II. A. Ọba 4:18-44
II. A. Ọba 4:18-44 Bibeli Mimọ (YBCV)
Nigbati ọmọ na si dagba, o di ọjọ kan, ti o jade tọ̀ baba rẹ̀ lọ si ọdọ awọn olukore. O si wi fun baba rẹ̀ pe, Ori mi, ori mi! On si sọ fun ọmọ-ọdọ̀ kan pe, Gbé e tọ̀ iya rẹ̀ lọ. Nigbati o si gbé e, ti o mu u tọ̀ iya rẹ̀ wá, o joko li ẽkun rẹ̀ titi di ọjọ kanri, o si kú. On si gòke, o si tẹ́ ẹ sori ibùsun enia Ọlọrun na, o si sé ilẹ̀kun mọ ọ, o si jade lọ. On si ke si ọkọ rẹ̀, o si wipe, Emi bẹ̀ ọ, rán ọkan ninu awọn ọdọmọkunrin si mi, ati ọkan ninu awọn kẹtẹkẹtẹ, emi o si sare tọ̀ enia Ọlọrun lọ, emi o si tun pada. On si wipe, Ẽṣe ti iwọ o fi tọ̀ ọ lọ loni? kì isa ṣe oṣù titun, bẹ̃ni kì iṣe ọjọ isimi. On sì wipe, Alafia ni. Nigbana li o di kẹtẹkẹtẹ ni gãri, o si wi fun iranṣẹ rẹ̀ pe, Mã le e, ki o si ma nṣo; máṣe dẹ̀ ire fun mi, bikòṣepe mo sọ fun ọ. Bẹ̃li o lọ, o si de ọdọ enia Ọlọrun na li òke Karmeli. O si ṣe, nigbati enia Ọlọrun na ri i li okère, o si sọ fun Gehasi ọmọ ọdọ rẹ̀ pe, Wò ara Ṣunemu nì: Emi bẹ̀ ọ, sure nisisiyi ki o pade rẹ̀, ki o si wi fun u pe, Alafia ki o wà bi? alafia ki ọkọ rẹ̀ wà bi? alafia ki ọmọde wà bi? On si dahùn wipe, Alafia ni. Nigbati o si de ọdọ enia Ọlọrun li ori òke, o gbá a li ẹsẹ̀ mu: ṣugbọn Gehasi sunmọ ọ lati tì i kurò. Enia Ọlọrun na si wipe, Jọwọ rẹ̀ nitori ọkàn rẹ̀ bajẹ ninu rẹ̀, Oluwa si pa a mọ́ fun mi, kò si sọ fun mi. Nigbana li o wipe, Mo ha tọrọ ọmọ li ọwọ oluwa mi bi? Emi kò ha wipe, Máṣe tàn mi jẹ? O si wi fun Gehasi pe, Di àmure rẹ, ki o si mu ọpa mi li ọwọ rẹ, ki o si lọ, bi iwọ ba ri ẹnikẹni li ọ̀na, máṣe ki i; bi ẹnikeni ba si kí ọ, máṣe da a li ohùn: ki o si fi ọpá mi le iwaju ọmọ na. Iya ọmọ na si wipe, Bi Oluwa ti mbẹ, ati bi ẹmi rẹ ti mbẹ, emi kì o fi ọ silẹ. On si dide, o si ntọ̀ ọ lẹhin. Gehasi si kọja siwaju wọn, o si fi ọpá na le ọmọ na ni iwaju, ṣugbọn kò si ohùn, tabi afiyesi: nitorina o si tun pada lati lọ ipade rẹ̀, o si wi fun u pe, Ọmọ na kò ji. Nigbati Eliṣa si wọ̀ inu ile, kiyesi i, ọmọ na ti kú, a si tẹ́ ẹ sori ibùsun rẹ̀. O si wọ̀ inu ile lọ, o si se ilẹ̀kun mọ awọn mejeji, o si gbadura si Oluwa. On si gòke, o si dubulẹ le ọmọ na, o si fi ẹnu rẹ̀ le ẹnu rẹ̀, ati oju rẹ̀ le oju rẹ̀, ati ọwọ rẹ̀ le ọwọ rẹ̀: on si nà ara rẹ̀ le ọmọ na, ara ọmọ na si di gbigboná. O si pada, o si rìn lọ, rìn bọ̀ ninu ile lẹ̃kan; o si gòke, o si nà ara rẹ̀ le e; ọmọ na si sín nigba meje; ọmọ na si là oju rẹ̀. O si pè Gehasi, o si wipe, Pè ara Ṣunemu yi wá. O si pè e. Nigbati o si wọle tọ̀ ọ wá, o ni, Gbé ọmọ rẹ. Nigbana li o wọ̀ inu ile, o si wolẹ li ẹba ẹṣẹ̀ rẹ̀, o si dojubolẹ, o si gbé ọmọ rẹ̀, o si jade lọ. Eliṣa si tun pada wá si Gilgali, iyàn si mu ni ilẹ na; awọn ọmọ awọn woli joko niwaju rẹ̀: on si wi fun iranṣẹ rẹ̀ pe, Gbe ìkoko nla ka iná, ki ẹ si pa ipẹ̀tẹ fun awọn ọmọ awọn woli. Ẹnikan si jade lọ si igbẹ lati fẹ́ ewebẹ̀, o si ri ajara-igbẹ kan, o si ka eso rẹ̀ kún aṣọ rẹ̀, o si rẹ́ ẹ wẹwẹ, o dà wọn sinu ikoko ipẹ̀tẹ na: nitoripe nwọn kò mọ̀ wọn. Bẹ̃ni nwọn si dà a fun awọn ọkunrin na lati jẹ. O si ṣe bi nwọn ti njẹ ipẹ̀tẹ na, nwọn si kigbe, nwọn si wipe, Iwọ enia Ọlọrun, ikú mbẹ ninu ikoko na! Nwọn kò si le jẹ ẹ. Ṣugbọn on wipe, Njẹ, ẹ mu iyẹ̀fun wá. O si dà a sinu ikoko na, o si wipe, Dà a fun awọn enia, ki nwọn ki o le jẹ. Kò si si jamba ninu ikoko mọ. Ọkunrin kan si ti Baali-Ṣaliṣa wá, o si mu àkara akọso-eso, ogun iṣu àkara barle, ati ṣiri ọkà titun ninu àpo rẹ̀ wá fun enia Ọlọrun na. On si wipe, Fi fun awọn enia, ki nwọn ki o le jẹ. Iranṣẹ rẹ̀ si wipe, Kinla, ki emi ki o gbé eyi kà iwaju ọgọrun enia? On si tun wipe, Fi fun awọn enia, ki nwọn ki o le jẹ: nitori bayi li Oluwa wi pe, Nwọn o jẹ, nwọn o si kù silẹ. Bẹ̃li o gbe e kà iwaju wọn, nwọn si jẹ, nwọn si kù silẹ, gẹgẹ bi ọ̀rọ Oluwa.
II. A. Ọba 4:18-44 Yoruba Bible (YCE)
Ní ọjọ́ kan, lẹ́yìn tí ọmọ náà dàgbà, ó lọ bá baba rẹ̀ ninu oko níbi tí wọ́n ti ń kórè. Lójijì, ó kígbe pe baba rẹ̀, ó ní, “Orí mi! Orí mi!” Baba rẹ̀ sì sọ fún iranṣẹ kan kí ó gbé ọmọ náà lọ sọ́dọ̀ ìyá rẹ̀. Nígbà tí iranṣẹ náà gbé ọmọ náà dé ọ̀dọ̀ ìyá rẹ̀, ìyá rẹ̀ gbé e lé ẹsẹ̀ títí ọmọ náà fi kú ní ọ̀sán ọjọ́ náà. Obinrin náà bá gbé òkú ọmọ náà lọ sí yàrá Eliṣa, ó tẹ́ ẹ sí orí ibùsùn rẹ̀, ó ti ìlẹ̀kùn, ó sì jáde. Ó kígbe pe ọkọ rẹ̀ pé, “Jọ̀wọ́ rán iranṣẹ kan sí mi pẹlu kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ kan. Mo fẹ́ sáré lọ rí eniyan Ọlọ́run, n óo pada dé kíákíá.” Ọkọ rẹ̀ bèèrè lọ́wọ́ rẹ̀ pé, “Kí ló dé tí o fi fẹ́ lọ rí i lónìí? Òní kì í ṣe ọjọ́ oṣù tuntun tabi ọjọ́ ìsinmi.” Ó sì dáhùn pé, “Kò séwu.” Lẹ́yìn tí wọ́n ti di kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ náà ní gàárì tán, ó sọ fún iranṣẹ náà pé, “Jẹ́ kí kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ náà máa sáré dáradára, kí ó má sì dẹ̀rìn, àfi bí mo bá sọ pé kí ó má sáré mọ́.” Ó lọ bá Eliṣa ní orí òkè Kamẹli. Eliṣa rí i tí ó ń bọ̀ lókèèrè, ó bá sọ fún Gehasi, iranṣẹ rẹ̀, pé, “Wò ó! Obinrin ará Ṣunemu nì ni ó ń bọ̀ yìí! Sáré lọ pàdé rẹ̀ kí o sì bèèrè alaafia rẹ̀ ati ti ọkọ rẹ̀ ati ti ọmọ rẹ̀ pẹlu.” Obinrin náà dá Gehasi lóhùn pé, “Alaafia ni gbogbo wa wà.” Nígbà tí ó dé ọ̀dọ̀ Eliṣa, ó wólẹ̀ níwájú rẹ̀, ó sì di ẹsẹ̀ rẹ̀ mú. Gehasi súnmọ́ ọn láti tì í kúrò, ṣugbọn Eliṣa wí fún un pé, “Fi obinrin náà sílẹ̀, ṣé o kò rí i pé inú rẹ̀ bàjẹ́ gidigidi ni? OLUWA kò sì bá mi sọ nǹkankan nípa rẹ̀.” Obinrin náà bá sọ fún Eliṣa pé, “Ǹjẹ́ mo tọrọ ọmọ lọ́wọ́ rẹ bí? Ǹjẹ́ n kò sọ fún ọ kí o má ṣe tàn mí jẹ?” Eliṣa bá sọ fún Gehasi pé, “Ṣe gírí, kí o mú ọ̀pá mi lọ́wọ́, kí o sì máa lọ. Bí o bá pàdé ẹnikẹ́ni lọ́nà, má ṣe kí i, bí ẹnikẹ́ni bá kí ọ, má dáhùn.” Nígbà náà ni ìyá ọmọ náà wí pé “Bí OLUWA tí ń bẹ láàyè tí ẹ̀mí ìwọ pàápàá sì ń bẹ, n kò ní fi ọ́ sílẹ̀.” Gehasi bá dìde, ó bá a lọ. Ó lọ fi ọ̀pá Eliṣa lé ọmọ náà lójú, ṣugbọn ọmọ náà kò jí. Ó bá pada lọ sọ fún Eliṣa pé ọmọ náà kò jí. Nígbà tí Eliṣa dé ilé náà, ó bá òkú ọmọ náà lórí ibùsùn. Ó wọlé síbi tí òkú ọmọ náà wà, ó ti ìlẹ̀kùn, ó sì gbadura sí OLUWA. Ó nà gbalaja lé ọmọ náà lórí, ó fẹnu kò ó lẹ́nu, ó fojú kò ó lójú, ó sì gbé ọwọ́ lé ọwọ́ rẹ̀. Bí ó sì ti nà lé ọmọ náà, ara ọmọ náà bẹ̀rẹ̀ sí lọ́ wọ́ọ́rọ́. Lẹ́yìn náà, ó dìde, ó rìn síwá sẹ́yìn ninu ilé náà, ó tún pada lọ nà lé ọmọ náà. Ọmọ náà sín lẹẹmeje, ó sì la ojú rẹ̀. Lẹ́yìn náà, ó wí fún Gehasi pé kí ó pe obinrin ará Ṣunemu náà wá, Gehasi bá pè é. Nígbà tí obinrin náà dé, Eliṣa wí fún un pé kí ó gba ọmọ rẹ̀. Obinrin náà wólẹ̀ lẹ́gbẹ̀ẹ́ ẹsẹ̀ rẹ̀, ó sì dojúbolẹ̀. Lẹ́yìn náà, ó mú ọmọ rẹ̀, ó sì jáde lọ. Eliṣa dé sí Giligali nígbà tí ìyàn wà ní ilẹ̀ náà. Bí àwọn ọmọ wolii ti jókòó níwájú rẹ̀, ó sọ fún àwọn iranṣẹ rẹ̀, ó ní, “Ẹ gbé ìkòkò ńlá léná kí ẹ sì se àsáró fún àwọn ọmọ wolii.” Ọ̀kan ninu àwọn iranṣẹ náà lọ sí oko láti já ewébẹ̀, ó rí àjàrà tí ó máa ń hù ninu igbó, ó sì ká ninu èso rẹ̀. Nígbà tí ó dé ilé, ó rẹ́ wọn sinu ìkòkò àsáró náà láìmọ̀ ohun tí wọ́n jẹ́. Wọ́n bu oúnjẹ fún àwọn ọmọ wolii láti jẹ. Bí wọ́n ti ń jẹ àsáró náà, wọ́n kígbe pé “Eniyan Ọlọrun, májèlé wà ninu ìkòkò yìí!” Wọn kò sì lè jẹ ẹ́ mọ́. Eliṣa dáhùn, ó ní, “Ẹ bu oúnjẹ díẹ̀ wá.” Ó da oúnjẹ náà sinu ìkòkò, ó sì wí pé, “Bu oúnjẹ fún àwọn ọkunrin náà, kí wọ́n lè jẹun.” Kò sì sí oró májèlé ninu oúnjẹ náà mọ́. Ọkunrin kan wá láti Baaliṣaliṣa, ó mú burẹdi àkọ́so èso wá fún eniyan Ọlọrun, ati ogún burẹdi tí a fi ọkà-baali ṣe ati ṣiiri ọkà tuntun ninu àpò rẹ̀. Eliṣa bá wí pé, “Ẹ kó wọn fún àwọn ọmọkunrin, kí wọ́n jẹ ẹ́.” Ṣugbọn iranṣẹ rẹ̀ wí pé, “Báwo ni n óo ṣe wá gbé èyí kalẹ̀ níwájú ọgọrun-un eniyan láti jẹ?” Eliṣa tún ní, “Kó wọn fún àwọn ọmọkunrin kí wọ́n jẹ ẹ́, nítorí pé OLUWA ní, ‘Wọn yóo jẹ, yóo sì ṣẹ́kù.’ ” Iranṣẹ náà bá gbé oúnjẹ náà kalẹ̀ níwájú àwọn ọmọkunrin náà, wọ́n jẹ, ó sì ṣẹ́kù gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ OLUWA.
II. A. Ọba 4:18-44 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Ọmọ náà dàgbà, ní ọjọ́ kan, ó jáde lọ sí ọ̀dọ̀ baba rẹ̀, ó wà pẹ̀lú àwọn olùkórè. “Orí mi! Orí mi!” Ó wí fún baba rẹ̀. Baba rẹ̀ sọ fún ìránṣẹ́, “Gbé e lọ sọ́dọ̀ ìyá rẹ̀.” Lẹ́yìn ìgbà tí ìránṣẹ́ náà ti gbé e sókè tí ó sì gbé e tọ ìyá rẹ̀ lọ, ọmọ ọkùnrin náà jókòó sórí ẹsẹ̀ rẹ̀ títí ó fi di ọ̀sán gangan, nígbà náà ó sì kú. Ó lọ sí òkè ó sì tẹ́ ọmọ náà lórí ibùsùn ènìyàn Ọlọ́run, ó sì tìlẹ̀kùn, ó jáde lọ. Ó pe ọkọ rẹ̀ ó sì wí pé, “Jọ̀wọ́ rán ọ̀kan lára àwọn ìránṣẹ́ rẹ àti kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ kan kí èmi kí ó lè lọ sí ọ̀dọ̀ ènìyàn Ọlọ́run kíákíá kí n sì padà.” “Kí ni ó dé tí o fi fẹ́ lọ sọ́dọ̀ rẹ̀ lónìí?” Ó béèrè. “Kì í ṣe oṣù tuntun tàbí ọjọ́ ìsinmi.” Ó wí pé, “Gbogbo rẹ̀ ti dára.” Ó sì di kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ ní gàárì ó sì wí fún ìránṣẹ́ rẹ̀ pé, “Máa nìṣó; má ṣe dẹ́sẹ̀ dúró dè mí àyàfi tí mo bá sọ fún ọ.” Bẹ́ẹ̀ ni ó sì jáde wá, ó sì wá sọ́dọ̀ ènìyàn Ọlọ́run ní orí òkè Karmeli. Nígbà tí ó sì rí i láti òkèrè, ènìyàn Ọlọ́run sọ fún ìránṣẹ́ rẹ̀ Gehasi, “Wò ó! Ará Ṣunemu nì! Sáré lọ pàdé rẹ̀ kí o sì béèrè lọ́wọ́ rẹ̀, ‘Ṣé o wà dáradára? Ṣé ọkọ rẹ wà dáradára? Ṣé ọmọ rẹ wà dáradára?’ ” Ó wí pé, “Gbogbo nǹkan wà dáradára.” Nígbà tí ó dé ọ̀dọ̀ ènìyàn Ọlọ́run ní orí òkè, ó gbá a ní ẹsẹ̀ mú. Gehasi wá láti wá lé e dànù, ṣùgbọ́n ènìyàn Ọlọ́run wí pé, “Fi í sílẹ̀! Ó wà nínú ìpọ́njú, Kíkorò, ṣùgbọ́n OLúWA fi pamọ́ fún mi kò sì sọ ìdí rẹ̀ fún mi.” “Ṣé mo béèrè ọmọ lọ́wọ́ rẹ, olúwa mi?” Obìnrin náà wí pé, “Ṣé mi ò sọ fún ọ pé kí o, ‘Má ṣe fa ìrètí mi sókè’?” Eliṣa wí fún Gehasi pé, “Ká agbádá rẹ sínú ọ̀já àmùrè, mú ọ̀pá mi sí ọwọ́ rẹ kí o sì sáré. Tí o bá pàdé ẹnikẹ́ni má ṣe kí i, tí ẹnikẹ́ni bá kí ọ, má ṣe dá a lóhùn, fi ọ̀pá náà lé ojú ọmọ ọkùnrin náà.” Ṣùgbọ́n ìyá ọmọ náà wí pé, “Gẹ́gẹ́ bí OLúWA ti ń bẹ láààyè àti gẹ́gẹ́ bí ó ti wà láààyè, èmi kò ní í fi ọ́ sílẹ̀.” Bẹ́ẹ̀ ni ó sì dìde ó sì tẹ̀lé e. Gehasi sì ń lọ síbẹ̀ ó sì fi ọ̀pá náà lé ojú ọmọ náà, ṣùgbọ́n kò sí ohùn tàbí ìdáhùn. Bẹ́ẹ̀ ni Gehasi padà lọ láti lọ bá Eliṣa láti sọ fún un pé, “Ọmọ ọkùnrin náà kò tí ì dìde.” Nígbà tí Eliṣa dé inú ilé, níbẹ̀ ni òkú ọmọ ọkùnrin náà dùbúlẹ̀ lórí ibùsùn. Ó sì wọ ilé, ó sì ti ìlẹ̀kùn mọ́ àwọn méjèèjì ó sì gbàdúrà sí OLúWA. Nígbà náà ó dé orí ibùsùn, ó sùn sórí ọmọ ọkùnrin náà, ẹnu sí ẹnu, ojú sí ojú, ọwọ́ sí ọwọ́. Gẹ́gẹ́ bí ó ti nà ara rẹ̀ lórí rẹ̀, ara ọmọ náà sì gbóná. Eliṣa yípadà lọ, ó sì rìn padà ó sì jáde wá sínú ilé nígbà náà ó sì padà sí orí ibùsùn ó sì tún nà lé e ní ẹ̀ẹ̀kan sí i. Ọmọ ọkùnrin náà sì sín ní ìgbà méje ó sì ṣí ojú rẹ̀. Eliṣa sì pe Gehasi ó sì wí pé, “Pe ará Ṣunemu.” Ó sì ṣe bẹ́ẹ̀. Nígbà tí ó dé, ó wí pé, “Gba ọmọ rẹ.” Ó sì wọlé, ó sì kúnlẹ̀ síwájú ẹsẹ̀ rẹ̀ ó sì tẹ̀ Orí sílẹ̀. Nígbà náà ó sì mú ọmọ rẹ̀ ó sì jáde lọ. Eliṣa padà sí Gilgali ìyàn sì wà ní ilẹ̀ náà. Nígbà tí àwọn ọmọ wòlíì ṣe ìpàdé pẹ̀lú rẹ̀, ó sì wí fún ìránṣẹ́ rẹ̀ pé, “Gbé ìkòkò ńlá ka iná kí o sì se ọbẹ̀ aláta díẹ̀ fún àwọn ọkùnrin yìí.” Ọ̀kan lára wọn jáde lọ sí orí pápá láti kó ewébẹ̀ jọ àti láti wá àjàrà igbó. Ó sì kó díẹ̀ nínú ẹ̀fọ́ gbọ̀rọ̀ rẹ̀ jọ, ó sì ka a kún aṣọ agbádá rẹ̀. Nígbà tí ó padà dé, ó sì gé wọn sínú ìkòkò ọbẹ̀, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé kò sí ẹni tí ó mọ ohun tí wọ́n ń jẹ. Wọ́n da ọbẹ̀ náà jáde fun àwọn ọkùnrin náà, ṣùgbọ́n bí wọ́n ti bẹ̀rẹ̀ sí ní jẹ oúnjẹ náà, wọ́n sọkún jáde, “Ìwọ ènìyàn Ọlọ́run ikú ń bẹ nínú ìkòkò yìí!” Wọn kò sì le jẹ ẹ́. Eliṣa sì wí pé, “Mú ìyẹ̀fun díẹ̀ wá,” Ó sì fi sínú ìkòkò ó sì wí pé, “Kí ó sì fi fún àwọn ènìyàn láti jẹ.” Kò sì sí ohun tí ó léwu nínú ìkòkò náà. Ọkùnrin kan wá láti Baali-Ṣaliṣa, ó sì mú àkàrà àkọ́so èso, ogún ìṣù àkàrà barle, tí wọ́n dín láti ara àkọ́so èso àgbàdo, àti pẹ̀lú síírí ọkà tuntun nínú àpò rẹ̀ wá fún ènìyàn Ọlọ́run náà. Òun sì wí pé “Fún àwọn ènìyàn láti jẹ.” “Báwo ni èmi yóò ṣe gbé èyí ka iwájú àwọn ọgọ́ọ̀rún (100) ènìyàn?” ìránṣẹ́ rẹ̀ béèrè. Ṣùgbọ́n Eliṣa dá a lóhùn pé, “Gbé e fún àwọn ènìyàn láti jẹ, nítorí èyí ni ohun tí OLúWA sọ: ‘Wọn yóò jẹ yóò sì tún ṣẹ́kù’ ” Nígbà náà ó gbé e ka iwájú wọn, wọ́n sì jẹ ẹ́, wọ́n sì ní èyí tó ṣẹ́kù, gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ OLúWA.