II. A. Ọba 23:15 - Compare All Versions
II. A. Ọba 23:15 YBCV (Bibeli Mimọ)
Ati pẹlu, pẹpẹ ti o ti wà ni Beteli, ati ibi giga ti Jeroboamu ọmọ Nebati, ẹniti o mu Israeli ṣẹ̀, ti tẹ́, ati pẹpẹ na, ati ibi giga na ni o wó lulẹ, o si sun ibi giga na, o si lọ̀ ọ lũlu, o si sun ere-oriṣa na.
II. A. Ọba 23:15 YCE (Yoruba Bible)
Josaya wó ilé oriṣa tí Jeroboamu ọba, ọmọ Nebati, ẹni tí ó mú Israẹli ṣẹ̀, kọ́ sí Bẹtẹli. Josaya wó pẹpẹ ìrúbọ tí ó wà níbẹ̀, ó fọ́ òkúta rẹ̀ túútúú, ó lọ̀ wọ́n lúbúlúbú, ó sì jó ère Aṣera pẹlu.
II. A. Ọba 23:15 BMYO (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Àní pẹpẹ tí ó wà ní Beteli ibi gíga tí Jeroboamu ọmọ Nebati dá. Tí ó ti fa Israẹli láti ṣẹ̀, àní pẹpẹ náà àti ibi gíga tí ó fọ́ túútúú. Ó jó àwọn ibi gíga, ó sì lọ̀ ọ́ sí ẹ̀tù, ó sì sun ère Aṣerah pẹ̀lú.