II. A. Ọba 24:2-5
II. A. Ọba 24:2-5 Bibeli Mimọ (YBCV)
Oluwa si rán ẹgbẹ́ ogun awọn ara Kaldea si i, ati ẹgbẹ́ ogun awọn ara Siria, ati ẹgbẹ́ ogun awọn ara Moabu, ati ẹgbẹ́ ogun awọn ọmọ Ammoni, o si rán wọn si Juda lati pa a run, gẹgẹ bi ọ̀rọ Oluwa, ti o ti sọ nipa awọn iranṣẹ rẹ̀ awọn woli. Nitõtọ lati ẹnu Oluwa li eyi ti wá sori Juda, lati mu wọn kuro niwaju rẹ̀, nitori ẹ̀ṣẹ Manasse, gẹgẹ bi gbogbo eyiti o ṣe; Ati nitori ẹ̀jẹ alaiṣẹ̀ ti o ta silẹ pẹlu: nitoriti o fi ẹ̀jẹ alaiṣẹ̀ kún Jerusalemu; ti Oluwa kò fẹ darijì. Ati iyokù iṣe Jehoiakimu, ati gbogbo eyiti o ṣe, a kò ha kọ wọn sinu iwe ọ̀rọ ọjọ awọn ọba Juda?
II. A. Ọba 24:2-5 Yoruba Bible (YCE)
OLUWA bá rán àwọn ọmọ ogun Kalidea, ati ti Siria, ti Moabu, ati ti Amoni, láti pa Juda run bí ọ̀rọ̀ ti OLUWA sọ láti ẹnu àwọn wolii, iranṣẹ rẹ̀. Ìjìyà yìí dé bá Juda láti ọ̀dọ̀ OLUWA, láti pa wọ́n run kúrò níwájú rẹ̀, nítorí ìwà ẹ̀ṣẹ̀ Manase ọba, ati nítorí ẹ̀jẹ̀ aláìṣẹ̀ tí ó ti ta sílẹ̀, nítorí tí ó ta ẹ̀jẹ̀ aláìṣẹ̀ sílẹ̀ ní gbogbo ìgboro Jerusalẹmu, OLUWA kò ní dáríjì í. Gbogbo nǹkan yòókù tí Jehoiakimu ṣe ni a kọ sinu Ìwé Ìtàn Àwọn Ọba Juda.
II. A. Ọba 24:2-5 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
OLúWA sì rán àwọn ará Babeli, àwọn ará Aramu, àwọn ará Moabu àti àwọn ọmọ Ammoni. Ó rán wọn láti pa Juda run, ní ìbámu pẹ̀lú ọ̀rọ̀ OLúWA tí ó ti sọ nípasẹ̀ àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ wòlíì. Nítòótọ́ eléyìí ṣẹlẹ̀ sí Juda gẹ́gẹ́ bí àṣẹ OLúWA, láti mú wọn kúrò níwájú rẹ̀ nítorí ẹ̀ṣẹ̀ Manase àti gbogbo nǹkan tí ó ṣe. Àti pẹ̀lú ẹ̀jẹ̀ aláìṣẹ̀ tí a ta sílẹ̀ nítorí ó ti kún Jerusalẹmu pẹ̀lú ẹ̀jẹ̀ aláìṣẹ̀ tí OLúWA kò sì fẹ́ láti dáríjì. Ní ti ìyókù iṣẹ́ ìjọba Jehoiakimu, àti gbogbo nǹkan tí ó ṣe, ṣé wọn kò kọ wọ́n sínú ìwé ìtàn ọba Juda?