II. A. Ọba 22:1-11
II. A. Ọba 22:1-11 Bibeli Mimọ (YBCV)
ẸNI ọdun mẹjọ ni Josiah nigbati o bẹ̀rẹ si ijọba; o si jọba li ọdun mọkanlelọgbọ̀n ni Jerusalemu, Orukọ iya rẹ̀ ni Jedida, ọmọbinrin Adaiah ti Boskati. On si ṣe eyiti o tọ́ li oju Oluwa o si rìn li ọ̀na Dafidi baba rẹ̀ gbogbo, kò si yipada si apa ọ̀tún tabi si apa òsi. O si ṣe li ọdun kejidilogun Josiah ọba li ọba rán Ṣafani ọmọ Asaliah ọmọ Mesullamu, akọwe, si ile Oluwa, wipe, Gòke tọ̀ Hilkiah olori alufa lọ, ki o le ṣirò iye fadakà ti a mu wá sinu ile Oluwa, ti awọn olùtọju iloro ti kojọ lọwọ awọn enia: Ẹ si jẹ ki wọn ki o fi le awọn olùṣe iṣẹ na lọwọ, ti nṣe alabojuto ile Oluwa: ki ẹ si jẹ ki wọn ki o fi fun awọn olùṣe iṣẹ na ti mbẹ ninu ile Oluwa, lati tun ibi ẹya ile na ṣe. Fun awọn gbẹnagbẹna, ati fun awọn akọle, ati awọn ọ̀mọle, lati rà ìti-igi ati okuta gbígbẹ lati tún ile na ṣe. Ṣugbọn a kò ba wọn ṣe iṣirò owo ti a fi le wọn lọwọ, nitoriti nwọn ṣe otitọ. Hilkiah olori alufa si sọ fun Ṣafani akọwe pe, Emi ri iwe ofin ni ile Oluwa. Hilkiah si fi iwe na fun Ṣafani, on si kà a. Ṣafani akọwe si wá sọdọ ọba, o si tún mu èsi pada fun ọba wá, o si wipe, Awọn iranṣẹ rẹ ti kó owo na jọ ti a ri ni ile na, nwọn si ti fi le ọwọ awọn ti o nṣiṣẹ na, ti nṣe alabojuto ile Oluwa. Ṣafani akọwe si fi hàn ọba, pe, Hilkiah alufa fi iwe kan le mi lọwọ. Ṣafani si kà a niwaju ọba. O si ṣe, nigbati ọba gbọ́ ọ̀rọ inu iwe ofin na, o si fà aṣọ rẹ̀ ya.
II. A. Ọba 22:1-11 Yoruba Bible (YCE)
Ọmọ ọdún mẹjọ ni Josaya nígbà tí ó jọba, ó sì wà lórí oyè ní Jerusalẹmu fún ọdún mọkanlelọgbọn. Orúkọ ìyá rẹ̀ ni Jedida ọmọ Adaya ará Bosikati. Ó ṣe ohun tí ó dára lójú OLUWA, ó tẹ̀ sí ọ̀nà Dafidi, baba ńlá rẹ̀, kò sì ṣe nǹkankan tí ó lòdì sí àpẹẹrẹ tí Dafidi fi lélẹ̀. Ní ọdún kejidinlogun tí Josaya jọba, ó rán Ṣafani, akọ̀wé rẹ̀, ọmọ Asalaya, ọmọ Meṣulamu, sí ilé OLUWA pé kí ó lọ sí ọ̀dọ̀ Hilikaya olórí alufaa, kí ó ṣírò iye owó tí àwọn alufaa tí wọ́n wà lẹ́nu ọ̀nà ti gbà lọ́wọ́ àwọn eniyan, kí ó gbé owó náà fún àwọn tí wọ́n ń ṣe àkóso àtúnṣe ilé OLUWA. Àwọn ni wọn yóo máa san owó fún àwọn gbẹ́nàgbẹ́nà, àwọn ọ̀mọ̀lé ati àwọn agbẹ́kùúta, kí wọ́n sì ra igi ati òkúta tí wọn yóo lò fún àtúnṣe ilé OLUWA. Ó ní àwọn tí wọ́n ń ṣe àkóso àtúnṣe ilé náà kò ní nílò láti ṣe ìṣirò owó tí wọn ń ná, nítorí pé gbogbo wọn ni wọ́n jẹ́ olóòótọ́. Ṣafani jíṣẹ́ ọba fún Hilikaya; Hilikaya olórí alufaa, sì sọ fún un pé òun ti rí ìwé òfin ninu ilé OLUWA. Ó fún Ṣafani ní ìwé náà, ó sì kà á. Ṣafani bá pada lọ jíṣẹ́ fún ọba, ó sọ fún ọba pé, àwọn iranṣẹ rẹ̀ ti kó owó tí ó wà ninu ilé OLUWA fún àwọn tí wọ́n ń ṣe àkóso àtúnṣe ilé OLUWA, ati pé Hilikaya fún òun ní ìwé kan; ó sì kà á sí etígbọ̀ọ́ ọba. Nígbà tí ọba gbọ́ ọ̀rọ̀ inú ìwé náà, ó fa aṣọ rẹ̀ ya láti fi ìbànújẹ́ rẹ̀ hàn.
II. A. Ọba 22:1-11 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Josiah jẹ́ ọmọ ọdún mẹ́jọ nígbà tí ó di ọba, ó sì jẹ ọba ní Jerusalẹmu fún ọdún mọ́kànlélọ́gbọ̀n. Orúkọ ìyá rẹ̀ a máa jẹ́ Jedida ọmọbìnrin Adaiah; ó wá láti Boskati. Ó sì ṣe èyí tí ó dára lójú OLúWA, ó sì rìn ní ọ̀nà Dafidi baba a rẹ̀, kò sì yípadà sí apá ọ̀tún tàbí sí apá òsì. Ní ọdún kejì-dínlógún tí ó fi jẹ ọba. Ọba Josiah rán akọ̀wé, Ṣafani ọmọ Asalia, ọmọ Meṣullamu, sí ilé OLúWA. Ó wí pé; “Gòkè lọ sí ọ̀dọ̀ Hilkiah olórí àlùfáà, kí o sì jẹ́ kí ó ṣírò iye owó tí a mú wá sí ilé OLúWA, tí àwọn olùṣọ́nà ti gbà lọ́wọ́ àwọn ènìyàn. Ẹ sì jẹ́ kí wọn ó fi lé àwọn ọkùnrin tí a ti yàn láti bojútó iṣẹ́ náà lórí ilé OLúWA. Kí ẹ sì jẹ́ kí àwọn ọkùnrin san án fún àwọn òṣìṣẹ́ tí ó ń tún ilé OLúWA ṣe. Àwọn gbẹ́nàgbẹ́nà, àwọn ọ̀mọ̀lé àti àwọn akọ́lé. Bákan náà ni wọ́n ra igi àti òkúta ọlọ́ṣọ̀ọ́ láti fi tún tẹmpili ṣe. Ṣùgbọ́n wọn kò ní láti ṣe ìṣirò fún owó náà tí a fi fún wọn, nítorí wọ́n ṣe òtítọ́.” Hilkiah olórí àlùfáà sọ fún Ṣafani akọ̀wé pé, “Èmi rí ìwé òfin nílé OLúWA.” Ó fi fún Ṣafani, ẹni tí ó kà á. Nígbà náà, Ṣafani akọ̀wé lọ sí ọ̀dọ̀ ọba. Ó sì sọ fún un pé: “Àwọn ìjòyè rẹ ti san owó náà tí ó wà nínú ilé OLúWA. Èmi sì ti fi lé ọwọ́ àwọn tí ó ń ṣe iṣẹ́ náà àti àwọn alábojútó nílé OLúWA.” Nígbà náà Ṣafani akọ̀wé sọ fún ọba pé, “Hilkiah àlùfáà ti fún un ní ìwé kan.” Ṣafani kà lára rẹ̀ níwájú ọba. Nígbà tí ọba gbọ́ ọ̀rọ̀ tí ó wà nínú ìwé òfin, ó sì fa aṣọ rẹ̀ ya.