítorí láti òní lọ, iranṣẹ rẹ kì yóo rúbọ sí ọlọrun mìíràn bíkòṣe OLUWA. Mo bẹ̀bẹ̀ kí OLUWA dáríjì mí nígbà tí mo bá tẹ̀lé oluwa mi lọ sinu tẹmpili Rimoni, oriṣa Siria láti rúbọ sí i. Bí oluwa mi bá gbé ara lé apá mi, tí èmi náà sì tẹríba ninu tẹmpili Rimoni, kí OLUWA dáríjì iranṣẹ rẹ.” Eliṣa sọ fún un pé “Máa lọ ní alaafia.” Naamani bá lọ. Ṣugbọn kò tíì rìn jìnnà, nígbà tí Gehasi, iranṣẹ Eliṣa, sọ ninu ara rẹ̀ pé, “Olúwa mi jẹ́ kí Naamani ará Siria yìí lọ láì gba ohun tí ó mú wá lọ́wọ́ rẹ̀. Mo fi OLUWA búra pé, n óo sáré tẹ̀lé e láti gba nǹkan lọ́wọ́ rẹ̀.” Ó bá sáré tẹ̀lé Naamani. Nígbà tí Naamani rí i pé ẹnìkan ń sáré bọ̀, ó sọ̀kalẹ̀ lórí kẹ̀kẹ́ ogun tí ó gùn láti pàdé rẹ̀, ó bèèrè pé, “Ṣé kò sí nǹkan?” Gehasi dáhùn pé, “Rárá, kò sí nǹkan. Oluwa mi ni ó rán mi sí ọ pé, ‘Nisinsinyii ni meji ninu àwọn ọmọ àwọn wolii tí wọn ń gbé òkè Efuraimu wá sọ́dọ̀ mi. Jọ̀wọ́ fún wọn ní ìwọ̀n talẹnti fadaka kan ati aṣọ meji.’ ” Naamani sì rọ̀ ọ́ kí ó gba ìwọ̀n talẹnti meji. Ó di owó náà sinu àpò meji pẹlu aṣọ meji. Ó pàṣẹ fún iranṣẹ meji kí wọ́n bá Gehasi gbé wọn lọ. Nígbà tí wọ́n dé orí òkè tí Eliṣa ń gbé, Gehasi gba àwọn ẹrù náà lórí wọn, ó gbé wọn sinu ilé, ó sì dá àwọn iranṣẹ Naamani pada. Nígbà tí ó wọlé, Eliṣa bèèrè lọ́wọ́ rẹ̀ pé, “Níbo ni o lọ?” Ó dáhùn pé, “N kò lọ sí ibìkan kan.” Eliṣa dáhùn pé, “Ṣé o kò mọ̀ pé mo wà pẹlu rẹ ninu ẹ̀mí, nígbà tí Naamani sọ̀kalẹ̀ ninu kẹ̀kẹ́-ogun, tí ó gùn, tí ó wá láti pàdé rẹ? Ṣé àkókò yìí ni ó yẹ láti gba fadaka tabi aṣọ tabi olifi tabi ọgbà àjàrà tabi aguntan tabi mààlúù tabi iranṣẹkunrin tabi iranṣẹbinrin? Nítorí ìdí èyí, ẹ̀tẹ̀ Naamani yóo lẹ̀ mọ́ ọ lára ati ìdílé rẹ ati ìrandíran rẹ títí lae.” Gehasi sì jáde kúrò lọ́dọ̀ Eliṣa ní adẹ́tẹ̀, ó funfun bíi ẹ̀gbọ̀n òwú.

II. A. Ọba 5:1-27 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)

Naamani jẹ́ olórí ogun ọba Aramu. Ó jẹ́ ènìyàn ńlá níwájú ọ̀gá rẹ̀, wọ́n sì bu ọlá fún un, nítorí nípasẹ̀ rẹ̀ ni OLúWA ti fi ìṣẹ́gun fún Aramu. Òun jẹ́ alágbára, akọni ọkùnrin ṣùgbọ́n, ó dẹ́tẹ̀. Nísinsin yìí ẹgbẹgbẹ́ láti Aramu ti jáde lọ láti mú ọmọ obìnrin kékeré kan ní ìgbèkùn láti Israẹli, ó sì sin ìyàwó Naamani. Ó sọ fún ọ̀gá rẹ̀ obìnrin pé, “Tí ó bá jẹ́ wí pé ọ̀gá mi lè rí wòlíì tí ó wà ní Samaria! Yóò wò ó sàn kúrò nínú ẹ̀tẹ̀ rẹ̀.” Naamani lọ sí ọ̀dọ̀ ọ̀gá rẹ̀ ó sì wí fún un ohun tí ọmọbìnrin Israẹli ti sọ. “Ní gbogbo ọ̀nà, lọ,” ọba Aramu dá a lóhùn pé, “Èmi yóò fi ìwé ránṣẹ́ sí ọba Israẹli.” Bẹ́ẹ̀ ni Naamani lọ, ó sì mú pẹ̀lú rẹ̀ tálẹ́ǹtì fàdákà mẹ́wàá, ẹgbẹ̀ta ìwọ̀n wúrà (6,000) àti ìpààrọ̀ aṣọ mẹ́wàá. Ìwé tí ó mú lọ sọ́dọ̀ ọba Israẹli kà pé: “Pẹ̀lú ìwé yìí èmi ń rán ìránṣẹ́ mi Naamani sí ọ pé o lè wò ó sàn kúrò nínú ẹ̀tẹ̀ rẹ̀.” Bí ọba Israẹli ti ka ìwé náà ó fa aṣọ rẹ̀ ya, ó sì wí pé, “Èmi ha jẹ́ Ọlọ́run? Ǹjẹ́ èmi le pa kí n sì mú wá sí ààyè padà? Kí ni ó dé tí eléyìí rán ènìyàn sí mi láti wo ààrùn ẹ̀tẹ̀ rẹ sàn, kí ẹ wo bí ó ti ń wá ọ̀nà láti wá ìjà pẹ̀lú mi!” Nígbà tí Eliṣa ènìyàn Ọlọ́run gbọ́ pé ọba Israẹli ti ya aṣọ rẹ̀, ó sì rán iṣẹ́ yìí sí i pé: “Kí ni ó dé tí o fi fa aṣọ rẹ ya? Jẹ́ kí ọkùnrin náà wá sí ọ̀dọ̀ mi. Òun yóò sì mọ̀ pé wòlíì wà ní Israẹli.” Bẹ́ẹ̀ ni Naamani sì lọ pẹ̀lú ẹṣin rẹ̀ àti kẹ̀kẹ́ rẹ̀ ó sì dúró ní ẹnu-ọ̀nà ilé Eliṣa. Eliṣa rán ìránṣẹ́ láti lọ sọ fún un pé, “Lọ, wẹ̀ ara rẹ ní ìgbà méje ní odò Jordani, ẹran-ara rẹ yóò sì tún padà bọ̀ sípò, ìwọ yóò sì mọ́.” Ṣùgbọ́n Naamani lọ pẹ̀lú ìbínú ó sì wí pé, “Mo lérò pé yóò sì dìde jáde wá nítòótọ́ sí mi, yóò sì pe orúkọ OLúWA Ọlọ́run, fi ọwọ́ rẹ̀ lórí ibẹ̀ kí ó sì wo ẹ̀tẹ̀ mi sàn. Abana àti Fapari, odò Damasku kò ha dára ju gbogbo omi Israẹli lọ? Ṣé èmi kò le wẹ̀ nínú wọn kí n sì mọ́?” Bẹ́ẹ̀ ni ó yípadà, ó sì lọ pẹ̀lú ìrunú. Ìránṣẹ́ Naamani lọ sọ́dọ̀ rẹ̀ ó sì wí pé, “Baba mi, tí wòlíì bá ti sọ fún ọ láti ṣe ohun ńlá kan, ṣé ìwọ kì bá ti ṣe, mélòó mélòó nígbà náà, nígbà tí ó sọ fún ọ pé, ‘Wẹ̀ kí o sì mọ́’!” Bẹ́ẹ̀ ni ó sì sọ̀kalẹ̀ lọ ó sì tẹ ara rẹ̀ bọ inú odò Jordani ní ìgbà méje, gẹ́gẹ́ bí ènìyàn Ọlọ́run ti sọ fún un, ẹran-ara rẹ̀ sì tún padà sí mímọ́ gẹ́gẹ́ bí ọmọkùnrin kékeré. Nígbà náà Naamani àti gbogbo àwọn ìránṣẹ́ padà lọ sí ọ̀dọ̀ ènìyàn Ọlọ́run. Ó sì dúró níwájú rẹ̀ ó sì wí pé, “Nísinsin yìí èmi mọ̀ pé kò sí Ọlọ́run ní gbogbo àgbáyé àyàfi ní Israẹli nìkan. Jọ̀wọ́ gba ẹ̀bùn láti ọwọ́ ìránṣẹ́ rẹ.” Wòlíì náà dáhùn pé, “Gẹ́gẹ́ bí OLúWA ti ń bẹ láààyè, ẹni tí mo ń sìn, èmi kò nígbà ohun kan,” Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé Naamani rọ̀ ọ́ láti gbà á, ó kọ̀. Naamani wí pé, “Tí o kò bá nígbà, jọ̀wọ́ jẹ́ kí a fi fún èmi ìránṣẹ́ rẹ gẹ́gẹ́ bí ọ̀pọ̀ ẹrù erùpẹ̀ tí ìbáaka méjì le rù, nítorí láti òní lọ ìránṣẹ́ rẹ kì yóò rú ẹbọ sísun àti rú ẹbọ sí ọ̀kan lára àwọn ọlọ́run mìíràn mọ́ bí kò ṣe sí OLúWA. Ṣùgbọ́n kí OLúWA kí ó dáríjì ìránṣẹ́ rẹ fún nǹkan yìí: Nígbà tí ọ̀gá mi wọ inú ilé Rimoni láti fi orí balẹ̀ tí ó sì fi ara ti ọwọ́ mi tí mo sì tẹ ara mi ba pẹ̀lú níbẹ̀. Nígbà tí èmi tẹ ara mi ba ní ilé Rimoni, kí OLúWA dáríjì ìránṣẹ́ rẹ fún èyí.” Eliṣa wí pé, “Máa lọ ní àlàáfíà.” Lẹ́yìn ìgbà tí Naamani tí rin ìrìnàjò tí ó jìnnà, Gehasi, ìránṣẹ́ Eliṣa ènìyàn Ọlọ́run, ó wí fún ara rẹ̀ pé, “Ọ̀gá mi jẹ́ ẹni tí ó rọ́nú lórí Naamani, ará Aramu, nípa pé kò gba ohunkóhun ní ọwọ́ rẹ̀ ohun tí ó mú wá, gẹ́gẹ́ bí OLúWA ti ń bẹ láààyè, èmi yóò sá tẹ̀lé e èmi yóò sì gba ohun kan ní ọwọ́ rẹ̀.” Bẹ́ẹ̀ ni Gehasi sáré tẹ̀lé Naamani. Nígbà tí Naamani rí i tí ó ń sáré tẹ̀lé e, ó sì sọ̀kalẹ̀ lórí kẹ̀kẹ́ láti pàdé rẹ̀. “Ṣé gbogbo nǹkan wà dáradára?” ó béèrè. “Gbogbo nǹkan wà dáradára,” Gehasi dá a lóhùn. “Ọ̀gá mi rán mi láti sọ wí pé, ‘Àwọn ọ̀dọ́ ọmọkùnrin méjì láti ọ̀dọ̀ ọmọ wòlíì wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ wá sí ọ̀dọ̀ mi láti orí òkè ìlú ti Efraimu. Jọ̀wọ́ fún wọn ní ẹ̀bùn fàdákà àti ìpààrọ̀ aṣọ méjì.’ ” Naamani wí pé, “Ní gbogbo ọ̀nà, mú ẹ̀bùn méjì.” Ó sì rọ Gehasi láti gbà wọ́n, ó sì di ẹ̀bùn méjì náà ti fàdákà ní inú àpò méjì, pẹ̀lú ìpààrọ̀ aṣọ méjì, ó sì fún àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ méjì, wọ́n sì kó wọn lọ sọ́dọ̀ Gehasi. Nígbà tí Gehasi sì dé ibi ilé ìṣọ́, ó gbà wọ́n lọ́wọ́ wọn, ó sì tó wọ́n sínú ilé, ó sì jọ̀wọ́ àwọn ọkùnrin náà lọ́wọ́ lọ, wọ́n sì jáde lọ. Nígbà náà ó sì wọlé wá ó sì dúró níwájú ọ̀gá rẹ̀ Eliṣa. “Níbo ni o ti wà Gehasi?” Eliṣa béèrè. “Ìránṣẹ́ rẹ kò lọ sí ibìkan kan.” Gehasi dá a lóhùn. Ṣùgbọ́n Eliṣa wí fún un pé, “Ẹ̀mí mi kò ha wà pẹ̀lú rẹ nígbà tí ọkùnrin náà sọ̀kalẹ̀ lórí kẹ̀kẹ́ láti pàdé rẹ? Ṣé àsìkò tí ó yẹ láti gba owó nìyìí, tàbí láti gba aṣọ, ọgbà olifi, ọgbà àjàrà, àgùntàn, màlúù tàbí ìránṣẹ́kùnrin àti ìránṣẹ́bìnrin? Ẹ̀tẹ̀ Naamani yóò lẹ̀ mọ́ ọ àti sí irú-ọmọ rẹ títí láé.” Nígbà náà Gehasi kúrò níwájú Eliṣa, ó sì di adẹ́tẹ̀, ó sì funfun gẹ́gẹ́ bí ẹ̀gbọ̀n òwú.