II. A. Ọba 23:1-3
II. A. Ọba 23:1-3 Bibeli Mimọ (YBCV)
ỌBA si ranṣẹ, nwọn si pè gbogbo awọn àgba Juda ati Jerusalemu jọ sọdọ rẹ̀. Ọba si gòke lọ sinu ile Oluwa, ati gbogbo awọn enia Juda ati gbogbo olugbe Jerusalemu pẹlu rẹ̀, ati awọn alufa, ati awọn woli ati gbogbo enia, ati ewe ati àgba: o si kà gbogbo ọ̀rọ inu iwe majẹmu na ti a ri ninu ile Oluwa li eti wọn. Ọba si duro ni ibuduro na, o si dá majẹmu niwaju Oluwa, lati mã fi gbogbo aìya ati gbogbo ọkàn rìn tọ̀ Oluwa lẹhin, ati lati pa ofin rẹ̀ mọ́, ati ẹri rẹ̀, ati aṣẹ rẹ̀, lati mu ọ̀rọ majẹmu yi ṣẹ, ti a ti kọ ninu iwe yi. Gbogbo awọn enia si duro si majẹmu na.
II. A. Ọba 23:1-3 Yoruba Bible (YCE)
Josaya bá pe ìpàdé gbogbo àwọn olórí Juda ati Jerusalẹmu. Gbogbo wọn lọ sí ilé OLUWA pẹlu àwọn alufaa ati àwọn wolii ati gbogbo àwọn eniyan, àtọmọdé àtàgbà wọn. Ọba bá ka ìwé majẹmu tí wọ́n rí ninu ilé OLUWA sí etígbọ̀ọ́ wọn. Ọba dúró sí ààyè rẹ̀, lẹ́bàá òpó, ó bá OLUWA dá majẹmu pé òun óo máa rìn ní ọ̀nà OLUWA ati láti pa àwọn òfin rẹ̀ mọ́ ati láti mú gbogbo ohun tí ó wà ninu Ìwé náà ṣẹ. Gbogbo àwọn eniyan sì ṣe ìlérí láti pa majẹmu náà mọ́.
II. A. Ọba 23:1-3 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Nígbà náà ọba pe gbogbo àwọn àgbàgbà Juda àti Jerusalẹmu jọ. Ó gòkè lọ sí ilé OLúWA pẹ̀lú àwọn ọkùnrin Juda, àwọn ènìyàn Jerusalẹmu, àwọn àlùfáà àti àwọn wòlíì—gbogbo àwọn ènìyàn láti ibi kéékèèkéé sí ńlá. Ó kà á sí etí ìgbọ́ ọ wọn, gbogbo ọ̀rọ̀ tí ó wà nínú ìwé májẹ̀mú, tí a ti rí nínú ilé OLúWA. Ọba sì dúró lẹ́bàá òpó, ó sì sọ májẹ̀mú di tuntun níwájú OLúWA láti tẹ̀lé OLúWA àti láti pa òfin rẹ̀ mọ́, ìlànà àti òfin pẹ̀lú gbogbo ọkàn rẹ̀ àti gbogbo ẹ̀mí rẹ̀, àti láti ṣe ìwádìí àwọn ọ̀rọ̀ májẹ̀mú tí a kọ sínú ìwé yìí. Nígbà náà, gbogbo àwọn ènìyàn sì ṣèlérí fúnrawọn sí májẹ̀mú náà.